2019: Marlian, òfégè ìgbéyàwó Buhari, Fatoyinbo àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá tó mi ìgboro tìtì ní 2019

Oríṣun àwòrán, OTHER
- Author, Busayo Akogun
- Role, Broadcast Journalist, BBC Yoruba
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Oriṣiriṣi iṣẹlẹ apanilẹrin, arikọgbọn, ibẹru, ati bẹẹbẹ lọ lo ṣẹlẹ ni orilẹede Naijiria ni ọdun 2019. Eyi ni akojọpọ diẹ lara awọn iṣẹlẹ naa.
Busola Dakolo Vs Biodun Fatoyinbo

Gbajugbaja ayaworan, to tun jẹ iyawo gbajugbaja akọrin, Timi Dakolo, Busola Dakolo, fi ẹsun kan pasitọ ijọ Commonwealth of Zion Assembly, Biodun Fatoyinbo, ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pe o fi ipa ba oun lopọ lọdun diẹ sẹyin.
Lẹyin awuyewuye tó tẹle ifòròwanilẹnuwo naa, pasitọ ọhun ti ni oun yoo gba ile ẹjọ lọ lori ọrọ naa.
Fatoyinbo ni, irọ pọnbele ni ẹsun Busola Dakolo, ati wi pe yatọ si iṣẹ oun gẹgẹ bii pasitọ, oun ko ba arabinrin naa ni nkankan pọ ni ikọkọ oun ko si fi ipa ba obinrin kankan lo pọ ri.
Ẹsun naa gba gbogbo ori ayelujara kan, ṣugbọn Fatoyinbo ni oun ko fipa ba obinrin kankan lo pọ ri.

Ninu fidio ifọrọwanilẹnuwo naa, Busola ni igba ti oun wa ni ileewe girama, ni oun kọkọ pade Fatoyinbo ni Ilorin, Ipinlẹ Kwara, nigba to ṣẹṣẹ bẹrẹ ijọ COZA.
O sọ ninu ẹsun rẹ ti fidio Y! NaijaTV gbe sita wi pe, igba meji ọtọọtọ ni pasitọ naa fipa ba oun lo pọ.
Niṣe ni awọn ọmọ Naijiria kan tu jade ti wọn si fi ẹhonu han lọ si awọn ẹka ijọ COZA ni Eko ati Port-Harcourt. to fi mọ ti Abuja. Wọn pe fun ifipo silẹ Fatoyinbo.
AWỌN IROYIN TẸẸ LE NIFẸ SI NIPA RẸ
Agbẹjọro fun Busola Dakolo ti ni awọn n gbe Biodun Fatoyinbo lọ si ile ọjọ kotẹmilọrun lẹyin ti ile ẹjọ da ẹjọ ifipanilopọ to pe naa danu.
------------------------------------------------------------
Igbeyawo ofege laarin Aarẹ Muhammadu Buhari ati Hajiya Sadiya Umar Farouq
Oriṣiiriṣi aworan ati akọle to pani lẹrin lo kun ori ayelujara ni eyi ti awọn eniyan fi n ṣeto ipalẹmọ igbeyawo ofege ti wọn ni o yẹ ko waye laarin Aarẹ Muhammadu Buhari ati Hajiya Sadiya Umar Farouq.

Oríṣun àwòrán, @others
Ṣaaju ni iroyin ẹlẹjẹ ti gba ori ayelujara pe eto igbeyawo naa yoo waye laarin minista tuntun fun Abojuto lori ọrọ Ijamba ati Igbayegbadun ọmọniyan lorilẹ-ede ati aarẹ Naijiria.
AWỌN IROYIN TẸẸ LE NIFẸ SI NIPA RẸ
Koda, wọn ṣe idasilẹ 'hashtag #BUSA2019' fun eto igbeyawo irọ naa. Ti ọpọlọpọ aworan apanilẹrin nipa 'igbeyawo naa' si kun ori ayelujara.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ninu gbogbo iṣẹlẹ iroyin igbeyawo ofege Aarẹ Buhari yii ni fidio kan ti n tan kalẹ pe wọn ti ti Aisha Buhari mọle ninu ile ijọba ni Abuja.
Ṣugbọn ileeṣẹ aarẹ sọ wi pe irọ ni iroyin igbeyawo naa.
---------------------------------------------------------------------------------------------------------------
Naira Marley rẹwọn he, o gba ipo kinni lori Google Trend
Afeez Fashola ti ọpọ mọ si Naira Marley jẹ gbajugbaja akọrin takasufe lorilẹede Naijiria.
Lọwọ ti a wa yii, Naira Marley ti fẹẹ di oriṣa akunlẹbọ fun ọpọlọpọ awọn ọdọ. Wo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó mú Naira Marley di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ ní 2019

Oríṣun àwòrán, Naira Marley/twitter
Iroyin ti o jadi laipẹ yii sọ pe oun ni ọmọ Naijiria ti awọn eeyan ṣe afẹri rẹ ju lọ loju opo Google lọdun 2019.
AWỌN IROYIN TẸẸ LE NIFẸ SI NIPA RẸ
Ni oṣu karun ọdun 2019 ni akọrin ara, Simi pariwo sita lori ikanni ayelujara lati koro oju si bi awọn ọdọ ṣe n kan si agbami iwa jibiti ori ayelujara.
Eyi si fa itahunsira laarin oun ati Naira Marley.
Naira Marley koju ija si Ruggedman
Kii ṣe Simi nikan ni Naira Marley ba wọ iya ija lori ọrọ boya jibiti ori ayelujara, yahoo-yahoo tọna paapaa julọ lẹyin orin 'Am I a yahoo boy?' to gbe sita.
Ọkan lara awọn odu asọrọdorin lorilẹede Naijiria, Ruggedman pẹlu sọ si ọrọ naa ninu eyi to ti ni ko dara ki awọn olorin, gẹgẹ bi awokọṣe lawujọ o maa gbe lẹyin awọn oni yahooyahoo.
Eyi ko dun mọ Naira Marley ninu, o si fi esi ọrọ kobakungbe ranṣẹ sii lori ayelujara. Koda awọn ololufẹ Naira Marley kan tilẹ kọlu Ruggedman ni ilu Gẹẹsi lori ọrọ yii gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ.
Ni ọjọ kẹwa oṣu karun un ọdun 2019 lawọn oṣiṣẹ ajọ EFCC mu Naira Marley niluu Eko. Ẹsun mọkanla ni wọn fi kan an eyi to da lori gbigbimọ pọ lati huwa ibi, ninu ayederu kaadi igbawo lọwọ pẹlu iwa jibiti.
Lẹyin to lo ọpọlọpọ ọsẹ ni ọdọ awọn ajọ EFCC ni ile ẹjọ gba oniduro rẹ.
Lati igba ti ọrọ igbẹjọ rẹ naa ti bẹrẹ lo si ti di gbajugbaja ni aarin awọn ọdọ, paapaa julọ awọn to rii gẹgẹ bii ẹni to n ja fun awọn ọdọ nitori aarin awọn ọdọ ni yahoo-yahoo pọ si julọ.
Ariwo Marlian! Marlian !! lo gbode kan bayii.
------------------------------------------------------------------------------------------------------------------
Liz Anjorin Vs Toyin Abraham

Oríṣun àwòrán, @trafficwaka
Laipẹ yii ni ija bẹ silẹ laarin oṣerebinrin meji naa, Toyin ati Liz. Ija ọhun bẹrẹ ni igba ti Lizzy Anjorin fi fidio kan sita l'oju opo instagram rẹ, nibi ti o ti fi ọpọlọpọ eebu ranṣẹ si Toyin.
Ọrọ naa da awuyewuye silẹ ti Toyin si sọ pe oun fi ọrọ yii lọ agbejẹro rẹ, Legal House Solicitors.
AWỌN IROYIN TẸẸ LE NIFẸ SI NIPA RẸ
- Àwọn olólùfẹ̀ Toyin Abraham ati Liz Anjorin ti gbé ọ̀rọ̀ wọn rù sórí, ẹ wo òjò òkò ọ̀rọ̀
- Lizzy Anjorin: Mi ò bẹ Toyin o! Ẹ̀yin olólùfẹ́ mi àti ẹbí ni mo bẹ̀
- Kemi Olunloyo dá sí ìjà Toyin Abraham àti Lizzy Anjorin
- Ọkọ Toyin Abraham pẹ́ ọ̀rọ̀ sọ lórí aáwọ̀ láàrin ìyàwó rẹ̀ àti Lizzy Anjorin
- Ẹ lọ́ jáwé gbé jẹ́ẹ́ sọ́wọ́ bí bẹ́ẹ̀ kọ́..., ẹgbẹ́ òṣèré tíátà pàṣẹ fún Lizzy àti Toyin
- Ìjà Toyin àti Lizzy kìí ṣe àkọ́kọ́, àwọn òṣèré t'ọ́rọ̀ ìjà kàn rí rèé
- Àgbo ṣiṣẹ́ fún mi l'asìkò tí mò ń wojú Olúwa fún ọmọ- Toyin Abraham
Niṣe ni awọn ololufẹ awọn oṣere mejeeji ọhun gbe ọrọ ija naa ru sori.
Lẹyin eyi ni awọn agba ọjẹ ninu iṣẹ oṣere nilẹ Yoruba bii Mr Latin, Jide Kosọkọ àti Mama Rainbow sọrọ lori ija naa, wọn si gbiyanju lati dasi i.
----------------------------------------------------------------------------------
Wọn fi ẹ̀ṣẹ́ ja irawọ Anthony Joshua, o tun fi ẹ̀ṣẹ́ gba a pada
Erongba abẹṣẹ ku bi ojo ọmọ ile Gẹẹsi ati Naijiria, Anthony Joshua, lati fi irawọ kun irawọ rẹ nilẹ Amẹrika ja si pabo ni ibẹrẹ ọdun 2019.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Joshua to ti gba ami ẹyẹ to ga ju lagbo ere idaraya ẹṣẹ kikan lagbaye lẹẹmẹta ọtọọtọ fidirẹmi, to si jẹ iya ajẹbolori lọwọ ẹni ti ko to o, Andy Ruiz lasiko ti wọn koju ara wọn ni Madison Square Garden.
AWỌN IROYIN TẸẸ LE NIFẸ SI NIPA RẸ
Ẹẹmẹrin ọtọọtọ ni Ruiz fi ẹsẹ kan Joshua mọlẹ lai le dide. Eyi lo si mu ko gba ami ẹyẹ nla mẹta, World Boxing Association, International Boxing Federation and World Boxing Organization.
Ṣugbọn nigba ti wọn tun jọ pada ja ninu oṣu Kejila, Anthony Joshua gba igbanu ogo rẹ pada lẹyin to bori Andy Ruiz ninu idije ẹṣẹ kikan to waye ni lu Riyadh ni Saudi Arabi.
Sotitobire Miracle Centre
Ka ma gbagbe, iṣẹlẹ kan wa to ti bẹrẹ si ni gbode lati bii oṣu melo sẹyin ni ilu Akurẹ ipinlẹ Ondo ni ijọ Sotitobire Miracle Centre nibi ti ọmọ ọdun kan, Gold ti dede poora titi di akoko yii.
Lẹyin ọpọlọpọ iṣẹlẹ alatamọ to ti rọ mọ eyi, Pasitọ ijọ naa ṣaa ti wa latimọle titi di dun to mbọ bayii.
AWỌN IROYIN TẸẸ LE NIFẸ SI NIPA RẸ
----------------------------------------------------------------------------------------------------------------
#Sex for Grade
Iṣẹlẹ miran to tun mi igboro Naijiria ni ti fidio iwadii ikọkọ kan ti BBC Africa Eye ṣe lori awọn olukọ fasiti to maa n beere fun ibalopọ lọwọ awọn akẹkọọ obinrin, ki wn o to o fun wọn ni maaki gidi.















