Sheik Gumi, Banditry in Nigeria: Ọ̀run àpáàdì ń dúró de gbogbo ẹ̀yin aláìní ìrònúpìwàdà- Fani Kayode sí Gumi

Gani Fawehinmi Gumi

Oríṣun àwòrán, others

Ọ̀run àpáàdì ń dúró de gbogbo ẹ̀yin aláìní ìrònúnupiwada - Fani Kayode sí Gunmi

Mínísíta ìrìnà òfurufú nígbà kan rí Femi Fani-Kayode tí bẹnu àtẹ́lu ọ̀rọ̀ tí Sheik Ahmad Gumi tó ń sọ pé kí ìjọba àpapọ̀ bá àwọn ọ̀daràn ajínigbé pawó ni gbólóhùn kàkà kí wọ́n pawọ́n dànù.

O ni laipẹ laijina ni onikaluku maa jere iṣẹ ọwọ rẹ ni eyi to maa jẹ ki awon kan wọ ọrun apaadi ni.

Nínú Ìfọ̀rọ̀wànilẹ́nuwò kan lọ́jọ́ Ajé lọ tí sọ pé kò sí ilé ìwé tí yóò ní àlàáfíà àfi tí ìjọba bá dúnadúrà pẹ̀lú àwọn jàndùkú.

Ó ṣàpèjúwe ọ̀daràn bí àwọn tí wọ́n ń fìyà jẹ ti ó sì kìlọ̀ fún ìjọba láti má dábà á pípa wọ́n.

Àkọlé fídíò, Fulani attack, Ajowa Ondo: Àwọn Bororo yìí ti kọ́kọ́ ń dàná ní Ajọwa tẹ́lẹ̀, ọmọ mi 5 di

Lásìkò to ń fèsì si ọ̀rọ̀ Gumi Fani-Kayode bẹnu atẹ́ lu ọ̀rọ̀ ọkùnrin náà tí ó sì gba àwọn ọlọ́pàá níyànjú láti pá àwọn ọ̀daràn tí wọ́n mú yìí dànù.

Femi Fani Kayode ni: "Ẹ tẹ́ti sí ọkùnrin tí kò ní ọkàn ènìyàn tó ń gbèti àwọn ají ọmọ gbé àti apànìyàn. Ènìyàn burúkú, ẹranko àti aláìnírònúpiwàdà" lójú òpó Facebook.

Àkọlé fídíò, End SARS: Kemi jáde níle láti lọ bá mi ra oògùn ni mo gbọ́ pé ọlọ́pàá ti gbée- Ìyá Kemisol

"Gbogbo àwọn olùtàjẹ̀sílé, agbesùmọ̀mí àti àwọn agbénipawo yẹn ló yẹ kí wọ́n pá dànù kí wọ́n sì rán wọn lọ sí ọ̀run àpáàdì.

Àwọn tí wọ́n ń gbẹnu wọn sọ̀rọ̀, tí wọ́n ń gbè tí wọ́n tí wọ́n sì ń bá sì bá wọ́n wá awawi pé nǹkan tí wọ́n ṣe dára nílò láti kojú nǹkan tó burú jáì, kódà ọrùn àápàádi ló yẹ́ wọ́n

Sheikh Ahmad Gumi

Oríṣun àwòrán, Facebook/Dr Ahmad Abubakar Mahmud Gumi

Ó yẹ kí ìjọba wá ǹkan fi tan àwọn ajínigbépawó, ǹkan bíi owó, iṣẹ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ

Kò lè sí ààbò fún iléẹ̀kọ́ kankan àfi tí ìjọba bá wá iṣẹ́ fáwọn tó ń jí ọmọ gbé - Gumi

Ilumooka ààfáà ẹṣin Islam kan to tun máa n ba awọn àgbesunmọmi at'awọn ajinigbe sọrọ pẹlẹ kutu, Sheik Gumi ti ni o to egberun lọnà ọgọrun agbebon lo wa ni iha Ariwa Iwo Oorun Naijiria nikan.

Gumi ni kii ṣe pe wọn n doju kọ ẹsin kankan, o ni ka ma tun gbagbe pe wọn o kawe yala lọnà lilọ ileewe ni tabi labẹ ile.

"Wọn kan n rin kiri pelu maalu ni ti wọn sì saadede ri iṣẹ tó lee pawo wọlé fún wọn".

Amọ Gumi ni pẹlu ibanisọrọ, kikọni ni ẹkọ, at'awọn nkan taa le fi tan èèyàn bíi iṣẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ, won a fi iṣẹ yìí silẹ.

Gumi ni awọn agbebọn to n ji awon akẹ́kọ̀ọ́ gbe gẹgẹ bí ẹ ṣe n gbọ lọtun ati losi banuje pe oun n ba awọn duna dura lai ni ọwọ ìjọba àpapọ̀ nínú.

Aafaa yìí ni dandan, o di igba ti ijọba ba ba awọn Fulani darandaran sọrọ, ko lè sí ileewe kankan ti abo rẹ daju.

Àkọlé fídíò, Àṣírí ìdí tí ìjínigbé fi ń ṣẹlẹ̀ ní Nàìjíríà ló tú nínú fídíò yìí

O sọrọ yii nigba to ba iwe iroyin Punch sọrọ lori akitiyan to n jade lati doola awọn ọmọ ileewe Tegina Islamic School ni ipinle Niger.

"Awọn ajinigbepawo ọhun n beere fún ìgbà mílíọ̀nù naira ti wọn si pada din in ku si aadojo mílíọ̀nù naira".

Gumi ni pẹlu bi akitiyan láti doola wọn ṣe pọ to, awọn ajinigbe ohun duro lori ọrọ wọn fún owo ti wọn beere fun.

Àkọlé fídíò, End SARS: Kemi jáde níle láti lọ bá mi ra oògùn ni mo gbọ́ pé ọlọ́pàá ti gbée- Ìyá Kemisol

O ni amọ awọn ti n ba wọn sọrọ ọpọlọ pe awọn ọmọ ileewe yii ko mọwọ mẹsẹ.

Gumi fi kun un pe lori ọrọ awọn akẹkọọ musulumi yìí, o ti fi aridaju hàn fun orilẹede pe awọn ajinigbe naa,

"ope niwọn wọn ni iriri igbaniwọ inu ẹgbẹ, wọn kan n wa owo lasan ni torinaa nkan to dara ni mo kaa sí".

"Amọ a nilo alabaṣiṣẹpọ, a sì nilo ìjọba lati ni oye nipa gbogbo eeyan. Emi nikan o le ṣe e".

Gumi tẹsiwaju pe gbogbo awọn tàwọn ti bá pade ti dawọ ijingbe duro ayafi ọkan ninu wọn to tun pada sinu èébì rẹ.

O ni o si so idi fún àwọn pe wọn pa oun ti lẹyin ti oun ro pe o yẹ ki idunadura waye.

Torí naa Gumi ni bi o ba ṣe ya si lati ba wọn sọrọ pọ, "awọn to ti pinu lati ko nkan ija silẹ, ẹo lo wọn lati tọju awọn to ku".

Àkọlé fídíò, Life saver car: Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ yì ti gba ẹ̀mí ọ̀pọ̀ aláboyún àtọmọ ọwọ́ lá ní Jigawa

Bo tilẹ jẹ pe ijọba ipinlẹ Niger n gbiyanju lati doola awọn ọmọ naa amọ Gumi ni wọn o ní to lati ṣe eyi.

Lo ba ni àfi laa o, "awọn ijọba ko lagbara lati da abo bo awọn ileewe lalai kọkọ wa ọna ati fopin sí ijinigbe.

"Tẹẹ ba fẹ aabo láwọn ileewe, eo ṣe kọkọ bá àwọn ajinigbe joko sọrọ? Lẹyìn náà, eo le ka iye wọn. Bẹẹ bá kan n lo awọn ọmọ ogun fi ba wọn ja, yóò bá iṣẹ yín jẹ síi ni o tori tẹẹ ba bẹrẹ sí ní pa ọmọ wọn, ẹ ma gbagbe pé àwọn náà ni àwọn ọmọ tiwa nikawọ wọn".