Ṣé lóòtọ́ ni ìjọba Amẹrika kọ̀ láti fún Tinubu ni Físà?

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad

Ikọ ipolongo ẹgbẹ oṣelu APC ti sọ pe irọ nla gba ni iroyin to sọ pe ijọba Amẹrika kọ lati fun oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ naa, Bola Ahmed Tinubu ni iwe irinna Fisa.

Ṣaaju lo yẹ ki Tinubu rinrinajo lọ silẹ Amẹrika nibi to yẹ ko ti ṣe ipade kan lonii ọjọ kẹrin, oṣu Kejila, ọdun 2022 yii, to si yẹ ko pada si Naijiria lọjọ kejila, oṣu kan naa.

Amọ kaka ki Tinubu lọ si Amẹrika, ni ṣe ni wọn sun irinajo naa siwaju.

Ko pẹ lẹyin naa ti iroyin jade pe Tinubu ti sun irinajo rẹ siwaju ti iroyin gbode pe ṣe ni ijọba Amẹrika kọ lati fun Tinibu ni iwe irinna, ni ko jẹ ko le lọ si irinajo ọhun.

Lẹyin naa tun ni aworan kan Tinubu pẹlu Aarẹ ilẹ Amẹrika, Joe Biden bẹrẹ si n fa ori ayelujara ya, ti awọn ololufẹ APC kan si sọ pe Tinubu ti lọ si Amẹrika, nibi to ti ba Aarẹ Biden ya fọto.

Amọ ẹgbẹ oṣelu naa sọ ninu atẹjade kan pe ayederu ni aworan ọhun, ati pe awọn ọmọ ẹgbẹ alatako lo po aworan naa pọ lati tan awọn araalu jẹ ati lati tabuku Bola Tinubbu.

Ṣe lootọ ni ijọba Amẹrika kọ lati fun Tinubu ni Fisa?

Bola Tinubu Visa

Oríṣun àwòrán, Festus Keyamo

Agbẹnusọ ikọ ipolongo Tinubu, Festus Keyamo ti sọ loju opo Twitter rẹ pe Tinubu ni iwe irinna ilẹ Amẹrika dani, o si le fi Fisa naa rinrinajo titi di ọdun to n bọ.

Keyamọ tun fi aworan iwe irininna ‘passport’ Tinubu lede, ninu eyii ti Fisa Amẹrika naa wa lara rẹ. 

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

O ni “Aworan yii wa fun awọn gbọyisọyi to n gbe iroyin ẹlẹjẹ kiri nipa Bola Tinubu pe ko ri Fisa Amẹrika gba.”

Gẹgẹ bii ohun ti ninu Fisa ti Keyami fi lede, Tinubu le fi iwe naa lo si Amẹrika titi di oṣu Kọkanla, ọdun 2023.

Ẹwẹ, ọpọ eeyan lo n sọ loju Twitter naa pe ayederu ni Fisa ti Keyamo fi lede.

Amọ ṣa, Tinubu yoo sọrọ nibi ipade kan ni Chatham House niluu London, nibi ti yoo ti ṣalaye nipa awọn eto rẹ fun Naijiria to ba le de ipo Aarẹ.