Climate change: Wo àwọn orílẹ̀èdè tó ṣeéṣe kí omi parẹ́ láìpẹ́.

arakunrin Kofe n sọrọ ninu omi

Oríṣun àwòrán, Tuvalu foreign ministry

Ronu fun iṣẹju diẹ lori ile, ipilẹ rẹ atawọn ibi gbogbo ti o fẹran julọ lagbaye ati bi yoo ṣe nira pipọ bi iru awọn ibi bayii ba kan ṣadede parẹ kuro lori ilẹ aye lojiji.

Fun awon olugbe ọpọ awọn ipinlẹ ohu ti a n sọ yii ni wọn n ba finra.

Bi ọwọ omi okun ṣe n goke eti bebe nitori awọn iwa aitọ ti a n hu si ayika ati oju ọjọ eyi si ti n faa pipadanu awọn ilẹ ti ṣee dako tabi gbe, bẹẹni omi to mọ gaara ti n sọwọn lawọn erekusu wọnyii.

BBC gbe ohun to n ṣẹlẹ ni orilẹede kekere kan ni agbagbe okun Pacific (Pacific Ocean) yẹwo nibi ti orilẹede Tuvalu ti n foju winna wahala ikun omi.

Àkọlé fídíò, Ọ̀nà ọ̀fun lọ̀nà ọ̀run - omi ò jẹ́ ká ta ọjà

Bakan naa ni orilẹede naa n gbaradi lati pe awọn orilẹede yoku lagbaye lẹjõ bi omi ba lee gba ilẹ wọn lọ.

Minisita feto , ibaraẹnisọrọ ati ọrọ ilẹ okeere lorilẹede Tuvalu, Simon Kofe fi ọrọ nla sowo sibi ipade awọn olori orileede lori wahala ọrọ ayuka COP26 to waye ni Glasgow lorilẹede Scotland.

"A n ri sinu omi diẹdiẹṣugbọn awa nikan kọ o, gbogbo agbaye naa n ri pẹlu."

Omi okun ati ewu to wa lori rẹ lọwọlọwọ

Erekuṣu kekekeeke mẹsan lo wa ni Tuwalu to to iwon ẹgbẹrun mẹrin kilomita si Australia ati Hawaii. Awọn to sun mọ ju n Kiiribati, samoa ati Fiji.

Odiwọn orilẹede naa ni fifẹ ko ju kilimita mẹrindinlọgbọn ni tibu ati fifẹ lọ ẹgbẹrun mejila eeyan lo si n gbe inu rẹ.

okun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ipa ti okun n ni lara omi mimu

Ni awọn agbegbe kan, awọn omi okun n wọ inu ilẹ wọn to si n ba ibi oorisun omi gbogbo jẹ, gẹgẹ bi Kofe ṣe sọ.

"Omi ojo la saba maa n mu, ṣugbọn lawọn erekuṣu kan, wọn a tun maa gbẹ kọnga lati ri omi mu.

"Loni, ko ri bẹẹ mọ nitori pe omi okun ti n ya wọ awọn orisun omi mimu, nitoeinaa omi ojo nikan la n mu.

aworan maapu

Bi omi okun ṣe n ya wọ orisun omi wonyii tun n ṣe akoba fun eto ọgbin ti gbogbo awọn ilẹ oko si ti di eyi ti ko wulo fun iṣẹ ọgbin mọ.

Orilẹede Taiwan n seranwọ eto igbalode kan lati ran Tuvalu lọwọ lori pipese ounjẹ lọna eto ogbin igbalode kan

"Bi omi okun ti ṣe ba gbogbo ilẹ ibẹ jẹ ti gbingbin ohun jijẹ wa si di isoro ti sọ wa di ẹni ti n ko ounje wole lati oke okun " ni alaye ti Kofe ṣe.

Àkọlé fídíò, wọ́n ń fi mi pamọ́ ni lásìkò ti mo kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alága nítorí ọmọdé ni mí

Ipenija to n koju awọn orilẹede erekuṣu gbogbo

Awọn orilẹede erekusu bii Tuvalu ti n ke si gbogbo agbaye lati gbe igbesẹ ti loorin lori didaabo bo ayika lati nnkan bii ọgbọn ọdun seyin

Ni ọdun 1990, awọn orilẹde to wa lagbegbe okun Pacific (Pacific Ocean) ko ara jọ pọ pẹlu awọn orilẹede miran bii Antigua ati Barbuda, ni agbegbe Caribbean atawọn miran ni agbegbe okun Idian Ocean bii Maldives lati fi imọ ṣọkan lori gbigbe igbesẹ lori ọrọ ioenija oju ọjọ ati ayika.

igbo eti okun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajọṣepọ awọn orilẹede naa ti wọn oe adape rẹ ni Aosis ti ni orilẹede mọkandinlogoji bayii gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ, bẹẹni wọn si ti ko ipa ribiribi lati rii pe ọwọja wahala oju ọjọ ati ayika, paapaa lagbegbe wọn ko ṣokunkun si gbogbo agbaye.

Ki lawọn onimọ sayẹnsi sọ?

Igbimọ Ajọ iṣọkan agbaye lori ọrọ ipenija oju ọjọ atọrọ ayika, IPCC fọnrere rẹ ninu abajade uwadii wọn lọjọ kẹsan oṣu kẹjọ pe ọwọ ti omi okun fi n goke sii lọdọọdun ti pọ sii pẹlu ida mẹta laarin ọdun 1901 si 2018.

Mama kan n da omi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ipẹjọ fun ẹbun gba maa binu

Tuvalu tun n beere ohun kan tawọn orilẹede to ku diẹ kaa to n beere fun ṣugbọn ti awọn orilẹede ti ti moke ti wọn si ri jajẹ ko fẹ ṣiṣẹ le lori: sisan owo fba maa binu fun awọn adanu wọnyi ti ipenija oju ọjọ ati ayika da silẹ fun wọn

Tuvalu pẹlu ifọwọsowọpọ ijọba orilẹede Antigua ati Barbuda ti fi osdrukọ ajọ tuntun kan silẹ ni Ajọ Iṣọkan agbaye.

eeyan kan n ge ibẹpẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lara ohun to fa idasilẹ ajọ naa ni lati lee maa ti ipasẹ rẹ lanfani si igbimọ igbẹjọ lori ofin to de okun, ti a si n beere amọran lọwọ rẹ lori ofo ati adanu gbogbo ti o n ṣẹlẹ" Ọgbẹni Kofẹ tun ṣalayr siwaju sii.

Igbimọ igbẹjọ lori ofin to de okun, ti olu ileeṣẹ rẹ wa ni Hamburg, lorilẹede Germany lo wa fun yiyanju awọn aawọ ti ba niis ṣe pẹlu afẹnuko ofin Ajọ Iṣọkan agbaye t'odun1982 lori ofin to de okun lagbaye.