Mọ̀ si nípa Bassey Albert, olùdíje sípò gómìnà ní Akwa Ibom tó rí ẹ̀wọ̀n ọdún 42 he

BASSEY ALBERT

Oríṣun àwòrán, BASSEY ALBERTFACEBOOK

Ile ẹjọ giga kan niluu Uyo, ti ran oludije sipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu YPP, Sẹnetọ Bassey Albert lẹwọn ọdun mejilelogoji lori ẹsun iwa ibajẹ.

Ṣaaju ni ajọ EFCC ti kọkọ fi ẹsun mẹfa ọtọtọ kan oloṣelu ọhun eyii to jọ mọ jibiti.

Wọn ni o gba ọkọ ayọkẹlẹ mẹfa ti iye owo rẹ to miliọnu mejilenigba naira lọwọ Olajide Omokore – Omokore, to jẹ ọrẹ timọtimọ minisita fun ọrọ epo bẹntiro tẹlẹ, Diezani Alison-Madueke.

Ọdun 2012 ni iṣẹlẹ to gbe oloṣelu naa lọ sẹwọn waye nigba ti ọkunrin naa n ṣiṣẹ gẹgẹ bii kọmiṣọna fun eto iṣuna nipinlẹ Akwa Ibom.

Bi Bassey ṣe kagbako iṣẹlẹ to sọ di ero ẹwọn

Inu oṣu Kẹfa, ọdun 2019 ni wọn fẹsun naa kan Bassey lẹyin to gba awọn ọkọ ayọkẹlẹ ọhun lọwọ Olajide Omokore – Omokore, to jẹ ọrẹ korikosun Diezani Alison-Madueke to n jẹjọ ẹsun ajẹbanu.

Awọn ọkọ naa Infinity QX 56 BP ti iye rẹ to miliọnu marundinlaadọta naira; Toyota Land Cruiser V8 BP, ti iye owo rẹ to ogoji miliọnu naira; Toyota Hiace High Roof ti iye rẹ to miliọnu mẹrindinlogun naira ati Toyota Hilux 4x4, ti iye owo rẹ to miliọnu mẹrindinlogoji naira.

Lasiko igbẹjọ naa, bassey sọ pe lootọ loun gba awọn ọkọ ọhun lọwọ Omokere amọ kii ṣe oun lo gbe awọn akanṣe iṣẹ kan fun ileeṣẹ rẹ lọdun 2013.

O ni o ya oun lẹnu bi ileeṣẹ IMDLCC ti oun jẹ alaga rẹ lasiko naa ṣe n ko owo fun Omokore.

Ta ni Sẹnetọ Bassey Albert Akpan?

Ọdun 1972 ni wọn bi ọkunrin ọhun sinu idile Oloye Albert Robert Akpan, ti oun naa jẹ oloṣelu nipinlẹ Akwa Ibom.

Wọn dibo yan gẹgẹ bii Sẹnetọ lọdun 2015 lati ṣoju ẹkun idibo Ariwa ipinlẹ Akwa Ibom.

O naa lo n dije du ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Youth Progressive Party, YPP, ninu eto idibo gbogbogbo ti yoo waye lọdun 2023.

Ṣaaju ko to di Sẹnetọ, o ṣiṣẹ gẹgẹ bii kọmiṣọna fun eto iṣuna ipinlẹ Akwa Ibom lati ọdun 2007.

O ti fi awọn igba kan ṣiṣẹ lawọn banki bii United Bank for Africa (UBA), Continental Trust Bank, First Inland Bank Plc ati First City Monument Bank ri, ko to darapọ mọ oṣelu.