Ritual Murder: Bàbá akẹ́kọ̀ọ́bìnrin LASU tí ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ fi ṣ'òògùn owó ń bèèrè fún ìdájọ́ òdodo

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police
Ohun kan ti baba akẹkọọbinrin fasiti ipinlẹ Eko, LASU to n mura fun eto agunbanirọ, Favour Daley-Oladele n beere fun ni idajọ ododo.
O ni ki ijọba da ẹjọ to yẹ fun awọn to fi ọmọ oun ṣe oogun owo.
Pasito ijọ alaṣọ funfun kan, Segun Philip ati Adeeko Owolabi to jẹ ọrẹkunrin Favour pẹlu iya rẹ, Bola Oladele ni ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ṣafihan wọn lọjọ Aje niluu Abeokuta lori ẹsun pe wọn jọ gbimọ pọ ni.
Awọn ọlọpaa ni wọn fi akẹkọọbinrin naa ṣe oogun owo.
Favour ni iroyin sọ pe o kuro nile lọjọ kẹjọ oṣu kejila ọdun 2019, to si di awati, lẹyin naa ni wọn ri oku rẹ ninu eyi ti awọn ẹya ara rẹ kan ko si nibẹ mọ.
Nigba ti awọn ọlọpaa ṣewadii ni wn gbọ pe irina arabinrin yii jọ mọ lilọ si ijọ alaṣọ funfun kan ni niyan niyan Ikoyi-Ile nipinlẹ Osun.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo wọn pẹlu Adeeko lo ti ṣalaye pe pasitọ fun oun ni ọmọ odo lati fi lu u lori ti pasit si sare fi ọbẹ yọ ọkan rẹ eyi to fi se asejẹ fun Adeeko ati iya rẹ.
Ile iṣẹ ọlọpaa to wa ni Mowe lawọn obi rẹ fi ọrọ naa to leti ki ọwọ ofin to tẹ awọn to ṣiṣẹ ibi ọhun.
Pasitọ Philip jẹwọ niwaju awọn ọlọpaa wi pe lootọ loun gbimọ pọ pẹlu Owolabi lati fi Favour ṣe oogun owo, amọ iya Owolabi ko mọ nipa ero awọn mejeeji.
Philip ni ohun tawọn gbero lati ṣe ni lati jo awọn ẹya ara akẹkọọbinrin kan pọ fi ṣe agbo fun iya Owolabi ki o le maa ri iṣẹ nla nla ti yoo maa mu owo wọle gba.
Amọ o ni ẹlẹda Favour ko jẹ ni oogun owo, eyi ni ko jẹ ki oogun naa ṣiṣẹ.
Owolabi ẹni ọdun mẹtalelogun naa sọ pe oun kabamọọ ohun ti oun ṣe pẹlu Philip, o ni iṣẹ to bọ lọwọ baba ati mama oun lo sun oun debi fifi ọrẹbinrin oun ṣe oogun owo.
Ẹwẹ, baba oloogbe akẹkọọbinrin naa ṣapejuwe Favour gẹgẹ bi wura ninu idile oun.
''A woju Ọlọrun fun ọdun diẹ ki a to bi Favour, o si lọ fasiti eyi to mu inu wa dun pe yoo kẹkọọ gboye laipẹ ṣugbọn eeyan kan gbimọ pọ lati ṣekupa a,'' baba lo sọ bẹẹ.
Baba oloogbe naa ni iku Favour jẹ ibanujẹ nla fun idile oun.















