‘Ayọ̀ mí kún nígbà tí mó rí àwọn ọmọ mi obìnrin márùn-ún lẹ́yìn tí wọ́n jí wọn gbé’

Oríṣun àwòrán, Others
Iya awọn ọmọ obinrin marun un ti awọn ajinigbe tusilẹ nipinlẹ Zamfara ti salaye ohun ti awọn ọmọ naa lakọja nigba ti wọn wa ni ahamọ awọn ajinigba ọhun.
Awọn ọmọ obinrin ọhun ti wọn ọmọ agba ọjẹ nipinlẹ Zamfara, Alhaji Abubakar Bello Furfur, ni wọn lo oṣu marun un ni ọwọ awọn ajinigbe
Iroyin lori ijinigbe wọn ni kọminu awọn ọmọ orilẹede Naijiria, papa julọ awọn ti apa ariwa orilẹede naa lẹyin ti fọran kan bọ sori ayelujara nibi awọn ajinigbe ti sẹruba awọn ọmọ naa pe awọn sọ wọn di ọkan lara wọn ti awọn mọlẹbi ba kọ lati san owo ti wọn bere fun.
Ọjọ Aje ni wọn tu awọn ọmọ obinrin marun un lẹyin ti iroyin kan ni pe Baba awọn ọmọ ti san owo itusilẹ nigba mẹta ọtọtọ
‘Wọn ko ba wọn ṣe nnkankan pọ’

Oríṣun àwòrán, Zamfara State Government
Iya wọn, Hajiya Hadiza Abubakar, sọ fun ileeṣẹ BBC pe inu oun dun nigba ti awọn kede itudilẹ awọn ọmọ naa.
“Inu mi dun. Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun,
“Bi inu mi ṣe dun to nigba ti mo gbọ pe wọn ko ba awọn ọmọ naa ṣe ibalopọ kankan.
“Wọn lẹyin ẹfon ati awọn inira pẹpẹ mii, ko si nkankan to ṣe awọn.”
O fikun pe ohun to fa omije loju awọn ni ibi awọnṣe ri fọran kan to safihan bi awọn ajinigbe naa ṣe gbe ibọn dani, o ni “inu mi bajẹ, ti mo si ra ọwọ ibẹ si Ọlọrun.”
Hajiya Hadiza ni pẹlu idunu ati ayọ ni oun fi dimọ awọn ọmọ ọhun ati kete ti oun gbọ pe gomina ni ki wọn ba ni ohun ki sure lọ ba gomina.
“Mogbọ pe Gomina Muhammed Matawalle n wa awọn ọmọ ni mo ki wọn ma lọ.”
O tẹsiwaju si pe awọn ko ri ohun ko ohun gba gẹgẹ bii iranlọwọ, ti awọn si ni lati gbe ọpọlọpọ dukia ta lati ri owo san fun awọn ajinigbe.















