Travel Ban List: Muhammed ní Amẹ́ríkà kò bùn Nàíjíríà gbọ nípa ìgbésẹ̀ náà

Papakọ ofurufu kan ni Naijiria ati awọn eeyan to fẹ rinrinajo silẹ okeere

Oríṣun àwòrán, @nigimmigration

Minisita feto iroyin lorileede Naijiria, Lai Mohammed ti sọ pe, o ku diẹ kaato bi orileede Amẹrika ṣe fi orukọ Naijiria kun awọn orileede ti wọn gbegi dina irina awọn ọmọ ilẹ wọn lọ si Amẹrika.

Lai Mohammed ni iru igbesẹ bayi ti ya ju ati pe, o le mu iporuru ọkan wa fun awọn to ba fẹ dokowo pẹlu Naijiria.

Nilu London ni o ti fi ọrọ yi sita ninu ifọrọwerọ pẹlu ile iṣẹ iroyin Reuters.

Ni Ọjọru ọsẹ to kọja ni aarẹ Donald Trump kede pe oun yoo fi kun iye awọn orileede tawọn ko ni gba laaye lati wọ ilu awọn.

Lai Mohammed

Bo tilẹ jẹ pe ko darukọ awọn orileede kankan ni pato, awọn to mọ nipa igbesẹ yii sọ pe, lara awọn orileede ti ọrọ yii le kan la ti ri Naijiria, Belarus, Eritrea, Kyrgyzstan, Myanmar, Sudan ati Tanzania.

Lai Mohammed ni, ko si igba ti ikede naa ko ni pada waye ṣugbọn Amẹrika ko bun Naijiria gbọ ati pe, wọn ko sọ idi kankan ti wọn yoo fi gbe iru igbesẹ bẹẹ.

Papakọ ofurufu kan ni Naijiria ati awọn eeyan to fẹ rinrinajo silẹ okeere

Oríṣun àwòrán, @nigimmigration

''Gbogbo agbara la n ṣa lati yanju ọrọ yii. Bi wọn ba gbegi dina irinajo lọ si orilẹede wọn, yoo ṣe akoba fun orileede wa paapa ju lọ, awọn to ba nilo itọju. Ọrọ naa yoo kan awọn ile ẹkọ pẹlu''

Ko ti daju ọna ti idiwọ yii yoo gba ṣugbọn lawọn orileede bi Iran, Libya North Kore ati Somalia ti Amẹrika ti gbe gi dina tẹlẹ, awọn alaṣẹ ati mọlẹbi wọn ko le gba awọn iwe irina 'visa' mọ lati wọ Amẹrika.

Àkọlé fídíò, Làáhànmí: Ìwádìí ní èèyàn 219 ni ibà Lassa pa lọ́dún tó lọ́, 29 lọ́dún yìí, tètè dènà rẹ̀

Ọpọ ọmọ Naijiria lo n gbe orilẹede Amẹrika, ti Naijiria ati Amẹerika si jọ ni ajọṣepọ lati doju ija kọ awọn agbesunmọmi.