Fact Check: Ẹranko àìmọ́ kan wọ Nàìjíríà, ó pa ènìyàn mẹ́rin ni Benue- ilé iṣẹ́ ọmọogun ni ìròyìn òfegè ni

Eranko

Oríṣun àwòrán, others

Ilé iṣẹ́ ọmọogun Nàìjíríà tí sọ fún àwọn ènìyàn láti keti ìkún sì fọnran kan tó safihan ẹranko àìmọ tó ń jà rainrain lórí ayélujára.

Lójú òpó ìkànsíraẹni Facebook wọn ní wọ́n tí sàfihan rẹ bí ìròyìn òfégè ni, àtẹ̀jáde náà sọ pé àwọn ọmọogun pá ẹranko àìmọ kan ni ìpínlẹ̀ Benue.

Ìròyìn náà ni pé fọ́nrán kan ń jà rainrain lópin ọ̀sẹ̀ tó kọjá èyí tí ọ̀pọ̀ sì gbàgbọ́ pé ajá igbó ni lóòótọ́.

"Nǹkan tó jọ ajá igbó sì sùn silẹ tó nínú fọ́nrán náà tí ọkùnrin kan sì ń sọ èdè Pidgin pé tí wọn ba ni kí ẹ dúró sílè yín ẹ ó ní gbọ́

Defence

Oríṣun àwòrán, @DHQ

Fọ́nrán náà kan gbogbo àwọn ènìyàn nítorí pé wọ́n ń ìgbàgbọ́ pé ìkòkò tí wọ orileede yii.

Ṣùgbọ́n ilé iṣẹ́ ọmọogun sọ pé ìròyìn òfégè ni.

Àkọlé fídíò, Fulani attack, Ajowa Ondo: Àwọn Bororo yìí ti kọ́kọ́ ń dàná ní Ajọwa tẹ́lẹ̀, ọmọ mi 5 di

"Àtẹ̀jáde àti fọ́ran to lọ ká lórí ayélujára nípa ẹranko abàmì kan tó ní ara ènìyàn tí ọkàn nínú àwọn ọmọogun ikọ operation whirl stroke kíi ṣe ootọ́.

Wọn ni ojúlówó fọ́nrán náà jẹ ti eré sinima "Lobisomem Morto a Tiros".

Àkọlé fídíò, End SARS: Kemi jáde níle láti lọ bá mi ra oògùn ni mo gbọ́ pé ọlọ́pàá ti gbée- Ìyá Kemisol

Nínú àtẹ̀jáde ayédèrú náà ni wọ́n ti sọ pé ìlú Tempele lọ tí ṣẹlẹ̀ nípìnlẹ̀ Benue pé àwọn kan ló tá ikọ ọmọogun náà lolobo ri wọn sì pá ẹranko ọ̀hún.

Ile isẹ ọmọogun Naijiria ni, ẹni tó gbé ìròyìn ayédèrú náà síta ni Nàìjíríà gbé ohùn rẹ lè ojúlówó ohun tó wà nínú fọnran tí Cloud Wold ṣe.