Wo ìdí tí EFCC fi fẹ́ wádìí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ogun láti ọdun 2015 dí àsìkò yìí

Awọn oṣiṣẹ EFCC ati aworan ile aṣofin ipinlẹ Ogun

Oríṣun àwòrán, others

Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria, EFCC, ti ṣetan wadii ile aṣofin ipinlẹ Ogun, lori ẹsun inakuna.

Awọn iwe iroyin abẹle jabọ iroyin pe EFCC ti kọ iwe si ile aṣofin naa, lati beere fun akọsilẹ nipa gbogbo awọn eto isuna ati awọn owo ti wọn gba laarin ọdun 2015 di akoko yii.

Lori eto kan, Sunday Morning Live on FM, ti waye lori redio ipinlẹ Ogun, ni ẹni to jẹ olori ile aṣofin ipinlẹ naa, Olakunle Oluomo, ti fidirẹ mulẹ pe lootọ ni awọn gba lẹta lati ọdọ EFCC.

O sọ pe lasiko ti awọn oṣiṣẹ ile ẹjọ wa ni ẹnu iyanṣẹlodi ni lẹta naa de.

Gẹgẹ bi o sẹ sọ, o ni o ṣeeṣe ko jẹ aṣofin kan lo kọ iwe ẹsun si ajọ naa.

Botilẹ jẹ pe Oluomo ko darukọ aṣofin naa, iroyin sọ pe Aṣofin Dare Kadiri, to ti fi igba kan jẹ Igbakeji olori ile, amọ ti wọn yọ nipo, ti fi igba kan fi ẹsun kan Oluomo pe oun ṣe eto inawo ile ni nkan aṣiri.

Ẹsun to fi kan nigba naa ni pe nitori oun n beere fun akoyawọ ni wọn ṣe yọ oun ni ipo.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: 'Ǹkan tÍ Sunday Igboho Ṣe ní Ibarapa tún ti ṣelẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun'

Oluomo sọ pe "oun ko si ni ipo adari ile laarin ọdun 2015 si 2019 ti wọn n beere fun.

O ṣalaye pe ọwọ ijọba ipinlẹ ni awọn aṣofin ti n gba owo; owo oṣu ati ajẹmọnu, ti ko si si owo mii to tun n wọ apo wọn.

O ni oun si ti paṣẹ fun awọn oṣiṣẹ ile ẹjọ lati tete ṣe akojọpọ awọn iwe ti EFCC n beere fun, nitori pe ile aṣofin naa ko ni ẹbọ ni ẹru rẹ.

Àkọlé fídíò, 'CAC Agbala Itura ni mo ti bẹ̀rẹ̀ ìlú lílú kí ń tó máa bá Janet, àbúrò Michael Jackson lù Gangan àti Omele'