Oyingbo Market Protest: Folashade Tinubu ti ọjà Oyingbo pa torí N5m, àwọn ọlọ́jà ń ṣe iwọ́de

Folashade Tinubu-Ojo

Oríṣun àwòrán, Folashade Tinubu-Ojo

Iyaloja Gbogboogbo nipinlẹ Eko, Arabinrin Folashade Tinubu-Ojo ti fesi si iwọde ti àwọn ọlọja kan ni Oyingbo ṣe.

Owurọ Ọjọ́rú ni awọn ọlọja naa ṣe iwọde, ti wọn si fi ẹ̀sùn kan Iyaloja naa pe o ti ọjà pa fun ọ̀sẹ̀ meji, to si tun n beere miliọnu marun Naira lọwọ wọn.

Ṣugbọn ninu ọrọ to sọ fun BBC Yoruba, Arabinrin Tinubu-Ojo sọ pe nitori obitibi ìdọ̀tí to wa ninu ọgbà ile itaja naa ni òun ṣe ti i pa.

Àkọlé fídíò, Itunu Babalọla Death:Àgbáyé ẹ gbà mí, mọ fẹ́ ìdájọ́ òdodo lórí ikú ọmọ mí! ìyà yí tí pọ̀jù

O ni koda, gbogbo sọọbu to wa ni àwọn òkè 'complex' naa ni wọn pati, ti gbogbo wọn si n ta ọjà ni ìsàlẹ̀ ati oju ọna.

Ọja Oyingbo

Oríṣun àwòrán, OTHERS

"Ọpọ igba ni àwọn to ma n na ọjà Oyingbo ti fi ẹ̀sùn ransẹ si mi pe ọjà naa ti dọti ju."

"Bẹẹ ni mo si baa nigba ti mo ṣe abẹwo síbẹ̀. Koda, agidi ni mo fi raaye gbe ọkọ wọlé nitori ìdọ̀tí to kun gbogbo ọjà naa."

Àkọlé fídíò, Ọdún 1999 ni mo tí ń gbìyànjú láti gba SAN kí wọ́n tó fún mí ẹ̀ní ọdún 90 -Toriola Oyewo

Arabinrin Tinubu-Ojo ni alaga ìjọba ibilẹ agbegbe Oyingbo lo kọkọ ti ọjà naa.

O ni lati bi ọ̀sẹ̀ bii mẹta ni àwọn òṣìṣẹ́ akolẹ ko ìdọ̀tí ti n ko ìdọ̀tí ninu ọjà naa.

O sọ pe lati ìbẹ̀rẹ̀ pẹpẹ ni oun ti sọ fun àwọn ọlọja naa pe o di igba ti isẹ àtúnṣe ba pari, ki ọjà naa to di ṣíṣí pada.

Bakan naa lo sọ pe owo itanran fun pe ọjà dọti lai naani gbogbo ikilọ, ni miliọnu marun-un Naira ti wọn ni ki awon ọlọja naa san.

Àwọn ọlọ́jà ní Oyingbo ṣe iwọ́de, wọ́n ní Folashade Tinubu ti ọjà pa torí N5m

Àwọn ontaja kan ninu ọjà Oyingbo, ọkan lara awọn ọja nla nipinlẹ Eko ti n ṣe iwọde tako ẹni to jẹ Iyaloja gbogboogbo nipinlẹ Eko, Arabinrin Folashade Tinubu-Ojo.

Owurọ Ọjọ́rú, ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù Kọkanla, ni iwọde naa waye ni Oyingbo.

Orisirisi akọle ni àwọn ọlọja naa gbe dani, lara eyi ti a ti ri "Gbogbo Eko, ẹ gba wa lọwọ ọmọ Tinubu, o ti ba Oyingbo jẹ."

Ọja Oyingbo

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ẹnikan to jẹ onisẹ ọwọ ni Oyingbo, àmọ́ ti ko fẹ ka darukọ rẹ sọ pe lootọ ni Iyaloja naa ti abala kan ninu ọjà Oyingbo pa.

O ni abala to jẹ àwọn sọọbu ti wọn kọ (shopping complex) ni ọrọ naa kan.

O sọ pe iroyin ti oun gbọ ni pe Iyaloja náà, Folashade Tinubu-Ojo pasẹ fun àwọn to n lo àwọn sọọbu ọhun, to fi mọ awọn to n taja lẹgbẹ titi, pe ki wọn o da miliọnu marun Naira jọ, ki wọn o si fi ransẹ si oun.

Ọja Oyingbo

Oríṣun àwòrán, OTHERS

"Nitori pe àwọn ọlọja naa ko ko owo lọ, lo ṣe ti àwọn ile itaja wọn pa lati fun ọsẹ meji.

Ninu fidio iwọde ọhun to wa lori ayelujara, nise ni àwọn ọlọja, paapaa àwọn to n ta nkan ti ẹnu n jẹ, n da awon oúnjẹ bi gari, irẹsi, anamọ l, ẹ̀fọ́, ati bẹẹ bẹẹ lọ, si oju titi.

Wọn ni bi wọn ko ṣe jẹ ki àwọn si sọọbu ti ba àwọn ọjà naa jẹ.

Botilẹ jẹ pe a kò tii le sọ nkan to mu Iyaloja naa ṣe bẹẹ, àwọn iroyin kan ni nitori pe àwọn ọlọja naa kii tun ọjà ṣe, to si ma n kun fun ìdọ̀tí ati ẹ̀gbin lo fi ṣe bẹẹ gẹgẹ bi ìbáwí.

Àkọlé fídíò, Àwọn ọmọ ọkùnrin mẹ́tà ló timi mọ́lé tí wọ́n n bá mi sùn lójoojúmọ́ ni Libya