Igbákejì olórí ẹgbẹ́ Ilana Ọmọ Oodua kọ̀wé fi ipò sílẹ̀

Aworan

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Igbakeji adari ẹgbẹ to n ja fun idasilẹ orilẹ-ede Oduduwa, Ilana Omo Oodua, ti kọwe fi ipo rẹ silẹ.

Ọjọgbọn Wale Adeniran sọ ninu lẹta kan to kọ si olori ẹgbẹ naa, Ọjọgbọn Banji Akintoye.

O ni iṣẹ oun gẹgẹ bi igbakeji olori tán ni ọjọ kẹfaa, oṣu Kọkanla, ọdun 2022.

Iroyin yii jẹyọ ninu atẹajde ti agbẹnusọ ẹgbẹ Ilana Omo Oodua, Maxwell Adeleye fi sita ni owurọ ọjọ Aje, ọjọ keje, oṣu Kọkanla.

Kikọwe fi isẹ silẹ Ọjọgbọn Adeniran waye lẹyin ọjọ kẹta ti agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Adeleye, naa kọwe fi ipo silẹ.

Ṣugbọn igbimọ oluṣakoso ẹgbẹ naa kọ iwe ti Adeleye fi fi ipo silẹ, oun naa ko si tii gba ẹ̀bẹ̀ wọn lati tẹsiwaju.

Ninu lẹta ti igbakeji olori, Ọjọgbọn Wale Adeniran kọ lati fi ipo silẹ, o ni fifi ipo naa silẹ ko tumọ si pe oun fi ẹgbẹ silẹ.

“Pe mo fi ipo igbakeji Alana, Ilana Omo Oodua silẹ lati ọjọ Aiku, ọjọ kẹfaa, oṣu Kọkanla, ko tumọ si pe mo fi ẹgbẹ silẹ.

“Nitori ipinnu ọkan mi lati ri daju pe idasilẹ orilẹ-ede Yoruba to da duro kuRO Ni Naijiria, ni ma a ṣi fi wa gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ to n ja fun ominira wa.”

O ni oun fi ipo naa silẹ nitori awọn ilana kan ti oun n tẹle, eyi to han si Ọjọgbọn Banji Akintoye ati Ọlọrun.

Àwa kọ́ la rán àwọn tó ṣèkọlù sí ikọ̀ ọmọogun Naijiria, a ò mọ̀ wọ́n rí – Ilana Ọmọ Oodua

Ẹgbẹ to n ja fun ominira ilẹ Yoruba, Ilana Ọmọ Oodua ti bu ẹnu atẹ lu awọn to ṣekọlu si ikọ ileeṣẹ ọmọogun Naijiria ni agbegbe Ado/odo Ọta nipinlẹ Ogun.

Ninu atẹjade ti wọn fi lede ni wọn ti sọ wi pe awọn to mọ nkankan nipa iṣẹlẹ naa.

Bakan naa ni wọn kọ ẹyin si iru iṣẹlẹ naa , nitori o tabuku ohun ti wọn gbẹkẹle.

Kilo ṣẹlẹ ni ifẹhọnuhan Yoruba Nation ni Ado/Odo Ota?

Iroyin ni awọn afẹhọnuhan pẹlu asia Yoruba Nation ni wọn ṣe ifẹhọnuhan ni agbegbe Ado/Odo Ọta nipinlẹ Ogun ni Ọjọ Kẹrin, Oṣu Kọkanla, ọdun 2022.

Lasiko ifẹhọnuhan naa ni wọn ṣekọlu si ikọ ọmọogun ilẹ Naijiria, ti wọn si ṣekọlu si ọkọ ati awọn ọmọogun naa.

Ẹgbẹ Ilana ọmọ Oodua ọhun ti Ọjọgbọn Banji Akintoye n ṣe adari fun lo sọ wi pe awọn ko mọ nkankan nipa awọn to hu iwa ipa si awọn ẹṣọ alaabo.

''Ilana Ọmọ Oodua ko faramọ iwa ipa’’

Àwòrán Ọjọgbọn Banji Akintoye

Oríṣun àwòrán, ilana omo odua

Ninu atẹjade ti wọn fi lede ni wọn ti ni awọn to hu iru iwa bayii fẹ ba orukọ ẹgbẹ jẹ ni.

Bakan naa ni wọn fikun un pe wọn ko sọ fun ẹnikẹni to jẹ adari ninu ẹgbẹ pe wọn fẹ gbe iru igbeṣẹ lati ṣewọde naa.

‘’A fẹ ki awọn eniyan mọ wi pe a ko faramọ iwa ipa rara, ati wi pe ako gbọ si iwọde naa ti wọn ṣe.’’

‘’Nitori naa awọn ti wọn ṣe iwọde naa ṣe ni adabọwọ ara wọn’’.

Ẹgbẹ naa wa kesi ileeṣẹ ọlọpaa lati ma ṣe magomago ni iwadii naa, ki wọn fi idi otitọ mulẹ.

Ẹgbẹ Ilana ọmọ Oodua wa fikun un pe awọn ni igbagbọ pe awọn to fẹ ba orukọ ẹgbẹ jẹ lo ṣagbatẹru awọn to ṣekọlu ọhun.

Ewu ń bẹ lóko, ọ̀pọ̀ jàǹdùkú tí yáwọ ilẹ̀ Yorùbá - Akintoye figbe ta

Adari apapọ ẹgbẹ Ilana ọmọ Oodua, Ọjọgbọn Banji Akintoye tí pariwo síta lori awọn isẹlẹ ijinigbe lọkan o jọkan.

Akintoye ni awọn janduku kan lati oke okun ti yawọ awọn apa ibì kan ni ilẹ Yoruba ati lorilẹede Naijiria.

Akintoye sọ eleyi nigba to n ba awọn ọmọ ẹgbẹ ṣe ipade pọ niluu Ibadan.

Nigba to n ba wọn sọrọ lori ẹrọ ibanisọrọ, o ni pupọ awọn ikọlu ati ijinigbe to n waye ni awọn apa ibi kan lorilẹede Naijiria ni ko sẹyin awọn janduku naa.

Akintoye tẹsiwaju pe ko si ṣíṣe ayafi ki awọn ọmọ Yoruba fọwọsowọpọ lati gba ominira ilẹ Yoruba.

O ni eyi yoo si wa si ìmuṣẹ ko to di pari oṣu Kejila ọdun 2022.

"Awọn janduku lati ilẹ okeere ni wọn wa laarin wa.

"Ko to di ipari oṣu Kejìla, a o gba ominira fun ilẹ Yoruba.

Emi ati Ọjọgbọn Adeniran wa lẹyin èyí. A ní latí gba ilẹ wa nítorí ninu ewu nla la wa."

Bola Tinubu fẹ́ ba orúkọ mí jẹ́ àti ẹgbẹ́ Ilana Omo Oodua – Banji Akintoye

Aworan

Adari ẹgbẹ awọn ọmọ Yoruba to n ja fun ominira ilẹ Yoruba labẹ asia ẹgbẹ Ilana ọmọ Oodua, Banji Akintoye ti ni oludije fẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu n tiraka lati ba ẹgbẹ ọhun jẹ.

Banji Akintoye lo sọ eleyii ninu atẹjade to fi lede ni Ọgbọnjọ, Oṣu Kẹwaa, ọdun 2022 lati tako ipade ẹgbẹ naa ti wọn pe lẹyin rẹ.

Akintoye ni oun gẹgẹbi adari ko pe ipade ẹgbẹ kankan ni Ọjọ Kinni, Osu Kọkanla, ọdun 2022.

‘’Irọ patapata ni iroyin ti awọn kan fi lede pe ki ẹgbẹ ilana Ọmọ Oodua parapọ wa si ibi ipade ti wọn pe ni ilu Ibadan, ni ipinlẹ Ọyọ.

Aworan

Oríṣun àwòrán, OTHERS

‘’Awọn oṣiṣẹ Tinubu ti wọnu ẹgbẹ Ilana Ọmọ Ọọdua lati tu wa ka’’

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Akintoye wa ṣe apejuwe awọn to n gbe iroyin ipade naa gẹgẹ bi awọn ẹni ibi ti wọn ko ni nkan rere lati ṣe fun iran Yoruba.

O ṣapejuwe awọn to fẹ gbe ipade naa kalẹ gẹgẹ bi awọn oṣisẹ Tinubu to fẹ da ẹgbẹ naa ru.

‘’Awọn alatilẹyin awọn oloṣelu ti wọ aarin wa, paapaa Bola Tinubu n fi owo ra awọn eniyan lati tabuku ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua ati emi gẹgẹ bi adari ẹgbẹ naa.’’

‘’Nitori naa ni mo ṣe n kede fun gbogbo awọn ọmọ Yoruba lagbaye pe mi o ran ẹnikẹni ni iṣẹ lati ṣe ipade kankan ni ilu Ibadan.’’

‘’Awọn ọbayejẹ lo wa lẹyin ipade naa, ti wọn si n fẹ oye awọn oloṣelu kaka ki wọn ja fun ilẹ Yoruba.’’

‘’Bakan naa ni Bola Tinubu ti ṣeleri lati da ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua ru ati gbogbo awọn ẹgbẹ ọmọ Yoruba’ miran.’’

‘’O ṣeni laanu pe Bola Tinubu ko ni ifẹ awọn ọmọ Yoruba ni ọkan, imọtara ẹni nikan lo n ja fun kaakiri.’’

‘’Nitori naa mo rọ gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ tootọ lati tako awọn iranṣẹ Tinubu to ti wọnu ẹgbẹ wa. Ẹ jẹ ka ja fun ominira ilẹ Yoruba ki a le gba awọn ohun ini wa pada lọwọ awọn amunisin.’’

Ki lo ti waye sẹyin laarin Banji Akintoye ati Bola Tinubu?

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe ẹgbẹ to n ja fun idasilẹ orilẹede Yoruba, Ilana Ọmọ Oodua ti sọ pe oro nla lawọn ọmọ ilẹ Yoruba gbogbo to ba kopa ninu eto idibo 2023 lorilẹede Naijiria, n da fun awon mọlẹbi wọn.

 Adari apapọ ẹgbẹ Ilana ọmọ Oodua, Ọjọgbọn Banji Akintoye lo sọ eyi ninu atẹjade kan to fi sita pe bi Naijiria ṣe wa bayi, ko si anfani kankan ti ẹya Yoruba le ri jẹ lara rẹ.

 O ni oniruuru ifasẹyin ni apapọ orilẹede yii ti mu ba oniruuru igbesẹ idagbasoke bii ẹkọ ọfẹ, igbayegbadun araalu, ilera ọfẹ ati bẹẹbẹ lọ ti awọn Akin ọmọ Yoruba ti gbe kalẹ fun ẹya Yoruba.

 Bakan naa lo fi kun un pe nṣe lawọn ọmọ Yoruba to n dije, paapaa Aṣiwaju Ahmed Bola Tinubu to n dije fun ipo aarẹ Naijiria lẹgbẹ oṣelu APC n ba ọjọ iwaju Yoruba jẹ ati pe ogun ti yoo mu itinu ba atiranderan lo nle.

Tinubu fesi pada fun Akintoye lori ẹsun to fi kan-an

Wayi o, alaga ikọ̀ ìpolongo ipò Ààrẹ Tinubu/Shettima, Bayo Onanuga nínu atẹjade kan to fisita ni gbogbo ẹnu ni òun fi sọ wí pé Asiwaju Bola Tinubu ní ìfarajìn sí iṣẹ́ ìsìn ọmọnìyàn, ló ṣe gbégbá láti di Ààrẹ Nàìjíríà.

 Ó ní ìgbàgbọ́ Tinubu nínú ìṣọ̀kan àti ìdúróire Nàìjíríà níbi tí gbogbo ènìyàn orílẹ̀ èdè yìí yóò ti jẹ múkùndún ìjọba àwaarawa láìfi ẹ̀yà tàbí ẹ̀sìn ṣe ló ṣe gbégbá láti di ààrẹ.

 Ó fi kun pé gbogbo àwọn ohun tí Ọjọgbọn Akintoye sọ wí pé ó jẹ àwọn lógún ni Tinubu ti ṣaájú sọ wí pé òun yóò gbájúmọ́ tí òun bá di ààrẹ Nàìjíríà nígbà tó ń ṣàfilọ́lẹ̀ àwọn nǹkan tó fẹ́ ṣe tó bá di ààrẹ.

 Onanuga tẹ̀síwájú pé Tinubu mọ̀ wí pé agbára tó sodo sọ́wọ́ ìjọba àpapọ̀ ti pọ̀ púpọ̀ jù ló fàá tí àwọn ìpínlẹ̀ kò fi gòkè tó bó ṣe yẹ tó sì ṣèlérí láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin láti fi ààyè gba àwọn ìjọba ìbílẹ̀ láti le wà ní ààyè ara wọn ju bí wọ́n ṣe wà lásìkò yìí lọ.