Sheikh Ahmad Gumi: Kíni ìdi tí Gumi fi kọ́ ilé ẹ́kọ́ fáwọn Daran-daran Fulani?

Sheik Gumi

Oríṣun àwòrán, Google

Gbajugbaja adari ẹsin Islamu lorilẹede Naijiria ati olubadamọran awọn agbesunmọmi, Sheikh Ahmad Gumi, ti ṣalaye awọn idi tó fi kọ ile-ẹkọ kan, ile-iwosan ati ikẹkọ iṣẹ akanṣe fun awọn Fulani darandaran ti o wa ni ipinlẹ Kaduna.

O sọ fun BBC pe oun ti kọ Sheikh Uthman Bin Fodio Centre ni Kagarko, nitosi igbo Kohoto ni Ipinle Kaduna lati kọ awọn darandaran.

Gege bi o ti so, kikọ awọn darandaran ni eko ati ipese awon ohun elo to dara julo ni ona ti o dara ju ni lati fopin si eto ààbò tó mẹ́hẹ ni ariwa Naijiria.

Bi oluko naa se n fi hàn pe oun lo sinu igbo ti awon ọmọ ologun ti n gba aabo, ti won si n waasu, ti won si n rọ won pe ki won gbe ohun ija silẹ ti da awuyewuye sile ni orile-ede Naijiria, ti awon agbegbe kan si n bu ẹnu atẹ lu iwa rẹ gẹ́gẹ́ bí àfihàn àtìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ibi tí wọ́n ń ṣe.

Sheikh Ahmad Gumi sọ pé àìsí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ló jẹ́ ọ̀kan lára ​​ohun tó ń fa ìṣòro ààbò ní àríwá Nàìjíríà.

Àkọlé fídíò, Itunu Babalọla Death:Àgbáyé ẹ gbà mí, mọ fẹ́ ìdájọ́ òdodo lórí ikú ọmọ mí! ìyà yí tí pọ̀jù

Eyi jẹ ọkan ninu awọn idi ti Alfaa naa fi sọ pe oun n ṣe ifilọlẹ ipolongo itusilẹ ni àwọn àgbesumọmi ni ipinlẹ Kaduna ati awọn ipinlẹ miiran lati kọ wọn ati awọn olùgbé agbegbe naa.

Ó ṣàwárí ìṣòro àwọn olùṣọ́ àgùntàn nípa bó ṣe bá wọn lò nígbà tó lọ wàásù fún wọn nínú aginjù.

Idi ti a fi kọ ile-iwe naa

Sheikh Gumi sọ fun BBC pe idi pataki ti oun fi pinnu lati ṣí iru ileewe bẹẹ ni bi iṣoro aimọ-iwe ṣe pọ si ni Naijiria.

Gẹ́gẹ́ bi o ti so, pelu ipese eto eko ati awon ohun elo miran lawujo, wahala ati awon ọrọ aabo miiran yoo yanju.

“Nígbà gbogbo bi ẹ ba wo nnkan to n dun wa nile yii, ẹ ẹ ri i pe aimọkan lo n se wọn, ati pe eni to ba ye ko kawe, niwon igba ti ileewe ba wa, ti awon molebi ẹ si mọ pe oun n bọ ọ, kò ní fẹ lati fa wàhálà, nítorí kò ní fẹ́ nnkan ti yoo ba eto ẹkọ wọn jẹ. "

O ni oun gbagbọ pe ile-iwe naa yoo ṣe iranlọwọ lati mu alaafia ba agbegbe ni Naijiria.

Ile-iwe naa, ni ibamu pẹlu alasilẹ ìjọba gẹgẹ bi Sheikh Gumi ṣe sọ, ó ni awọn yara ikawe mẹfa, eyiti yoo pese ipele ti eto-ẹkọ bii awọn ile-iwe alakọbẹrẹ ati gírámà máa ń ní.

Awọn yara ikawe nla tun ti wa lati pese ikẹkọ iṣẹ-ọwọ fun awọn ọkunrin ati obinrin.

Àkọlé fídíò, Àwọn ọmọ ọkùnrin mẹ́tà ló timi mọ́lé tí wọ́n n bá mi sùn lójoojúmọ́ ni Libya

"Awọn obìnrin yoo kọ isẹ aṣọ ríran, ọsẹ ṣíṣe àti àwọn nǹkan mìíràn, nigba ti awọn ọkunrin yoo kọ iṣẹ kafinta àti àwọn àti bẹẹbẹ lọ." bí Gumi ṣe sọ.

Ni afikun si ileewe naa, olukọ naa sọ fun BBC pe oun ti kọ ile iwosan fun awọn darandaran lati ran wọn lọwọ lati ni ilera paapaa awọn alaboyun ti Sheikh Gumi sọ pe wọn n jiya ninu igbó, awọn akosemọsẹ oníṣègùn ti wọn lọ káàkiri lo n mójú tó wọn.”

“Nitori naa ti wọn ba ni awọn aaye bii eyi, wọn yoo ni igbeaye ti o rọrun lati bimọ.

Sheikh Ahmad Gumi sọ pe awọn ti ṣeto fun ẹgbẹ awọn olukọ Fulani lati ṣe iranlọwọ fun ṣiṣe ile-iwe naa.

O ni o se pataki fún awon oludamoran pàtàkì fún ìjọba lórí eto eto aabo lati wọ inu igbo ki won lo ye awon isoro ti awon darandaran n koju wo, lati le se agbekale awon ohun elo amayederun ti yoo se iranlọwọ lati koju awon ipenija aabo.