Olóbinrin ilé: 'Ọ̀làjú ti dé obìnrin ò nílo láti ma ṣe iṣẹ́ aṣekú.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ibi ti aye kọjú sí fẹ́ni kan, ẹ̀yìn ló kójú si fún elòmíràn, èyí ló dífá fú àwọn àlejo lóri ètò "Níbo Laye Koju" ti BBC Yoruba maa n ṣe lọ́sẹ̀ẹ̀sẹ̀ níbi tàwọn abilekọ meji ti sọ èrò ọkan wọ́n lóri ọ̀rọ̀ olóbinrin ilé láye atijọ àti láye òde òní.
Nínú àlayé wọ́n arabinrin Mariam Fashola ti wọ́n ti jẹ́ abilekọ lati igbà pípe díẹ̀ sàlàye pé ànfani to pọ ló wà nínú ṣíṣe olobinrin ilé, sùgbọ́n o fi kún pé ó ṣeni lápanu pé ọ̀pọ̀ ló ti sọ àsà yìí nú èyí ti kò sì yẹ ki ó rí bẹ́ẹ̀.
O ní ó jẹ ọkan gbòógi nínú àṣà ati ìṣé ilẹ̀ Yoruba, èyi sì lo máà n kó ẹbi papọ fún ayẹyẹ kan tàbi òmíràn, nínú ọ̀rọ́ rẹ, èyi máà n mú ìrẹ́pọ àti ìfẹ́ wà láàrin ẹbi.
Bẹ́ẹ́ si lo sọ pé àgbárijọpọ àwọn obinrin yiìí ń jẹ ki ìtẹriba wà to si n fún òbi láànfàni láti kọ àwọn ọmọ lọ́na rere.
Arabinrin, Fashola tún sàlàye pé ìwà ọ̀lẹ ni ko jẹ́ ki àwọn obinrin míràn lọ fun iṣẹ́ olobinrin ilé.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Sùgbọ́n ni ti arábinrin Zainab Suleiman nitirẹ o sàlàyé pé kìí ṣe ìwà ọlẹ rárá bíko ṣe pé o ṣe pàtàki láti fi àsìkò náà tọju ẹbi àti àwọn ọmọ.
O sọ pé, o ṣe pàtàki láti gbé irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ fún àwọn ti o jẹ́ pé iṣẹ́ wọ́n ní, o ní ọlaju ti dé àtipé gbogbo àwọn ayelujara ti mu ki ǹkan dẹrun nitori pe gbogbo obinrin ile lé jo ṣe ipade bi nkan yóò ṣe lọ eyi ti wọn o si jọ dáwo papọ láti ṣe ǹkan to tọ.
Nínú àlàyé rẹ ti wọ́n ba ran owo niṣẹ́, yóò fun wọ́n láànfani láti rí ààye fun ara wọ́n nitori pé láye òde oni, bi ọkọ ṣe n lọ si ibiṣẹ́ òòjọ rẹ̀ náàni ìyàwó ń lọ nítori náà kò dẹ̀run láti lọ máa ṣiṣẹ́ olóbinrin ilé.
Suleiman fi kún pé àilọ si ode olobinrin ilé kò tún mọ si pe àṣà n parun tàbi pé kò si ẹkọ ilé fún ọmọ tàbi ìyàwó ilé láti ma bọ̀wọ̀ fún àwọn ìyàwo ile to ba jùúlọ.












