Maryam Sanda: Toyin Abraham, Femi Adebayo, Tayo Sobola barajẹ́ lórí ìdájọ́ ikú

Toyin Abraham, Femi Adebayo ati Tayo Sobola
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Idajọ iku ti ileẹjọ giga ilu Abuja da fun Maryam Sanda, to pa ọkọ rẹ ti n mu oniruuru ariwisi dani lati ọdọ awọn osere ori itage Nollywood.

Ọpọ awọn osere tiata yii lo n para poro nipa awọn isẹlẹ iwa ipa to n waye lemọlemọ laarin lọkọ laye, ti wọn si n kilọ fun tọkunrin-tobinrin lati sọrase.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Toyin Abraham, loju opo Instagram rẹ lo n wa ẹkun mu poroporo, to si ni oun ko tii sunkun to bayi ri laye oun, ti idajọ naa si ba oun lọkan jẹ.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 1

Toyin Abraham wa n gba awọn lọkọlaya nimọran pe ti ede wọn ko ba yede mọ, ti igbeyawo wọn si n la ina kọja, yoo kuku dara ki tọkọtaya yago funra wọn, dipo ki wọn sekupa ara wọn.

Mama Ire, ẹni to n gbarata lori ohun ti yoo sẹlẹ si ọmọ ọwọ ti Maryam Sanda gbe dani lasiko ti wọn dajọ iku fun, wa n rawọ ẹbẹ si ọba oke pe ko siju aanu wo obinrin naa.

Maryam Sanda ti wọda obinrin n gbe jade nile ẹjọ

Bakan naa ni ilumọọka osere tiata miran, Femi Adebayo fi fidio kan to se si oju opo Instagram rẹ, to si n rọ awọn eeyan pe ibasepọ lọkọlaya kii se tipa tikuuku.

Femi naa wa gba awọn tọkọtaya nimọran pe, ti igbeyawo wọn ko ba mu adun lọwọ, yoo dara ki wọn pin gaari, ki olukaluku si ba tirẹ lọ.

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 2

Femi Adebayo, ti gbogbo eeyan mọ si Jẹlili, wa n beere pe "Bawo la se fẹ sọ fun ọmọ tuntun ẹjẹ ọrun naa pe iya rẹ lo pa baba rẹ, idi si ree ti wọn se yẹgi fun oun naa. Ohun ibanujẹ nla gbaa ni."

Femi, ti oju rẹ kọrẹ lọwọ lori isẹlẹ bi wọn se dajọ iku fun Maryam Sanda wa rawọ ẹbẹ sawọn eeyan pe "Ẹ jọwọ, ẹ dakun, mo rọ yin, ẹ jẹ ka maa sọra fun inufufu ati igbonara, ẹni apọnle ni abuku n wa kiri, adura mi si ni pe Ọlọrun oba yoo maa dari isisẹ wa."

Ko tan sibẹ, osere tiata obinrin miran, Tayo Sobola, to mura bii ẹni ti ọfọ sẹ loju opo Instagram rẹ ni imura oun lo n se afihan ipo ibanujẹ ti oun wa nitori inu oun bajẹ lori idajọ iku ti wọn se fun Maryam Sanda.

Tayo ni "Ile aye! Ibinu jẹ mihuwasi to lagbara pupọ eyi to maa n kesi eeyan lati kọbi ara sii amọ ibeere to yẹ ka bi ara wa ni pe bawo ni a se lee se akoso ibinu wa si?"

Sotayo salaye pe oun wo bi igbẹjọ Maryam Sanda, ti wọn dajọ iku fun tori pe o pa ọkọ rẹ lọdun 2017, se ti lọ nile ẹjọ, ti oun si rinrin ajo lai kuro loju kan soso.

Skip Instagram post, 3
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 3

"N ko tiẹ mọ ohun ti eeyan lee sọ, amọ mo kan n jẹrora ninu ọkan mi ni, ti mo si n woye pe bawo ni wọn yoo se yẹgi fun obinrin akẹẹgbẹ mi? Amọ ohun to daju ni pe lootọ lo pa ọkọ rẹ, boya lati ipasẹ asise ni abi o mọọmọ see."

Sobola fikun pe Maryam gba ibinu lati gbakoso ọkan rẹ, ohunkohun si lo lee fa isẹlẹ yii, koda awọn ọkunrin lee ti obinrin debi pe yoo fi gbẹmi eeyan, bakan naa si lawọn obinrin kan ni aseju lọwọ, ti wọn si maa n se idajọ lọwọ ara wọn, eyi to maa n mu ki nkan polukumusu sii.

"Amọ ootọ ọrọ to wa nilẹ ni pe a lee yago fun awọn nkan kan nitori ojoojumọ ni ọpọ iroyin n wa nipa awọn ọkunrin to n pa iyawo wọn ati awọn obinrin to n pa ọkọ wọn, tawọn afẹsọna lọkunrin-lobinrin naa si n gbẹmi ara wọn nitori ẹsun sise oju meji."

Osere tiata ọhun wa rawọ ẹbẹ sawọn eeyan pe ki wọn maa tiraka lati rin jinna si ohunkohun to ba lee fa wahala ba aye wọn tabi ge ẹmi wọn kuru, to si tun rọ wọn lati ta kete si ija, ki wọn si tun kẹyin si awọn eeyan to ba lee ru ibinu wọn soke.

Pásítọ̀ ìjọ Redeem, Ọ́mọ́ọ́ba kan l'Eko ati èèyàn mẹ́ta míì rèé to ti gba ìdájọ́ ikú rí

Sise idajọ iku fawọn ti ile ẹjọ ba fi idi ẹri mulẹ pe wọn ṣeku pa eeyan akẹẹgbẹ wọn, kii ṣe nkan tuntun.

EKO

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko fẹ̀sùn kan Lekan Shonde pé ó lu ìyàwó rẹ̀ pa, lẹ̀yín to fi ẹ̀sùn kan pé iyawo rẹ̀ pé óún yan àlè.

Koda ofin orileede Naijiria fi ofin gbe awọn agbofinro lẹyin, lati se amusẹ idajọ iku tile ẹjọ ba da, lẹyin ti Gomina ipinlẹ tabi Aarẹ ba ti buwọlu aṣẹ yii.

Iroyin idajọ iku fun arabinrin Maryam Sanda to pa ọkọ rẹ nilu Abuja, to waye lọjọ Aje, tun jẹ ohun aritọkasi pe iru idajọ iku bayii ṣi n waye ni Naijiria.

Amọ melo ni iru awọn eeyan to daran ipaniyan, ti ile ẹjọ dajọ iku fun, ti ẹyin ranti?

E jẹ ka ran ara wa leti nipa diẹ ninu wọn:

Ọmọ Ọba Eko Adewale Oyekan:

Ẹni aadọta ọdun ni ọmọọba Eko ana, Adewale Oyekan, ti o si gba idajọ iku lọdọ adajọ ile ẹjọ giga kan nilu Eko lori ẹsun pe o pa oniṣowo kan, Alhaja Sikirat Edun.

Gẹgẹ bi ohun ti a ri akọsilẹ rẹ, ọmọọba Adewale Oyekan fun Lateef Bello, tii se ọmọ ọdọ Alhaja Edun ni ẹgbẹrun lọna ọgọta Naira. lati pa ọga rẹ.

Ọmọọba ilu Eko Adewale to gba idajọ iku

Oríṣun àwòrán, Others

Iwaadi awọn ọlọpaa fihan pe wọn yin oloogbe lọrun pa, ti wọn si ju oku rẹ sinu kanga to wa ninu ile rẹ.

Osere tiata lapa oke ọya, Rabi Ismaila:

Oṣere tiata lapa ariwa ilẹ Naijiria ni Rabi Ismaila, to si fi ilu Kano ṣe ibudo.

Ẹsun ti wọn tori rẹ dajọ iku fun ni pe o pa ọrẹkunrin rẹ, ọgbẹni Auwalu lọdun 2002.

Ile ẹjọ giga ni Kano dajọ ki wọn yegi fun, titi ti ẹmi yoo fi bọ lara rẹ.

Rabi tawọn eeyan mọ si Rabi Cecilia ninu sinima, tan ọrẹkunrin rẹ lọ si adagun omi kan, ti o si fun ni majele jẹ ki o to ju oku rẹ sinu omi.

Pasitọ ijọ Redeem, Akolade Arowolo to pa iyawo rẹ:

Pasitọ awọn ọdọ kan ninu ijọ Redeem naa gba idajọ iku lori pe o pa iyawo rẹ, Titilayo to n ṣiṣẹ ni ile ifowopamọ kan.

Orukọ pasitọ naa ni Kolade Arowolo, ti ile ẹjọ si fidi ẹsun iwa ọdaran naa mulẹ pe oun funra rẹ lo pa iyawo rẹ sinu ile wọn.

Aworan Paitọ ijọ Redeem to pa iyawo rẹ

Oríṣun àwòrán, Others

Ẹjọ yi mu iriwisi wa ti awn eeyan si n ṣe emo bi ẹni to pe ara rẹ lẹni Ọlọrun ṣele hu iru iwa bayi.

Iwaadi fihan pe igba 76 ni o gun iyawo rẹ lọbẹ ti adajọ si fi wakati mta gbako ka idajọ rẹ.

Khadijat Oluboyo, ti ọrẹkunrin rẹ oniyahoo yahoo ṣeku pa:

Ni oṣu kẹta ọdun 2019 ni ile ẹjọ giga ni ipinlẹ Ondo da ẹjọ iku fun Seidu Adeyemi to pa ọmọ igbakeji gomina ana nipinlẹ Ondo, Khadijat Olubọyọ ni ọdun 2018.

Seidu Adeyemi to jẹ ọrẹkunrin Khadijat Oluboyo ni wọn fẹsun kan wi pe o pa a, ti o si tun rii mọle si inu yara rẹ ni Aratusi, Oke-Aro ni Akure, nipinlẹ Ondo.

Khadijat Oluboyo n mura lati jade fasiti ni ile iwe giga fasiti Adekunle Ajasin ni Akungba Akoko ni ipinlẹ Ondo, ki o to jade laye.

Khadijat Oluboyo
Àkọlé àwòrán, Ọ̀rẹ́kùnrin Khadijat Olubọyo gba ọjọ́ ikú

Lẹyin ọsẹ kan tí wọn ti ń wá Khadijat tó jẹ́ ọmọ igbákeji gómínà tẹ́lẹ̀rí ní ìpínlẹ̀ Ondo, ni wọ́n bá òkú rẹ̀ ní ilé àfẹ́sọ́nà rẹ̀, Adeyemi Alao.

Alukoro fun ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo to ba BBC Yoruba sọrọ lasiko ti isẹlẹ naa waye sọ wi pe, ṣe ni Adeyemi gbe oku Khadijat sinu ile fun ọjọ mẹfaki ẹnikẹni maa baa fura si.

Stella fi ibinu pa Stella alabagbe rẹ, o gba idajọ iku

Orukọ kanna ni wọn jijọ njẹ ṣugbọn arabirin Stella Gilbert ko wo eyi mọ alabagbe rẹ, Stella Godwin lara, ko to fi ibinu gun lọbẹ pa.

Ile ẹjọ ko ṣe iye meji ki o to dajọ pe o jẹbi ẹsun ipaniyan ti ijọba ipinlẹ Eko fi kan. Ẹṣẹ ipaniyan to hu yii si lo tako ofin ọdaran tipinlẹ Eko, abala okoolerugbao le kan.

Stella daku ni igba ti adaj dajọ iku fun

Oríṣun àwòrán, Google

Adugbo Ajegunle ni ojule kọkandinlọgọta, Opona Ojora ni iṣẹlẹ naa ti waye ni ọjọ kejilelogun oṣu Kẹfa ọdun 2013.

Stella sọ pe, looto loun gun alabagbele oun lọbẹ laya amọ lẹẹkan ṣoṣo ni.

Eyi si lo mu ki ile ẹjọ dajọ iku fun.