'Inú ewu ńlá ni gbogbo àgbáyé wà báyìí lórí ọ̀rọ̀ àyípadà ojú ọjọ́'

Obinrin kan ti wọn n fi aloku firiji gbe sọda odo

Apero lori ayipada oju ọjọ ti ajọ iṣọkan agbaye gbe kalẹ n lọ lọwọ lorilẹede Egypt, ikilọ ni wọn si fi ṣide nibẹ pe ohun to n ṣẹlẹ lorilẹ aye nipa ọrọ ayika n kọni lominu.

Akọwe agba ajọ iṣọkan agbaye, UN, Antonio Guterres ṣalaye ninu ọrọ to sọ si abajade iwadi ti ajọ UN ṣe eleyi ti wọn gbe jade lojo Aiku, eyi to sọ pe odun mẹjọ sẹyin si ọdun yii ni awọn odun to gbona julọ ninu itan agbaye.

Ko din ni ọgọfa awọn olori orilẹede kaakiri agbaye ti yoo kopa nibi ipade naa ti wọn da pe ni COP27 eyi tiyoo waye ni ilu Sharm el-Sheikh ni okun pupa.

Ọsẹ meji gbako ni ijiroro naa yoo fi waye laarin awọn orilẹede lori ayipada to n de ba oju ọjọ.

Aarẹ apero COP27, minisita fún ọrọ okeere ni Egypt, Sameh Shoukry je s’awọn adari lati maṣe faye gba wahala ounjẹ ati epo to n waye nipasẹ ogun ti Russia n gbe kọlu Ukraine di wọn lọwọ amojuto eto gbogbo to yẹ lori ọrọ ayipada oju ọjọ

“Ojuse gbogbo wa ti a peju silu Sharm el-Sheikh ni lati fi idaniloju wa han lori ipenija ti a n kojuati ipinnu wa lati bori rẹ.”

Ninu abajade iwadi ti ajọ iṣọkan agbaye UN ṣe naa, awọn onimọ ijinlẹ sayẹnsi ṣe ìkìlọ pe odiwọn igbona si agbaye baye ti goke si pẹlu iwọn 1.15 Centigrade ati pe awọn ọdun mẹjọ to kọja sẹyin lo fẹ gbona julọ ninu itan agbaye.

Iwadi naa tun kilo pe awọn àtúnbọ̀tán ayipada oju ọjọ tun n jẹyọ bii ẹkun omi okun nitori bi awọn yinyin to n yọ latawon ilẹ oni yinyin tun ṣe n pọ sinitori oru.

Akọwe agba ajọ iṣọkan agbaye UN, Antonio Guterres ni eyi wa lara awon ohun ti apero naa gbọdọ gbe igbesẹ to loorin ke lori.

Ireti wa pe oloru ijọba ilẹ Gẹẹsi, Rishi Sunak yoo rọ awọn adari orilẹede agbaye lati jawe si igbesẹ lori rẹ.

Bakan naa ni yoo rọ wọn lati maṣe fa sẹyin ninu ìpinnu wọn gbogbo nibi ipade naa, ti COP26 to waye ni ilu Glasgow.

Bakanna lẹyin ijiroro wọn, oniruru ipade ni yoo tun waye laarin ọsẹ meji, titi kan ipatẹ, idanilẹkọ ati idije aṣa laarin awọn ọdọ at’awọn eto miran.

Ko daju pe iwọde tako ipenija ayipada oju ọjọ to saba ma n waye nibi irufẹ apero yii to ti waye sẹyin yoo le waye nibi apero ti ọtẹ yii.

Aarẹ orilẹede Egypt Abdul Fattah al-Sisi, to ti wa nipo lati ọdun 2014 ti n gbogunti awọn alatako ijọba rẹ.

Awọn ẹgbẹ ajafetọ sọ pe ko din ni ẹgbẹrun lọna ọgọta awọn eeyan ti wọn ti fi si ẹwọn nitori nnkan to nii ṣe pẹlu oṣelu, ti pupọ ninu wọn ko tilẹ foju ba ile ẹjọ rara

Amọṣa o, awọn olugbe orilẹede Egypt fi to BBC leti pe akaimọye awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ labẹle lorilẹede naa ni wọn kuna lati forukọsilẹ fun apero naa.