Yinka Alaseyori Vs Solla Allyson: Kí ló ṣẹlẹ̀ láàrin Yinka Alaseyori àti Sola Allyson tí Alaseyori ń bẹ̀bẹ̀?

Oríṣun àwòrán, Adeyinka Alaseyori
Bo tilẹ jẹ pe pẹlu awada, Yinka Alaṣeyori ti ọpọ mọ si Oniduro mi ti tọrọ aforijin lọwọ ẹni to n wo gẹgẹ bi ọga orin, Sola Allyson pe oun ko mọọmọ ṣe ohun to ni oun ṣe, Sola Allyson naa ti fesi.
Ṣe ni awọn ọmọ Naijiria n gboriyin fun agbaọjẹ olorin Sola Allyson pe eeyan ti wọn fi n ṣe awokọ ṣe gbaa lo jẹ.
Koda awọn mii ni ẹru ti kọkọ ba awọn pe abi Sola Allyson n binu ni lootọ.

Oríṣun àwòrán, Adeyinka Alaseyori
Ninu atẹjade kan ti Sola Allyson fi sita ni ọjọ perete sẹyin lo ti kọ ọ bii lẹta si olorin kan to n jẹ Aduke Gold ati olorin Yinka Alaseyori pe oun ti kilọ fun awọn mejeji ni ọpọlọpọ igba ti oun si ti wa n fi ẹjọ wọn sun gbogbo agbaye bayii.
"Ko to di pe ọrọ dabi akukọ gagara n gberaga o, ẹ ṣọra yin ẹyin ọmọdebinrin mejeji yii o, kilode ti ẹyin mejeji yoo maa fi orokun mejeji kunlẹ ki mi" Ha. Mo ni mi o fẹran rẹ ẹ si tun n ba mi fa a".
Sola Allyson ni ki ati Adeyinka ati Aduke ṣọra wọn pẹlu bi wọn ṣe maa n fi ikunlẹ ki oun ni gbogbo ibi ti wọn ba ti ri oun, o ni oun gba kamu lọj naa ti wn n ba oun fa a amọ ko ba oun lara mu.

Oríṣun àwòrán, Alaseyori
"Mo mọ pe ẹ le fẹ bu ọla ati iyi fun mi. Iwa ire ni mo si mọ ọ loore amọ ẹ kan le ṣee ranpẹ ni ọna ọmọluabi dipo ki ẹ maa kunlẹ tan yanyan lori ilẹ. Ko le to yẹn kẹẹ!" O ni ki wọn maa lo ilana ọmọluabi ti awọn alakọwe.
"Mo nifẹ ẹyin mejeji gan. Koda lemọ lemọ ti Aduke lagbara! Mo ti mọ ọ ọjọ ti pẹ. Ha? Awọn ara aye a tun ni kilode ti mo n pe ẹyin mejeji ni ọmọdebinrin? O daa, yin ọdọbinrin abi iyale ile si ni".
O sọ eyi tori oju ti awọn eeyan le maa fi wo o pe o n fi oju keree awọn olorin naa.
O ni ohun ti oun ṣaa n gbiyanju lati fihan ni pe oun nifẹ awọn mejeji oun si bọwọ fun wọn atipe oun fẹ rere fun wọn tori eyi lo yẹ fun gbogbo ẹni to ba n ṣe iru iṣẹ ti awọn n ṣe yii ni oniruuru ọna amọ lati mu adun ba aye awọn eeyan.

Oríṣun àwòrán, Adeyinka Alaseyori
"O kan maa n da mi laamu nigbakuugba ti ẹ ba ri mi ti ẹ wa n kunlẹ kiri. Ka sọ tootọ, ko to iyẹn rara. Kẹẹ dẹ tun wa gbọ, mi o ki n ẹ "Mummy o".
O ni "Tani Mummy yín gan ná? Ha. Àṣejù ni Mọ́mì, Àntí Ṣolá ti wà okay."
Sola Allyson ṣalaye pe kii ṣe pe oun fi ọrọ yii sita tori ki wọn ma le ki oun daadaa mọ lawujọ o, ṣe lo tun daa si yẹyẹ pe bi wn ba ṣe bẹẹ oun a fi ti Anti kilọ fun wọn ni amọ oun ti fi ẹjọ wọn sun awọn aye toun si mọ pe o ti ye wọn.
Ṣe ni agba orin naa tun kẹnu bọ adura to ṣe fun awn mejeji pe wọn o ni ri idadura ninu ogo wọn to n tan.
Esi Yinka Alaseyori
Ninu esi gbajugbaja olorin Adeyinka Alaseyori ti oun naa da pada bii esi lẹta si Sola Allyson lo ti ṣalaye pe oun ko gba ọna to ni ki oun yipada lati maa ki i.
O ni oun mọ pe aṣa Yoruba ko gba ki eeyan maa da agbalagba lohun ọrọ ni gbangba am to ba ti jẹ oun (Allyson) ni ọkan oun balẹ.
Alaseyori ni oun le ṣe ki oun ma kunlẹ ki Allyson oun si ṣetan lati ri ti yoo ṣe fun oun. "Abi bawo la ba tun ṣe mọ riri ẹni to ti ṣe to to bayii to si tun n ṣe sii fun ijọba Ọlọrun, ni temi o, mo gbudọ bọwọ fun un yin".
O ni oun tọrọ aforijin bi o ba ri bakan lara Sola Allyson am oun ko mọ boya oun lee dawọ bibọwọfun un duro lọna to dara ju ti oun mọ.
"Ẹ kan ṣaa boju wo ọgọọrọ ọkan ti ẹ ti bukun fun ti ẹ si tun n jẹ ibukun fun. Iranlọwọ Ọlọrun nikan lo le jẹ ki ẹ ṣe eyi ibi ti emi naa si fẹ lọ niyẹn".
"Maami tootọ, oh Aunty mi mo lero pe mo ti yi ọkan yin pada lai da a ru pe ibọwọ fagba ni ọna to tọ".

Oríṣun àwòrán, Alaseyori

















