2021 Jamb UTME result: Wo bí o ṣe le wo èsì ìdánwò JAMB rẹ

Awon akẹkọọ to n ṣe idanwo Jamb

Oríṣun àwòrán, jamb.gov.ng

Esi idanwo JAMB fun ọdun 2021 ko ti i jade.

Ṣaaju ni awọn ileeṣẹ iroyin abẹle kan ti kede pe esi naa yoo jade ni Ọjọru, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹfa.

Ninu iroyin naa, iwe iroyin thecable sọ pe Ọga Agba ajọ naa, Ishaq Oloyede lo kede bẹẹ ni Ọjọru, nibi ipade apero kan nilu Enugu.

Ṣugbọn, agbẹnusọ ajọ JAMB, Fabian Benjamin, sọ fun BBC Pidgin ninu ifọrọwanilẹnuwo lori foonu pe esi idanwo ko ti i jade.

O ni awọn n duro de Ọga Agba, lati pada si olu ileeṣẹ ajọ naa nilu Abuja, lẹyin iṣẹ to lọ ọ ṣe ni ilu mii.

Ọgbẹni Fabian sọ pe ọga wọn ni yoo sọ asiko ti esi idanwo yoo jade.

Bi o ṣe n duro de esi idanwo JAMB ti o sẹ, wo bi o sẹ le yẹ esi idanwo rẹ wo nigba to ba jade tan:

Bi o ṣé le wo esi idanwo 2021 UTME JAMB lori ayelujara

  • Lọ si ori ayelujara ajọ JAMB ni https://portal.jamb.gov.ng/eFacility_/CheckUTMEResults
  • Tẹ nọmba iforukọsilẹ rẹ/imeeli si ibi to yẹ
  • Tẹ 'Check my results' lẹyin
  • Oju opo naa yoo gbe esi idanwo rẹ jade fun ọ
Àkọlé fídíò, Peter Fatomilola: Robbery burú ju Yahoo lọ, iṣẹ́ ọpọlọ lọmọ Yahoo fi ń gba owó ìran baba

Lati wo esi idanwo JAMB rẹ lori atẹjiṣẹ foonu 'SMS'

  • Lori nọmba foonu ti o fi silẹ lasiko iforukọsilẹ JAMB, tẹ RESULT ranṣẹ [SMS] si 55019
  • Ma gbiyanju rẹ lori nọmba ti ko si pẹlu ajọ JAMB
  • Ti o ba ti tẹ atẹranṣẹ naa, esi ti wa a ri ni pe "Dear...., esi idanwo rẹ lọ bayii... (wọn os i fun ọ ni gbogbo nkan ti o fẹ ẹ ri)
  • To ba wa jẹ pe ajọ JAMB ti gbẹsẹ le esi idanwo rẹ, esi ti wa a ri ni pe "Result Withheld'.
Àkọlé fídíò, Fisayo Amodemaja: Nínú eré 'Children Day' ní Sọ́ọ̀ṣì ni Abebi ti bẹ̀rẹ̀ eré ṣisṣe- Bukola

Àjọ JAMB ṣèlérí ìdánwò mìí fún àwọn tí NIN jákulẹ̀, ó tún fòfin de ibùdó CBT 25

Ajọ Jamb ti kede pe oun yoo pese anfaani mi fun awọn ti ko ni anfaani lati fi orukọ silẹ ninu idanwo UTME to n lọwọ, nitori nọmba NIN.

Awọn alaṣẹ Jamb sọ pe awọn yoo ṣe eto idanwo mii fun awọn ti ọrọ naa kan.

Àkọlé fídíò, End SARS: Kemi jáde níle láti lọ bá mi ra oògùn ni mo gbọ́ pé ọlọ́pàá ti gbée- Ìyá Kemisol

Saaju ni iroyin ti jade pe awọn akẹkọọ kan ko raaye fi orukọ silẹ lati sẹ idanwo UTME ti ọdun 2021, nitori ipenija ti wọn ni pẹlu NIN wọn.

O ni pe dandan ni fun awọn to ba fẹ ẹ ṣe idanwo naa lati lo NIN lasiko iforukọsilẹ.

Àkọlé fídíò, Fulani attack, Ajowa Ondo: Àwọn Bororo yìí ti kọ́kọ́ ń dàná ní Ajọwa tẹ́lẹ̀, ọmọ mi 5 di

Adele Ọga Agba ajọ naa, Shittu Biliaminu sọ pe ọrọ atunṣe idanwo naa yoo tun kan awọn akẹkọọ mii to tun ni ipenija lasiko ti wọn n ṣe idanwo wọn.

Wọn ni wọn yoo fi ikede sita lori ọjọ ti atunṣe idanwo naa yoo waye.

Bakan naa ni iroyin sọ pe ajọ naa ti fi ofin de awọn ibudo idanwo kan jakejado Naijiria.

Oludari ẹka ikede, Ọmọwe Fabian Benjamin sọ lọjọ Satide pe ki awọn akẹkọọ to yẹ ko ṣe idanwo ni awọn ibudo ti ọrọ kan, fi oju sọna fun itọna ati ilana ti wọn yoo tẹle lori nọmba foonu wọn, imeeli tabi akọsilẹ wọn lori ayelujara ajọ Jamb.

Àkọlé fídíò, 'CAC Agbala Itura ni mo ti bẹ̀rẹ̀ ìlú lílú kí ń tó máa bá Janet, àbúrò Michael Jackson lù Gangan àti Omele'

Ohun ti JAMB sọ ni pe awọn ibudo naa kuna lasiko idanwo to yẹ ko waye ni ọdọ wọn lọjọ Satide, ọjọ kọkandinlogun, ọdun 2021.

  • HARRY PASS POLYTECHNIC CBT CENTRE - Benue
  • IZISCO OBOS INSTITUTE OF MARITIME STUDIES AND TECHNOLOGY - Delta
  • OSENI ELAMAH ICT INSTITUTE - Edo
  • GIVITEC CBT CENTRE - Edo
Àkọlé fídíò, Bí wọ́n ṣe ya Sinima Ayinla Omowura rèé, BBC Yorùbá fọ̀rọ̀ wá àwọn òṣèré lẹ́nu wò
  • KINGS POLYTECHNIC - Edo
  • GEF SYSTEMS LTD, PUBLIC SERVICE INSTITUTE OF NIGERIA - Abuja
  • ABUJA GOVERNMENT SECONDARY SCHOOL - Abuja
  • ORU EAST CBT CENTRE (FOE ICT) - Imo
  • BETHEL BAPTIST HIGH SCHOOL - Kaduna
Àkọlé fídíò, Kini ‘technology’ ni ede Yoruba?
  • ZABIB COLLEGE - Kaduna
  • ST. ALBERT INSTITUTE - Kaduna
  • SKOLAK RESOURCES LTD - Kaduna
  • MASSINO COMPUTER CBT - Eko
  • IP SOFT TECHNOLOGIES LTD. - Eko
  • INSTITUTE OF CRIMINAL JUSTICE AND CRIMINOLOGY ADMINSTRATION - Eko
  • SWEET VALLEY EDUCATIONAL SERVICES - Eko
  • CERTIFIED INSTITUTION OF SHIPPING - Eko
  • AL-MIYZAN SCHOOLS CBT CENTRE - Eko
  • AUNTY ALICE SCHOOLS - Eko
  • THE FEDERAL POLYTECHNIC - Ile-Oluji, Ondo
Àkọlé fídíò, 'Ọwọ́ mi ti ń jẹ́rà ká tó mọ̀ pé àfi kí wọ́n tún gé e bí mo bá ṣì fẹ́ máa ṣe iṣẹ́ awakọ̀ lọ'
  • KING EMMANUEL COLLEGE ICT CENTRE - Ondo
  • ODUDUWA UNIVERSITY - Osun
  • FEDERAL COLLEGE OF EDUCATION (SPECIAL) - Oyo
  • PLATEAU STATE UNIVERSITY - Plateau
  • ST AUGUSTINE'S ACADEMY - Plateau
Àkọlé fídíò, Ẹ̀yin olórin ẹ̀mí tó ń bóra, lo èékáná gígùn, oò yàtọ̀ sí aṣẹ́wó hòtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n ń gbé bíi súùtì Pepper Menti - Bola Are