Àwọn ajínigbé ya bo Mọ́ṣáláṣí láti jí Ìmáàmù gbé, èèyàn mọ́kànlá farapa

Oríṣun àwòrán, The Letterman/Premuim Times
Eeeyan mọkanla ti farapa ninu Mọṣalaṣi kan nipinlẹ Delta lẹyin ti awọn ajinigbe kan kọlu ile ijọsin ọhun.
Mọṣalaṣi kan to wa niluu Ughelli ni iṣẹlẹ naa ti waye ni afẹmọju ọjọ Ẹti.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Bright Edafe sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP pe eeyan mọkanla lo farapa lasiko ikọlu ọhun nigba ti awọn afurasi naa gbiyanju lati ji awọn olujọsin naa gbe lọ.
Bo tilẹ jẹ pe o ni iwadii ti bẹrẹ lori ikọlu naa, awọn ileeṣẹ iroyin abẹle kan jabọ pe awọn ajinigbe naa ji Immamu mọṣalaṣi naa gbe lọ.
Amọ Edafe sọ pe ọrọ ko ri bẹẹ, ati pe ṣe ni wọn gbiyanju lati ji Imaamu naa gbe amọ wọn ko ṣe aṣeyọri ninu igbiyanju wọn.
Iṣẹlẹ ijinigbe ni Naijiria
Iṣẹlẹ ijinigbe kii ṣe ohun iyalẹnu mọ ni Naijiria, paapaa lati igab ti Aarẹ Muhammadu Buhari ti gori alefa.
Bo iṣẹlẹ ijinigbe ṣe n ṣẹlẹ ni iha Ariwa lemọlemọ naa lo n waye ni Guusu ati Iwọ oorun.
Ẹwẹ, irufẹ ikọlu bayii ko fi bẹẹ wọnpọ ni ipinlẹ Delta bii ibẹrẹ ọdun 1999 si 2000 ti awọn ọmọ ẹgbẹ ajigbara Niger Delta maa n kọlu awọn ileeṣẹ ti wọn ti n wa epo rọbi.
Amọ lawọn ilu mii to yi Delta ka ni iha Guusu, ori awọn ọmọ ẹgbẹ ajigbara IPOB ati ikọ alaabo Eastern Security Network ni ijọba n di ẹbi awọn iṣẹlẹ ijinigbe to n waye nibẹ le.
Ṣugbọn IPOB ti ni oun ko mọ nnkankan nipa awọn iṣẹlẹ ijinigbe to n ṣẹlẹ lagbegbe, ti awọn naa si n di ẹbi ọrọ naa le awọn darandaran.












