Soun Ogbomosho's death: Aare Muhammadu Buhari ránṣẹ́ sí ìlú Ogbomoso lórí ikú Soun

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Aare Muhammadu Buhari ti daro Soun Ogbomoso, Oba Oyewumi Ajagungbade Kẹta, to waja lọjọ kejila, oṣù Kejila, odun 2021.
Ninu atẹjade to fi sita lati ọwọ oluranlọwọ pataki fun lori eto iroyin, Femi Adesina, Aare Buhari sọ pe orúkọ Oba Oyewumi ko ni parun lailai fun ipa to ko lati mu ki irẹpọ ati ìṣọ̀kan wa nilu Ogbomoso.
O ni lootọ ni iku ori ade naa jẹ ibanujẹ, àmọ́ ki awọn ọmọ bibi ilẹ̀ Ogbomoso tu ara wọn ninu pẹlu igbeaye rere ti ọba naa gbe, paapaa nipa bo ṣe mu ki alaafia jọba nilu Ogbomoso, to si tun ko àwọn eeyan lati ilẹ̀ miran mọ́ra.
Soun ilu Ogbomoso, Oba Jimoh Oladunni Oyewumi Ajagungbade kẹta ti wọn kaa ilẹ lọ niluu Ogbomoso lonii ọjọ Aiku, ọjọ kejila oṣu kejila ọdun 2021.
Ni aarọ ọjọ Aiku ni a gbọ pe Soun ti lọ ba awọn baba nla rẹ lọrun aremọbọ.
Gẹgẹ bi musulumi, ni irọlẹ ọjọ Aiku yii naa ni wọn sin Oba Oyewumi ni ilana ẹsin musulumi.
Ọpọ awọn eeyan jankan jankan lo peju pesẹ si ibi eto isninku naa.
Inu aafin adateba ilu Ogbomoso ni wọn si Soun si.
Lọgan ti awọn ri iroyin pe Soun ti ilu Ogbomosho dagbere faye ni ẹsẹ ko ti gero ni aafin Soun ti oniruuru ikini ati adura si ti n waye.
Lara awọn to ti ṣabẹwo si aafin Soun Ogbomoso nigba ti wọn kede iku rẹ ni Gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ, Otunba Alao Akala.
Bakan naa, kete ti a gbọ iroyin ọhun ni akọroyin BBC Yoruba to wa ni ilu Ogbomosho ti de aafin.
Lara awọn ẹlẹgbẹ n jẹgbẹ to si kọkọ lọ aanfin lọ ki awọn olori ni ẹgbẹ awọn ẹlẹsin Kristẹni ni ilu naa eyi ti Biṣọọbu ijọ Anglican ti ilu naa dari.
Bo tilẹ jẹ pe Jimoh wa ninu orukọ Kabiyesi ti iwadi wa si fidi rẹ mulẹ pe Musulumi ni Soun, a rii pe awọn ẹlẹsin Kristẹni gan lo kọkọ lọ si aafin ti wọn si tẹ pẹpẹ ọpọlọpọ adura ni ilana ẹsin wọn.
Àwọn Pásítọ gbàdúrà fún Olorì Soun Ogbomosho tó jáde láyé, ìlú Ogbomosho àti asiko ti wọn yoo bẹrẹẹ yíyan arọpò fun Kabiyesi.
Wọn gbadura pe lẹyin ti Soun ti lọ simi, ilu Ogbomosho o ni daru.
Ọkan lara awọn oloye sọ fun Alufa to dari adura pe awọn fẹ rọ wọn pe ki wọn maa gbadura fun awọn tori asiko ti awọn yoo yan Ọba mii.
Lara awọn to sọrọ ni igba ti awọn gbọ, dandan ni ki ẹru ba awọn amọ awọn ti gba pe bi Ọlọrun ṣe fẹ ẹ niyẹn.
"Ko si ẹni to lee sọ pe Baba yii ko ṣe rere. Ati ogun ti wọn ja ni ati gbogbo ohun ti wọn ṣe si ilu lo ṣafihan pe wọn ja ogun ṣẹgun.
Musulumi ni Baba, ko da awa ẹlẹsin Kristẹni nu, gbogbo wa la maa n wa gbadura fun baba".
Biṣọọbu Titus Babatunde Olayinka to wa lara awọn to dari adura ni aafin Soun sọ pe gbogbo awọn ni yoo ni imọlara iku Kabiyesi.
Iroyin naa tẹ wa lọ́wọ lowurọ ọjọ Aiku bayii sọ pe Soun Ogbomoso ti w'àjà!.
Eeyan kan gboogi laafin Ọba Soun fi da BBC Yoruba loju pe lootọ ni baba ti waja lowurọ oni ọjọ Aiku, ọjọ Kejila oṣu Kejila ọdun 2021.
Bakan naa, Ọgbẹni Ajamu to jẹ olugbaninimọran pataki fun Oba Soun sọ fun BBC Yoruba pe ootọ ni nkan ti a n beere lọwọ oun ṣẹlẹ amọ ko tii to gbogboa raye leti o.
Ni ọjọ Kẹtadinlọgbọn oṣu Karun ni wọn bi Ṣọun ti ilẹ Ogbomọṣọ, Alayeluwa Ọba, Alhaji Dr. Jimoh Oladunni Oyewumi, Ajagungnade III to si gun ori Apere baba rẹ ni ọjọ Kẹrinlelogun oṣu Kẹwa ọdun 1973 titi di oni to waja.
Ẹ̀wẹ̀, nigba to di nkan bii ago mejila ọsan, awọn ẹlẹsin Islam naa de aafin Soun ti wọn si tẹwọ ọpọlọpọ adura fun ẹmi Ọba to waja.
Ori Ade yii padanu ọkan ninu awọn ọmọ rẹ ọkunrin, Pasitọ Olumide Oyewumi ninu oṣu Kejila ọdun 2020.
Awọn iroyin kan ni iku Olumide to jẹ Olusiro owo agba ni Fasiti Ladoke Akintola, Ogbomoso mi Kabiyesi titi nigba to ṣẹlẹ.
Ko tii si aridaju oun to fa iku Kabiyesi Soun ti Ogbomoso.
A o maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin wa fun un yin lati aafin bo ba ṣe n lọ.

Oríṣun àwòrán, OTHERS



















