National Assembly rain: Òjò rọ jẹ̀jẹ̀rẹ̀ n'ílé aṣòfin Abuja, ẹ wo bí gbogbo òrùlé ṣe gbe ojò wọlé

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Lẹ́yìn tí òjò arọọrọda kan rọ ni ilu Abuja lọjọ Iṣegun, ṣe ni wọn n gbọn omi gbuu gbuu ninu gbogbo faranda wọn.
Gbogbo awọn ibi kọkọ ati gbangba ti orule ti n jo ni ojo kun ti wọn si n fi garawa ati ike ilewọ gbọn n danu.
Awọn ibi ti ojo naa pa lara ju ni awọn ọna gbawuya ti wọn maa n gba wọ inu gbọngan ipade tabi gba jade.
Ko si aridaju boya ojo naa wọ inu awọn ọfiisi wọn ati gbọngan ti wọn ti maa n ṣepade.
Lọgan ni wọn ti dari awọn agbalẹ ile igbimọ aṣofin ki wọn lọ maa gbọn omi naa kuro ki wn gbe ike su awọnibi ti ojo naa ko tii da.
Lara awọn Sẹnetọ to ti wa nikalẹ ṣaaju akoko naa bọ sita lati foju gaani ohun to n ṣẹlẹ ti aworan si fihan bi wọn ṣe n sọrọ nipa rẹ.
Gẹgẹ bi iroyin kan ṣe sọ ọ, ẹ o ranti pe ile igbimọ aṣofin dabaa biliọnu mẹtadinlogoji naira fun atunṣe ile aṣofin amọ ko sẹni to mọ ibi ti eyi de duro.
Amọṣa iye owo yii ti n fa awuyewuye ati fifi oko ọrọ ranṣẹ sawọn aṣofin latọdọ to koro oju sii pe iye owo yii ti gọbọi ju fun nkan ti wọn ya a sọtọ fun.













