Kí ló gbé Olaiya Igwe lọ sí etí òkun ní ìhòhò ọmọlúàbí láti lọ ṣàdúrà?

Oríṣun àwòrán, OlaiyaIgwe
Ni bayii ti eto idibo sipo Aarẹ Naijiria ku oṣu melokan, oriṣiriṣi ara lawọn eeyan fi n ṣatilẹyin fun ẹni ti ọkan wọn fẹ ko de ipo Aarẹ.
Bi awọn kan ṣe n wọn oniruuru aṣọ to ni ami at orukọ oludije ti wọn to si lẹyin, lawọn mii n ṣe ọpọlọpọ fidio lati sọrọ lori eredi ti oludije ti wọn fẹ fi gbọdọ de ipo naa.
Ni ti awọn mii ẹwẹ, ṣe wọn n korajọ lati rin lati abegbe kan si omiran.
Eyii lo difa fun agba oṣere tiata Yoruba, Ebun Oloyede, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Olaiya Igwe to lọ ṣadura leti okun ni ihoho ọmọluabi.
Ninu fidio kan to fi lede loju opo Instagram rẹ ni Olaiya ti wa ni ihoho, to si n ṣadura pe ki Ọlọrun gba fun oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu pe ko jawe olubori ninu eto idibo Aarẹ ọdun to n bọ.
Bo tilẹ jẹ pe wọn ṣe ọpọlọpọ atunto si fidio ọhun, ohun ti agba oṣere naa n gbiyanju lati fi han araye ni pe ihoho ni oun wa, ti oun si ṣadura fun fun Tinubu leti okun ko le di Aarẹ.
Adura wo ni Olaiya Igwe n gba?
Ninu fidio ọhun ni Olaiya ti n gbadura pe “Ọba lana, Ọba leni, Ọba lọjọ aye gbogbo, mo pe ẹ, emi Ebun Lukmon Ọlaiya Igwe.”
“Ọlọrun Ọba o, tori Bola Ahmed Tinubu ni mo ṣe wa... Jẹ ko jawe olubori Ọlọrun.”
“Ba wa gbe Tinubu de ipo, mo diidi wa si eti okun lati wa bẹ ọ... bi omi okun yii ṣe pọ to, bẹẹ ni ki ibo Bola Ahmed Tinubu ṣe pọ, majẹ ki oji ti wa, majẹ ki oju ti Bola Tinubu Jagaban.”
Olaiya tun sọ ninu fidio naa pe oun ko le sun nitori iya to n jẹ awọn ọmọ Naijiria, oun si gbadura ki Ọlọrun jẹ ki Tinubu de ipo Aarẹ.
Oloore mi ni Tinubu
Ti ẹ ko ba gbagbe, Olayia Igwe ti sọ ṣaaju pe oloore oun ni Tinubu ati idile rẹ jẹ.
Ninu fidio kan to fi lede ṣaaju lo ti sọ pe iyawo Tinubu fi owo nlan kan ran oun lọwọ lasiko ti oun n ṣaisan lati fi gba itọju.
O ni idile Tinubu ṣe oun loore lasiko ti ọpọ awọn ti oun lero pe wọn yoo ran lọwọ kọ ẹyin si oun, o si sọ pe oun ko le fi oju oloore gungi.
Ẹwẹ, ọpọ awọn ololufẹ rẹ lo ti fi n erongba wọn lede lori fidio naa.
Pupọ ninu awọn to n tẹle loju opo Instagram lo n sọrọ kobakungbe si nitori fidoi ọhun, ti awọn kan si n pe agba oṣere naa ni alatẹnuje ni bi wọn ṣe ni fidio naa ko bojumu.












