Ijebu Ode Murder: Ìyàwó tuntun bẹ ọkọ rẹ̀ wò, ní ìyàwó kẹrin bá gún ọkọ pa

Oríṣun àwòrán, Guardian
Ara meeriri, mo ri ori ologbo lori atẹ ni isẹlẹ to waye nilu Ijebu Ode, nipinlẹ Ogun.
Obinrin kan ti wọn pe ni Olanshile Nasirudeen tii se ẹni ọdun mẹtadinlaadọta lo sadede gun ọkọ rẹ ni ọbẹ pa nitori pe o fun obinrin miran loyun.
Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi si ti fidi isẹlẹ naa mulẹ.
Iroyin naa ni obinrin to pa ọkọ rẹ, tii se ẹni ọdun mọkanlelaadọta, ni iyawo kẹrin, tawọn mejeeji si dijọ n sisẹ Alapata ni odo ẹran kan nilu Ijebu Ode.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Princess jèbùrẹ́, ọ̀rọ̀ Baba Ijesha gbóná ju èrò ọ̀pọ̀ èèyàn lọ - Adewale Eleso
- Yomi Fabiyi bá Sanwo-Olu, gómìnà Eko sọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha
- Àkúntúnkú, ìgbà mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ rè é tí Shekau kú, tí wọ́n ní kò kú mọ
- Ìrọ́ lẹ pa, ìbò ìjọba ìbílẹ̀ kò ní wáyé l‘Oyo ní Sátidé - APC fárígá
- Èèmọ̀ wọ̀lú! Àwọn jàndùkú jí Adájọ́ gbé lọ nínú kóòtù lọ́sàn án gangan
- Ẹ̀yin tí ẹ sọ pé irọ ni mo ń pa bayii ni yoo ri fún yín
Obinrin naa lo ri ẹni to loyun fun ọkọ rẹ ni Odo Ẹran, to si bẹrẹ si fi ọrọ wa lẹnu wo lori idi to fi n fẹ ọkọ oun.
Eyi lo fa ariyanjiyan laarin Olanshile ati ọkọ rẹ, ti esu si tapo si ọrọ wọn.
Gẹgẹ bi agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa Ogun ti wi, "Afurasi apaayan naa mu ọbẹ, to si kun ọkọ rẹ ni ẹyin ẹsẹ rẹ, to si fi ọbẹ ge isan rẹ.
Bi o tilẹ jẹ pe wọn tete gbe ọkunrin naa digbadigba lọ sile iwosan to wa ni arọwọto fun itọju, ti wsn si tun pada gbe lọ sile iwosan ijọba to wa nilu Ijebu Ode amọ ẹpa ko boro mọ.
Ile iwosan ijọba yii ni ẹlẹmi ti gba a nitori ẹjẹ pọ to da lara rẹ.
Idi ree ti Olanshile fi fẹsẹ fẹ nigba to gun ọkọ rẹ ni ọbẹ amọ tawọn osisẹ ọlọpaa tọpasẹ rẹ sibi to fi se buba ladugbo Mobalufon nilu Ijebu Ode.
Ọwọ si tẹ Olanshile nigba ti awọn eeyan kan fi isẹlẹ naa to ọga ọlọpaa to wa ni adugbo Obalende nilu Ijebu Ode leti.
"Nigba ta fi ọrọ wa obinrin naa, tii se iyawo kẹrin lẹnu wo, o ni ọkọ oun lo kọkọ gba oun leti nitori pe oun bi iyawo rẹ tuntun pe kli lo wa se ni isọ rẹ.
A ti gbe oku oloogbe naa fawọn ẹbi rẹ, ki wọn le sin nilana ẹsin Islam lẹyin ta pari eto ayẹwo ta se fun."
Kọmisana ọlọpaa nipnilẹ Ogun ti wa pasẹ pe ki wọn gbe ẹsun ipaniyan naa lọ si ẹka ọlọpaaọtẹlẹmuyẹ ileesẹ ọlọpaa, ta mọ si CID.

















