Maryam Sanda: Ṣe ló ń wa ẹkún mu nílé ẹjọ́ lórí ìdájọ́ ikú tí wọn fun
Aanu abiyamọ̀ yoo se eeyan nile ẹ́jọ lọ̀jọ Aje nigba ti adajọ ileẹjọ giga nilu Abuja gbe idajọ kalẹ pe Maryam Sanda jẹbi ẹsun ipaniyan.
Maryam yii ni wọn lo fi ọbẹ gun ọkọ rẹ, Bilyaminu Bello, eyi to ran sọrun ọsan gangan lọdun 2017.
Bi o tilẹ jẹ pe Maryam sọ̀ pe oun ko mọwọ mẹsẹ lori ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan oun naa, sibẹ o papa foju ba ileẹjọ.
Lẹyin atotonu agbẹjọro fun ijọba ati igun olujẹjọ, ni adajọ kede pe Maryam jẹbi ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan, to si ni ki wọn lọ yẹgi fun titi ti ẹmi yoo fi bọ ni ẹnu rẹ.
Ṣe ni Maryam ń wa ẹkún mu nílé ẹjọ́ lórí ìdájọ́ ikú tí wọn fun, to fi mọ̀ awọ̀n ẹbi ati ibatan rẹ to wa nile ẹjọ.