Naira Marley: Wo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó mú Naira Marley di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ lọ́dún 2019

Naira Marley

Oríṣun àwòrán, NAira Marley/ instagram

Azeez Fashola ti ọpọ mọ si Naira Marley jẹ gbajugbaja akọrin taka sufe lorilẹede Naijiria.

Lọwọ ti a wa yii, Naira Marley ti fẹ di oriṣa akunlẹbọ fun ọpọlọpọ awọn ọdọ.

Àkọlé fídíò, Akure Kidnap: Àwọn abiyamọ fẹ̀hónúhàn lórí ọmọ tí wan jígbé nílé ìjọsìn Akurẹ

Bẹẹni pẹlu iroyin ti o jadi laipẹ yii, oun ni ọmọ orilẹede Naijiria ti awọn eeyan ṣe afẹri rẹ juls lori oju opo google lọdun 2019. Koda, igbakeji aarẹ tẹlẹ Atiku Abubakar pẹlu gbajugbaja agbabọọlu ni Neymar ko lee duro lẹgbẹ rẹ.

Eyi ni awọn diẹ lara iṣẹlẹ to sọ gbajugbaja akọrin naa di oriṣa akunlẹbọ lọdun 2019.

Naira Marley pẹlu Simi

Naira Marley

Oríṣun àwòrán, NAira marley/instagram

Ni oṣu karun ọdun 2019 ni akọrin ara, Simi pariwo sita lori ikanni ayelujara lati koro oju si bi awọn ọdọ ṣe n kan si agbami iwa jibiti ori ayelujara.

Eyi lo si fa itahunsira laarin oun ati Naira Marley.

Naira Marley koju ija si Ruggedman

Kii ṣe Simi nikan ni Naira Marley ba wọ iya ija lori ọrọ boya jibiti ori ayelujara, yahooyahoo tọna paapaa julọ lẹyin orin 'Am I a yahoo boy?' to gbe sita. Ọkan lara awọn odu asọrọdorin lorilẹede Naijiria, Ruggedman pẹlu sọ si ọrọ naa ninu eyi to ti ni ko dara ki awọn olorin, gẹgẹ bi awokọṣe lawujọ o maa gbe lẹyin awọn oni yahooyahoo. Eyi ko dun mọ Naira Marley ninu, o si fi esi ọrọ kobakungbe ranṣẹ sii lori ayelujara. Koda awọn ololufẹ Naira Marley kan tilẹ kọlu Ruggedman ni ilu Gẹẹsi lori ọrs yii gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ.

Naira Marley ninu gbaga ajọ EFCC fun ẹsun jibiti ori ayelujara.

Naira Marley

Oríṣun àwòrán, NAira marley/instagram

Ni ọjọ kẹwa oṣu karun un ọdun 2019 lawọn oṣiṣẹ ajọ EFCC mu Naira Marley niluu Eko. Ẹsun mọkanla ni wọn fi kan an eyi to da lori gbigbimọ pọ lati huwa ibi, ninu ayederu kaadi igbawo lọwọ pẹlu iwa jibiti.

Oniruuru iọọrọ odi si ni Naira Marley dojukọ fun ṣiṣe atilẹyin fun iwa jibiti ori ayelujara ti ọpọ mọ si yahoo-yahoo.

Lẹyin to lo ọpọlọpọ ọsẹ ni ọdọ awọn ajọ EFCC ni ile ẹjọ gba oniduro rẹ.

Lati igba ti ọrọ igbẹjọ rẹ naa ti bẹrẹ lo si ti di gbajugbaja ni aarin awọn ọdọ, paapaa julọ awọn to rii gẹgẹ bii ẹni to n ja fun awọn ọdọ nitori aarin awọn ọdọ ni yahoo-yahoo pọ si julọ.

Ariwo Marlian! Marlian !! lo gbode kan bayii.