Ọyọ: Àwọn Alága APC fàáké kọ́rí fún Seyi Makinde, wọn padà sẹ́nu iṣẹ́

Abass-Aleshiloye n ba awọn eeyan sọrọ nijọba ibilẹ Oluyole

Oríṣun àwòrán, Oladiipo Oyeyemi Deeplomacy

Alaga ijọba ibilẹ ni ipinlẹ Oyo ti ni awọn kọ aṣẹ gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde to yọ awọn nipo lai ti pe ọjọ.

Alaga ẹgbẹ agbarijọpọ awọn alaga ijọba ibilẹ, ALGON, ẹka tipinlẹ Ọyọ, Ọmọọba Ayodeji Abass-Alẹshinoye sọ eyi lasiko to ba awọn akẹgbẹ rẹ sọrọ ni ilu Ibadan, ti wọn si panupọ sọ wi pe, awọn yoo pari saa awọn tan, eleyii to ku ọdun kan, ki awọn to kuro ni ipo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ijọba ipinlẹ Ọyọ ti yan awọn alaga fidihẹ fun awọn ijọba ibilẹ to wa ni ipinlẹ Oyo, lẹyin ti Gomina naa kọwe lọ gbe ile rẹ fun awọn alaga to wa nibẹ tẹlẹ.

Inu ọgba ijọba ibilẹ Oluyole

Oríṣun àwòrán, Oladiipo Oyeyemi Deeplomacy

Abass-Aleshinloye ni, alaga ijọba ibilẹ Oluyole ni ipinlẹ Oyo pẹlu aṣẹ ile ẹjọ to gaju lọ lorilẹede Naijiria.

Bakan naa lo paṣẹ fun awọn akẹgbẹ rẹ ti ijọba ti kọwe lọ gbe ile rẹ fun, lati pada si ibi iṣẹ wọn ni waranṣesa, ayafi awọn agbeegbe ti ijọba ti ti ileeṣẹ wọn.

Àkọlé fídíò, Làáhànmí: Ìwádìí ní èèyàn 219 ni ibà Lassa pa lọ́dún tó lọ́, 29 lọ́dún yìí, tètè dènà rẹ̀

Alaga ijọba ibilẹ ni ipinlẹ Oyo naa fi ẹsun kan Gomina Makinde wi pe, o tẹ oju ofin mọlẹ nipa titapa si aṣẹ ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria.

O ni oun ti gomina naa n ṣe ni lati bọwọ fun ofin ti o ba a lara mu, ti o si kọ awọn ofin to ku silẹ.

Ami idamọ ẹgbẹ osisẹ nijọba ibilẹ

Oríṣun àwòrán, Nulge

Iroyin ni ti ipa, ti ikuuku ni awọn alaga ijọba ti gomina yọ ni ipo fi wọ ileeṣẹ wọn ni Ọjọ Aje.

Laipẹ yii ni Minisita fun eto idajọ, Abubakar Malami kọ lẹta si Kọmisana feto idajọ ni ipinlẹ Oyo lati da awọn alaga ijọba ibilẹ ti gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde yọ nipo, pada si ipo wọn.