Nigeria Navy vs Cute Abiola: Ilééṣé ológun tí sòrò nípa òhun tó ṣokunfa atímọlè Cute Abiola

Oríṣun àwòrán, Facebook/thecuteabiola/Nigerian Navy
Ileeṣẹ ologun ori omi ti pada ṣalaye idi ti wọn fi sọ gbajugbaja oṣere apanilẹrin Cute Abiola si ahamọ.
Wọn ni Cute Abiola ko sọnu si ibi kankan ati pe iroyin ẹlẹjẹ gbaa leyi jẹ.
Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita ni idahun si ariwo to gbode nipa ibi ti Abiola wa, wọn ni ahamọ awọn ni Abiola wa nitori awọn ẹsẹ kan to ṣẹ.
Ọgagun Suleman Dahun to fọwọ si atẹjade yi lorukọ Ọga agba ileeṣẹ ologun yii sọ pe o tapa si ofin ileeṣẹ naa nipa lilo opo ayelujara ni .

Oríṣun àwòrán, Nigerian Navy
Ọnà ayédèrú ní wọn gbà gbé àbájáde ìwádìí Endsars tàwọn èèyàn n sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ jáde - Ọgágun Irabor
Bẹẹ lo ṣalaye pe o kọ lati tẹle awọn aṣẹ kan tawọn pa fun.
''Ileeṣẹ yi fi asiko yi sọ fun awọn oṣiṣẹ rẹ lati rii pe wọn tẹle aṣẹ ati ilana ologun to ni ṣe pẹlu lilo awọn oju opo ayelujara.''
''Ilana yi wa lati daabo bo awọn ọmọ ogun ati iṣẹ ta baa n ṣe lẹka ọmọ ogun orileede Naijiria''.
Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju ki ikede yi to jade?

Oríṣun àwòrán, Facebook/thecuteabiola
Iléeṣẹ́ Navy dákẹ́ lórí ibi tí Cute Abiola há sí àmọ́ àṣírí tí agbẹjọ́rò rẹ̀ tú fún BBC rèé
Agbẹjọro apanilẹẹrin Cute Abiola ti iroyin gbode pe o di awati ti ṣalaye ibi ti arakunrin naa wa.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ileeṣẹ BBC, Fatai Adebanjo sọ pe ahamọ ileeṣẹ ọmọ ogun ori omi ni Cute Abiola wa.
Amọ ṣa agbẹjọro naa ko sọ idi ti awọn ileeṣẹ yi ti Cute Abiola n ba ṣiṣẹ fi mu u kalẹ lai fi to awọn mọlẹbi rẹ leti.
Ninu alaye rẹ, agbẹjọro Fatai sọ pe Abiola ti orukọ abisọ rẹ n jẹ Abdulgafar Ahmed kuro nile to si wọ iṣẹ ni ileeṣẹ awọn ọmọ ogun omi to wa ni NNS Ojo l'Eko.
Ṣugbọn nigba ti yoo fi di ọjọ Iṣẹgun to yẹ ko pada sile, awọn ọrẹ ati mọlẹbi ko ri.
Airi Cute Abiola yi lo mu ki wọn ke gbajare ti ọrọ naa si di nkan to gbode kaakiri oju opo ayelujara.

Oríṣun àwòrán, Facebook/thecuteabiola
Agbẹjọro ọhun tẹsiwaju pe nigba toun de ọfisi rẹ loun rii pe o wa ni ahamọ ṣugbọn ko si ẹnikankan to ṣalaye idi to fiwa nibẹ.
Iroyin ti a n kẹfin ni BBC ni pe o ṣeeṣe ki ahamọ yi ni nkan ṣe pẹlu aworan kan ti Abiola fi sita laipẹ yi.
Ninu rẹ a ri pe o gbe ibọn AK47 lọwọ ninu ere fiimu kan to n ba wọn kopa ninu rẹ

Oríṣun àwòrán, thecuteabiola
Ọnà ayédèrú ní wọn gbà gbé àbájáde ìwádìí Endsars tàwọn èèyàn n sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ jáde - Ọgágun Irabor
Ohun to ṣe yi labẹ ofin awọn ileeṣẹ ọmọ ogun ori omi tapa si ofin.
Oṣiṣẹ wọn ko gbọdo gbe ibọn dani laiṣe pe o wa nidi iṣẹ.
Gẹgẹ baa ṣe gbọ, lọdun to kọja wọn fi si atimọle nitori pe o ya aworan pẹlu aṣọ ologun lọjọ ayajọ ibi rẹ.
Titi di ba ṣe n ko iroyin yi jọ, BBC ko tii ribi ba ọga ẹka iroyin NNS WEY, Ọgagun Okiewalu N.A sọrọ.
Gbogbo ipe wa sori ago rẹ ko ti ri idahun lati le ṣalaye ẹsẹ ti Cute Abiola ṣ to fi di ero atimọle

Oríṣun àwòrán, Facebook/thecuteabiola
À ń wá Gbajúmọ̀ apanilẹ́ẹ̀rín, Cute Abiola o! A kò gbúrò rẹ̀ nílé - Mọ̀lẹ́bí
Gbajugbaja apanilẹrin, Abdulgafar Ahmad Oluwatoyin, ti awọn ololufẹ rẹ tun mọ si Cute Abiola ti di àwátì.
Oluwatoyin to tun jẹ ọmọ ogun ori omi, ni akẹgbẹ rẹ ninu iṣẹ awada ṣíṣe, Mr Macaroni, kede loju opo Twitter rẹ pe ẹbi ati ọrẹ rẹ n wa.

Oríṣun àwòrán, Mc ALways
Ikede naa sọ pe ọjọ Aje, ọjọ kẹẹdogun, oṣù Kọkanla, ni iyawo Cute Abiola ati awọn alajọṣiṣẹpọ rẹ ti gburo rẹ kẹhin.
Iroyin sọ pe ni nkan bi aago mẹfa owurọ ọjọ naa lo kuro nile, lati lọ si ibi isẹ rẹ nileeṣẹ ọmọ ogun ori omi. O de ibi isẹ ni nkan bi aago meje, o si pe iyawo rẹ lati jẹ ko mọ pe oun ti de ọfiisi.
Lati igba naa si ni oun ati awọn alajọṣiṣẹpọ ti gburo rẹ mọ.
"Lẹyin to pe iyawo ati awọn alajọṣiṣẹpọ rẹ pe oun ti de ibi iṣẹ, ko ti i pada sile lọdọ ẹbi rẹ, bẹẹni ẹnikẹ́ni ko gburo rẹ titi di asiko yii."
Ṣugbọn sa, iroyin kan ti a ko tii fidirẹmulẹ sọ pe inu ahamọ ileeṣẹ ọmọ ogun ori omi lo wa lati igba to ti de ibi isẹ lọjọ Aje.
Bẹẹni ko si ẹni to mọ ẹ̀sùn ti wọn fi kan an, eyi to gbe de atimọle.
Iroyin naa tun sọ pe lati olu ileeṣẹ ologun naa ni àṣẹ ti wa pe ki wọn o fi Cute Abiola si ahamọ.
Ni odun 2020, ileeṣẹ ologun ori omi ti fi si ahamọ ri, "nitori pe o fi aṣọ ologun ya aworan ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ, to si tun fi aworan naa sori ayelujara Instagram.
Taa ni Cute Abiola?
Ọmọ ilu Ilorin, nipinlẹ Kwara ni Abdulgafar Ahmad Oluwatoyin.
Ọdun 1996 ni wọn bi.
O si ti bẹ̀rẹ̀ isẹ apanilẹrin lati kekere. Sugbon o di ilumọọka lati ọdun 2015.
Oṣù Karun-un, ọdun 2021 lo ṣe igbeyawo.
Òṣìṣẹ́ ọmọ ogun ori omi Naijiria, Nigerian Navy ni.
Bakan naa lo tun jẹ apanilẹrin ati oṣere ori itage.


















