2019 in Retrospect: Wo àwọn èèkàn tí ikú mú lọ lọ́dún 2019

Oríṣun àwòrán, OTHER
Wọn ni iku doro, iku naa ni ko jẹ keyi to gbo keke o jobi to gbo kẹkẹ.
Kii ṣe ọrọ abẹnu mọ pe kii ṣe gbogbo eeyan to ba wọnu ọdun kan nii jade nibẹ. Iku nii koju ẹbi jọ iku naa nii mu ki ogun ọmọde ma lee ṣere fun ogun ọdun.
Laarin ọmọ Yoruba, o ja, o mu awọn to fẹ mu lọ kọdun to kasẹ nlẹ. Kii ṣe pe agbo Yoruba nikan lo ti ṣẹlẹ kaakiri ẹya agbaye lo ti ṣ'ọṣẹ ṣugbọn a kan mu wa si iranti yin, awọn to ṣẹlẹ nigimu Yoruba.
- Wo àwọn èèyàn jáńkán tí yóò ṣe ọdún tuntun ní ọgbà ẹ̀wọ̀n
- Ẹni orí yọ, ó dilé! Agbébọn pààyàn méjì ní ṣọ́ọ̀ṣì, olùjọ́sìn yìnbọn p'òun náà
- ‘Ìjọba àpàpọ̀ gbọdọ̀ tọrọ ìdárìjì lọ́wọ́ Sowore, Dasuki’
- Marlian, òfégè ìgbéyàwó Buhari, Fatoyinbo àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá tó mi ìgboro tìtì ní 2019
- Marlian, òfégè ìgbéyàwó Buhari, Fatoyinbo àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá tó mi ìgboro tìtì ní 2019
- Bukola Saraki fi 'Gbas Gbos' ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí 'ilẹ̀ bàbá rẹ̀' tí ìjọba Kwara gbà padà
Lagbo oṣere tiata Yoruba lorilẹede Naijiria, iku naa da bira diẹ lọdun 2019 ti o n pari lọ yii. Diẹ lara awọn eekan oṣere tiata to jade laye lọdun 2019 ree.
Fasasi Olabankewin "Dagunro"

Oríṣun àwòrán, Instagram
Ko ṣee rọ sẹyin ni alagba Fasasi Ọlabankẹwin ti ọpọ mọ si Dagunro ninu sinima ede Yoruba.
Ilu Oṣogbo lo dakẹ si ni ọjọ kẹtala oṣu kẹfa ọdun 2019.
Aisan ranpẹ ni iroyin sọ pe o ṣe agba oṣere naa ki o to dagbere faye.
Ọmọ aadọrin ọdun ni baba Dagunro nigba ti iku de.
Funmilayọ 'Ijẹwuru'Ogunṣọla.

Oríṣun àwòrán, Instagram
Arabibnrin Funmilayọ Ogunṣọla ti ọpọ mọ si Ijẹwuru ku ni ọjọ Aje, ọjọ kẹrin oṣu keji ọdun 2019 ni ilu Ibadan.
Ọmọ ọdun mejidinlọgọta ni Ijẹwuru ki o to jade laye.
Gbajugbaja oṣere ni, ọkan lara awọn iyawo agba oṣere to ti wọ kaa ilẹ lọ, Ishọla 'I show pepper'Ogunṣọla lo jẹ.
Bi a ba taju kan diẹ wo ita kuro lagbo awọn oṣere Tiata, lara awọn ti iku alumuntu nawọ mu niyii.
Pius Adesanmi

Oríṣun àwòrán, Instagram
Ọjọgbọn ati onkọwe to gbayi kaakiri agbye ni Pius Adesanmi.
Oun si ni oludari ẹka ẹkọ nipa ilẹ Afirika ni fasiti Carleton lorilẹede Canada.
Inu baluu Ethiopian Airlines to ja ni ọjọ kẹwa oṣu kẹta ọdun 2019 ni Pius ti jẹ ipe ọlọjọ.
Gbenga 'Burger' Akintunde

Oríṣun àwòrán, Instagram
Ni Ọjọbọ ọjọ kẹta oṣu kini ọdun 2019 ni Gbenga 'Burger'Akintunde jade laye.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Ọgbẹni Akintunde funrarẹ gan lo lọ si ileewosan lati sọrọ nipa aisan iba to n ṣe e. Ohun ti yoo ṣẹlẹ lẹyin rẹ ni iroyin iku rẹ.
Ọmọ ọdun mẹtadinlaadọta ni ki ọlọjọ to de.
DJ Xgee

Oríṣun àwòrán, Instagram
Gbajugba aforindabira nibi ayẹyẹ ti oyinbo n pe ni DJ ni DJ Xgee.
Ni ọjọ kini ọdun 2019 ni iroyin iku rẹ gbode lẹyin to lọ kopa ni ode ayẹyẹ kan.
Iroyin sọ pe oun funra rẹ gan gbẹmi ara rẹ lẹyin to kọ iwe ibanilọkanjẹ kan sori oju opo Instagram rẹ.
'Mad Melon' ti 'Danfo Drivers'

Oríṣun àwòrán, Instagram
Ṣe ẹ ranti Danfo Drivers, iyẹn awọn akọrin meji kan to lu alujo orin sawọn ọmọ alafẹ lorilẹede yii ati loke okun lọdun diẹ sẹyin.
Oghenemaro Emeofa, ti ọpọ mọ ni Mad Melon, ọkan lara awọn meji to da ẹgbẹ naa silẹ jade laye ni ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹsan ọdun 2019.
Ọkọ danfo to n na Ọjọọ si Mile 2 l'Eko lawọn mejeeji yi n wa ki ileeṣẹ orin kan to gbe wọn jade faye ri.
Samuel Akinpẹlu 'Alabi Yellow'

Oríṣun àwòrán, yabaleftonline.ng
Ẹnu o ni pa ọ bii ti Alabi Yẹllow' ni gbajugbaja ọrọ tawọn eeyan maa n sọ laye igba kan. Ko si si idi meji ju ipa ti gbajugbaja oṣere tiata, Samuel Akinpẹlu ti ọpọ mọ si Alabi Yellow maa n ko ninu ere sinima lọ.
Aisan ọlọjọ pipẹ kan lo ṣokunfa iku rẹ. Aisan ẹjẹ riru lo da a dubulẹ lẹyin ti iyawo rẹ ku ni oṣu kẹta ọdun 2019 kan naa.
Bi o tilẹ jẹ pe o ri iranwọ owo miliọnu mẹwa naira latọwọ Wolii Esther Ajayi ti ọpọ mọ si iya adura ni oṣu kẹrin.
Amọṣa ni ọjọ kejilelogun ọdun, oṣu kejila 2019 ni Alabi Yellow jade laye.













