Cute Abiola: Àlàyé ohun tójú Abdulgafar Abiola rí láhàmọ́ iléeṣẹ ogun ojú omi tó ti ń ṣiṣẹ́ rèé

Cute Abiola

Oríṣun àwòrán, Cute Abiola

"Lootọ gbogbo irun ori ati irungbọn Cute Abiola lo ti kun gidi nigba ti mo de ọfiisi rẹ lọjọ ti wọn tu u silẹ tori o ti lo ọjọ mejindinlọgbọn latimọle amọ ẹ o tun ri i pe o ti bu sara".

Gbajumọ adẹrinpoṣonu to tun jẹ ọmọ ogun oju omi nileeṣẹ ogun Naijiria, Abdulgafar Abiola ti ọpọlọpọ mọ si Cute Abiola ti ni ki awọn ololufẹ rẹ maa reti awọn ẹ̀fẹ̀ tó tun le ńlẹ̀ síi.

Nigba ti ọrẹ rẹ timọ timọ ba BBC Yoruba sọrọ lẹyin ti wọn tu u silẹ, o jẹ ko di mimọ pe ṣaaju ọjọ ti wọn ju u si ahamọ o yẹ ki oun ati Cute Abiola jọ lọ fun ere kan ti gbajugbaja oṣere kan Femi Adebayo pe awọn mejeeji si amọ awọn pada yii pada si ọjọ keji.

O ni kii ṣe fiimu Femi Adebayo lo fa wahala yii atipe ile iṣẹ ogun oju omi gan ko tabuku fiimu ẹnikẹni bikoṣe pe Cute Abiola to jẹ oṣiṣẹ wọn nikan lawọn ba lọrọ.

"Nigba to fi di alẹ ni mámà (iyawo Cute) pe mi pe "Always" ṣe ẹ ti gbọ? gbọ kinni, wọn awọn o tii ro Cute nile awọn dẹ gbọ pe ileeṣẹ ogun oju omi ti ti i mọ ahamọ".

Àkọlé fídíò, Ibadan Young Girl: Obi Demilade salaye iru iku to pa ọmọ wọn

Mc Always ni nkan kekere lawọn kọkọ pe e gẹgẹ bi awọn ololufẹ rẹ naa ṣe n lero amọ nigba ti awọn ma fi de ibẹ, awọn ọga rẹ bẹrẹ si ni sọ pe awọn o le ri i".

O ṣalaye pe kii ṣe ti pe o n gbadun lahamọ to n jẹ itan adiyẹ tabi gbogbo kugu aye amọ o ṣe afiwe pe ko si iru ounjẹ ti wọn le fun eeyan ni ahamọ to le dabii ki ẹni naa ri itusilẹ gba.

Ọrẹ rẹ yii lo sọ fun wa pe nigba to ṣe diẹ ni awọn ọga kan gba ki oun nikan maa ri Cute Abiola soju to ba ti wa yẹ ẹ wo titi to fi di ọsẹ to koja yii lo ni wọn to dẹlẹ fun un ti wọn n jẹ ki iyawo ati iya rẹ naa maa wa foju kan an.

Ṣe wọn fiya jẹ Cute Abiola gidi ni tabi wọn fi atimọle ọjọ 28 fa a leti?

Mc Always jẹ ko di mimọ pe kii ṣe pe ileeṣẹ ologun oju omi sọ ọ sita pe ki wọn fiya jẹ Cute Abiola o, "amọ kii ṣe gbogbo ọrọ ni a le sọ jade bayii, bi asiko ọrọ ba to, a o sọ ọ".

"Mo bu Ileeṣẹ ogun oju omi o, a mọ nkan ti oju wa ri amọ boya ṣe wọn lu u tabi wn o fiya jẹ ẹ, emi o le sọ ọ jade bayii.

O ni ọrọ ko tii to sọ.

Aworan Cute Abiola

Oríṣun àwòrán, Facebook/Thecuteabiola

Ki wa ni ẹṣẹ rẹ gangan?

"Awọn ẹṣẹ ti wọn sọ fun wa pe Cute Abiola ṣẹ pọ gidi koda gbogbo ọrọ tun n pin si ida meji eyi ti Yoruba yoo si tumọ gẹgẹ bi irọ".

O ni lakọkọ, Cute Abiola ko gbe fọto alabaṣiṣẹ rẹto wa aṣọ ibi iṣẹ sori ayelujara, irọ ni kẹẹ lọ wo oju opo Cute Abiola.

"Lẹẹkeji, kii ṣe ibọn gidi ni Cute Abiola gbe dani ninu fiimu Jennifer's diary ti wọn ni o lo ibọn. "Props lasan ni, aṣọ ti wọn tun ni o wọ aṣọ Ọlọpaa, irọ ni, Costume lasan ni koda o fẹẹ fara jọ aṣọ awọn "Security".

O jẹ ko di mimọ pe gbogbo aṣọ tẹẹ ba ri ninu ere ẹfẹ Cute Abiola, aṣọ itage ti awọn to ni ere ko wa ni.

O ṣalaye eyi tori o ni awọn eeyan n sọ ọ kaakiri pe lootọ ni Cute ṣẹ to lo ibọn ti wọn ni ko maa fi ṣọ ibi iṣẹ amọ "mo fẹ rọ yin ki ẹ lọ wo o daadaa tabi ki ẹ tilẹ lọ bi Funke Akindele leere".

Cute Abiola: Abdulgafar Abiola dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ lẹyìn tí iléeṣẹ́ Navy tú u sílẹ̀

Iroyin naa jẹ eleyi ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ ti n reti to si mu idunnu ba wọn nigba to pada wa di ododo.

Bẹẹ lọrọ ri nigba ti aworan ati ọrọ idupẹ jade soju opo Abdulgafar Abiola, Cute Abiola adẹrinposonu ti awọn ọmọ ogun ori omi Naijiria, Navy tu silẹ lọjọ Aje.

Olokiki adẹrinposonu yi to tun jẹ ọmọ ileeṣẹ ologun ori omi ti fẹẹ lo to oṣu kan ni ahamọ lori ẹsun pe o tako ofin ileeṣẹ naa ti ko tẹle ilana ọmọ ogun ori omi.

Àkọlé fídíò, Ibadan Young Girl: Obi Demilade salaye iru iku to pa ọmọ wọn

Laarin igba to fi wa ni ahamọ yi, ọpọ awọn ololufẹ ati ọrẹ rẹ lo fi aidunnu han si bi wọn ko ṣe rii.

Lẹyin ọpọ ọjọ ati awuyewuye lori ọrọ yi, wọn ti wa pada fi Cute Abiola silẹ to si ti darapọ mọ awọn mọlẹbi rẹ.

Aworan Cute Abiola

Oríṣun àwòrán, Instagram/thecuteabiola

Loju opo rẹ ni Facebook ati Instagram, niṣe lo fi aworan ara rẹ sibẹ to si sọ pe ''eeyan le ni lati ja ogun lọpọ igba ko to le bori, mo dupẹ lọwọ gbogbo yin''.

Ki lo wa kan bayi?

Igba akọkọ kọ niyi ti awọn ileeṣẹ ologun yoo fa Cute Abiola leti lori iṣesi rẹ gẹgẹ bi ọmọ ileeṣe ọmọ ogun ori omi Naijiria.

Nigba to ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ to si fi aṣọ ọmọ ogun ya aworan, wọn kilọ fun pe ko ma ṣe iru rẹ mọ toun naa si tọrọ aforijin.

Amọ eleyi ti wọn mu u kẹyin yi to si pẹ ni ahamọ lo buru julọ ninu sẹria ti wọn da fun un.

Aworan Cute Abiola

Oríṣun àwòrán, Facbook/Thecuteabiola

Boya yoo wa tun ja ogun mii pẹlu ileeṣẹ ologun ori omi ko to le bori ko ye wa ṣugbọn ko sọ oun ti yoo ṣe bayi.

Awọn kan tilẹ n sọ pe boya ko fi iṣẹ Navy silẹ ko gbajumọ awada to n se ṣugbọn ko tii daju boya yoo tẹle amọran yi.

Bo tilẹ jẹ pe awọn ololufẹ rẹ kan n sọ pe ko ṣe jẹjẹ nidi awada to yan laayo, Cute Abiola fun ara rẹ ko tii sọ pato nkan to kan bayi.

Eyi to daju bayi ni pe yoo darapọ mọ awọn mọlẹbi rẹ ti yoo si kọkọ kan si ile gẹri gẹri lati fa irungbọn ati irun rẹ to kun latari bo ṣe pẹ ni ahamọ.