Mercy Aigbe àti Lanre Gentry fi òkò ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí ara wọn ní àyájọ́ àwọn bàbá

Mercy ati LAnre Gentry

Oríṣun àwòrán, others

Yoruba sọ pe, ọja ti ọmọ wọ ti di òkùtà.

Eyi to tumọ si pe ko si iru ija to le wa laarin baba ati iya, ọmọ wọn yoo so wọn pọ titi lai.

Ni ayajọ awọn baba to waye ni ọjọ Aiku, oko ọrọ ati eebu ni gbajugbaja osẹrebinrin, Mercy Aigbe ati ọkọ rẹ tẹlẹ, Lanre Gentry fi ṣọwọ si ara wọn lori ayelujara Instagram.

Ọdun 2013 ni Mercy ati Lanre ṣe igbeyawo, amọ ti wọn pada kọ ara wọn ni ọdun 2017.

Mercy ti kọkọ fẹ ọkọ kan ṣaaju Lanre, ṣugbọn o ni igbeyawo naa tuka nitori pe iya ọkọ oun n dasi igbeyawo naa.

Ọmọ kan lo bi sibẹ, iyẹn Mitchell.

Ọmọ kan naa, Olajuwon Gentry, lo tun bi fun Ọgbẹni Lanre Gentry.

Lasiko ti igbeyawo wọn tuka, awọn ẹsun ifiyajẹni ati iwa ipa ninu ile lo fi kan Lanre, pẹlu awọn awọn aworan loriṣiriṣi to fi si ori ayelujara.

Lara awọn aworan ti Mercy fi sita re e lọdun 2017 lati fihan pe ọkọ rẹ, Lanre Gentry n na ninu ile

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Lara awọn aworan ti Mercy fi sita re e lọdun 2017 lati fihan pe ọkọ rẹ, Lanre Gentry n na ninu ile

Lati igba naa si ni wọn ti tuka, amọ ọdọ Mercy ni awọn ọmọ rẹ mejeeji n gbe.

Botilẹ jẹ pe o dabi ẹni pe ọdọọdun ni awọn mejeeji ma n ṣe ariyanjiyan ni ayajọ awọn baba, ti ọdun yii tun gba ara ọtọ.

Mercy Aigbe lo kọkọ kọ awọn ọrọ kan sita ni owurọ kutu ọjọ Aiku to jẹ ọjọ awọn baba ni agbaye.

Ninu ọrọ naa to kọ si ori Instagram, lo ti ti ki ara rẹ ati awọn baba yooku to n ṣe ojuṣe wọn.

O ni "mo ki ara mi ati gbogbo awọn baba to n sẹ ojuṣe wọn.

Àkọlé fídíò, Life saver car: Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ yì ti gba ẹ̀mí ọ̀pọ̀ aláboyún àtọmọ ọwọ́ lá ní Jigawa

Ọmọ meji ni emi nikan n tọju, ọkan lara wọn n kawe nilẹ okeere...pẹlu iye ti a n sẹ Naira si Dollar! Ha, ko rọrun rara, ṣugbọn Ọlọrun n jẹri ara rẹ."

Mercy ni ki ẹnikẹni ma ṣe sọrọ si oun pe oun gba ogo baba, o ni jijẹ baba ọmọ ju ki eeyan kan fun obinrin loyun.

"To o ba jẹ ọkunrin, ṣugbọn ti o kọ lati sẹ ojuṣe rẹ lori awọn ọmọ rẹ, o ko yẹ ni ẹni ti wọn n pe ni baba...

Nitori pe emi ni mo n sẹ ojuṣe iya ati baba fun awọn ọmọ mi mejeeji, ẹ fi mi silẹ ki n yin ara mi lojoojumọ, nitori pe ko rọrun rara."

Kini Mercy sọ ọrọ yii tan, ni ọkọ rẹ tẹlẹ, Lanre Gentry naa pa aṣamọ ọrọ ranṣẹ si ni oju opo ayelujara Instagram tiẹ naa pe oun ki gbogbo awọn baba ni agbaye.

"Mo ki ara mi ku ayajọ baba, ati gbogbo baba ni agbaye... awọn obinrin kan wa nibi kan bayii, ti wọn o ma a ki ara wọn ku ayajọ baba, nigba ti wọn o yẹ ni ẹni to yẹ ko jẹ iya tabi iyawo ile, amọ ti awọn baba ma n mu inu wọn dun nigba ti wọn ṣi jọ n gbe papọ.

Ṣugbọn, kii ṣe ẹbi wọn, wọn o ni ipilẹ to daram bẹẹni awọn obi wọn kp gbe papọ, idi si niyẹn ti wọn ko fi mọ nkan ti ayajọ baba jẹ."

Mercy Aigbe

Oríṣun àwòrán, Mercy aigbe/instagram

Mercy Aigbe naa fesi pada fun Lanre Gentry

Ọrọ ti Ọgbẹni Gentry sọ yii bi Mercy ninu, ni oun naa ba fesi pada.

Botilẹ jẹ pe Lanre ko darukọ Mercy ninu awọn nkan to kọ, Mercy ko fi orukọ tiẹ bo rara nigba to fesi.

O ni "Ọgbẹni Lanre Gentry, o dara ki o fi opin si awọn irọ ti o n pa!. O jẹ ma mu inu bi mi!"

Bakan naa lo kesi ọkan lara awọn ọmọ ti ọkunrin naa bi, Lara Gentry pe ko kilọ fun baba rẹ alaiwulo.

"O to gẹ, mo ti gba radarada yii laye to gẹ.

Ọkọ mi nigba kan lo gba ami ẹyẹ baba ti ko ṣe ojuṣe rẹ fun ọdun yii. Alainitiju ọkunrin to yẹ ko fi ọwọ boju, naa n wa sori ayelujara lati kọ ikọkukọ."

Mercy ati LAnre Gentry

Oríṣun àwòrán, others

"Mo ṣetan lati ba ọ na tan bi owo pẹlu nkan ti o ṣe yii."

"Ki ẹnikẹni ma ṣe pe mi lori ọrọ yii. Mo ṣetan lati gbagbe ẹkọ ile ti mo ni, ati ipo mi gẹgẹ bi gbajumọ.

Lanre Gentry, mo ṣetan lati fa wahala pẹlu rẹ, pẹlu awọn ẹri to fihan pe baba ti ko ṣe ojuṣe ni ọ. Agbaya, alainitiju."

Àkọlé fídíò, 'Ọwọ́ mi ti ń jẹ́rà ká tó mọ̀ pé àfi kí wọ́n tún gé e bí mo bá ṣì fẹ́ máa ṣe iṣẹ́ awakọ̀ lọ'

Lanre Gentry leri lati tu aṣiri Mercy sita

Ki ni Mercy sọrọ tan si, niṣe ni Ọgbẹni Gentry naa tun fesi pada pe ko gba oun ni iṣẹju kan lati tu gbogbo aṣiri ikọkọ ati ti iwa aṣẹwo ti Mercy hu pẹlu awọn alagbata fiimu rẹ.

O ni ṣugbọn, oun ko ni i sẹ bẹẹ nitori ọmọ oun, Olajuwon, ati iya rere ti Mercy ni.

Àkọlé fídíò, 'Sister Tope Alabi yà mí lẹ́nu gan o pé "Oniduro mi" kìí ṣe orin tó yẹ kí ọlọ́run fún mi'

Gentry ni: "Amọ nigba ti asiko ba to, gbogbo aye ni yoo mọ iru igbeaye irọ ti o n gbe, o si nilo lati fi opin si igbeaye igberaga ti o n wu.

Lati igba ti awọn mejeeji ti n fi ọrọ ranṣẹ si ara wọn ni awọn alatilẹyin kaluku ti n sọ eyi to wu wọn nipa ọrọ naa.

Àkọlé fídíò, 'CAC Agbala Itura ni mo ti bẹ̀rẹ̀ ìlú lílú kí ń tó máa bá Janet, àbúrò Michael Jackson lù Gangan àti Omele'