Oyo State Security Governing Board: Makinde se ìfilọ́lẹ̀ ìgbìmọ̀ àlákòóso Amọtẹkun ó pè fún ìfọ̀wọ́sowọ́pọ̀ aráàlú

Oríṣun àwòrán, OfficialSeyiMakinde
Gomina ipinlẹ Oyo Seyi Makinde ni ijọba ipinlẹ Oyo yoo ṣiṣọ loju awọn ilana kan lati le koju ipenija aabo to ba ipinlẹ naa.
Lasiko to ṣe ifilọlẹ igbimọ akoso aabo ati igbimọ alakoso ikọ alaabọ Amọtẹkun lo fi ọrọ yi lede.
Lẹnu ọjọ mẹta yi, ipinlẹ Oyo n koju ipenija aabo orisirisi ti o si mu ki awọn eeyan kan maa sọ pe Makinde ko ṣojuṣe rẹ nipa pipese aabo to peye fara ilu.
- Amotekun gbàràdá ní ìpínlẹ̀ Oyo
- Tinubu kò ṣékú, kò ṣé ẹyẹ, o n dibọn ní lórí ọ̀rọ̀ ikọ̀ Amotekun - Fani Kayode
- Àìsí iṣẹ́ nígboro lọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ fi fẹ́ gba iṣẹ́ Amotekun - Toogun
- Ọwọ́ tẹ ọmọdébìnrín tó jí ara rẹ̀ gbẹ́ nítorí ìyá rẹ̀ ní kó lọ kọ́ ẹ̀kọ́ láti ṣe dókítà
- Dino Melaye fi ọkọ Rolls Royce bùgá lórí Instagram, ni oníṣòwò ọkọ́ bá ní kó wá san gbèsè owó ọkọ̀ tó jẹ́ òun
- Ẹ wo ohun tí a mọ̀ nípa bí agbébọn ṣe gbẹ̀mí sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀, Titus Badejo Ejanla ní ìlú Ibadan
Gomina Makinde sọ pe pẹlu ifilọlẹ igbimọ wọnyi, araalu yoo ri apẹrẹ wipe ijọba oun n gbe igbesẹ lati mu adinku ba ipenija aabo to koju Oyo.
O ni bẹẹ naa ni ibaṣepọ to mọyan lori yoo waye laarin awọn ikọ ati ileesẹ alaabo eyi ti yoo mu ki aabọ to peye wa lagbegbe naa.
Makinde tun wa parọwa si awọn eekan oṣelu lati yago fun lilo ipenija aabo to n koju Oyo fun ifẹ inu ara wọn.

Oríṣun àwòrán, OfficialSeyiMakinde
O wa rọ awọn araalu lati pawọpọ pẹlu awọn ẹṣọ alaabo lati jẹ ki aabo to jọju wa ni ipinlẹ Oyo.
Ajagunfẹyinti Brigadier General Kunle Togun ni yoo maa jẹ alaga igbimọ alakoso ẹlẹnimejila Amọtẹkun ọhun.
Igbimọ yi yoo tun ni awọn aṣoju kọọkan lati ileeṣẹ aabo ijọba apapọ,aṣoju kọọkan lati ẹkun idibo mẹtẹtaa.
Bakan naa ni Onpetu ilu Ijero, Oba Sunday Oyediran yoo jẹ aṣoju awọn lọbalọba ninu igbimọ naa.
- 'Kò sí ẹni tó lè ní kí a má wá sí Èkó, iwọ́de òní pẹ̀lẹ́ kùtù la fẹ́ ṣe'
- Kò lè sí ààbò fún iléèwé kankan àfi tí ìjọba bá wá iṣẹ́ fáwọn tó ń jí ọmọ gbé - Gumi
- Father's Day fa gbas-gbos láàrin Mercy Aigbe àti ọkọ rẹ̀ tẹ́lẹ̀, Gentry, ọkọ́ ní òun le tú àwọn àṣírí ìwà nọ̀bì rẹ̀ síta
- Gómìnà ṣàbẹ̀wò sí àwọn tí ọlọ́pàá yìnbon lù l'Enugu, Ọ̀gá ọlọ́pàá ní ìwádìí gbọdọ̀ wáyé kíákíá
- Àjọ JAMB ṣèlérí ìdánwò mìí fún àwọn tí NIN jákulẹ̀, ó tún fòfin de ibùdó CBT 25
















