Google Top Search 2019: Naira Marley na Atiku pa nínú àwọn orúkọ tàwọn èèyàn ń wá jùlọ ní 2019

Naira Marley

Oríṣun àwòrán, Instagram/nairamarley

Àkọlé àwòrán, Orukọ Naira Marley gbode kan lọdun yii lẹyin ti ajọ EFCC fi pampẹ ofin mu lori ẹsun jibiti

Ileeṣẹ atẹ imọ oju opo ayelujara Google ti ṣe agbejade orukọ ati awọn nkan tawọn eeyan n wa iroyin nipa rẹ julo loju opo rẹ fọdun 2019.

Wọn sọ nipa awọn nkan to ni ṣe pẹlu ibeere, awọn gbajugbaja eeyan, olorin, ere fiimu ati iroyin tawọn eeyan n wa nipa rẹ.

Ni isọri isọri, ni wọn ṣe agbekalẹ yi ṣugbọn eleyi to kan wa ni Naijiria la ni ki a ṣe atupalẹ rẹ fun ara wa.

Naira Marley lọwọ awọn agbofinro

Oríṣun àwòrán, OTHER

Marlians Marlians Marlians!!!

Gbajugbaja olorin Naijiria Afeez Fashola ti gbogbo eeyan mọ si Naira Marley ni orukọ rẹ leke ninu orukọ awọn ilumọọka ni Naijria tawọn eeyan n bere ọrọ nipa wọn.

Atiku Abubakar to du ipo aarẹ ninu idibo aarẹ Naijiria lọdun 2019 naa tẹlẹ ti agbabọọlu nii Neymar ati alaga awọn awakọ ipinlẹ Eko, MC Oluomo naa ko gbẹyin.

Mc Oluomo

Oríṣun àwòrán, Instagram/mcoluomo

ASUU Strike lalẹ garaga oju opo ni tawọn eeyan fẹ ka nipa rẹ

Ni abala ibeere nipa iroyin, iyanṣẹlodi awọn olukọ fasiti Naijiria ti o gbẹnu tolori tẹlẹmu wa lara awọn iroyin tawọn eeyan bere nipa rẹ julọ ni 2019 ni Naijiria.

Idije bọọlu afẹsẹgba ilẹ adulawọ AFCON 2019 naa wa lara awọn to lewaju ti Naira Marley tun ja wọ abala yi to fi mọ ibeere nipa Women's World Cup 2019 ati Xenophobia.

Aworan agbabọọlu Naijiria Chukwueze ati akẹgbẹ rẹ ọmọ South Afrika

Oríṣun àwòrán, GIUSEPPE CACACE

Àkọlé àwòrán, Ẹni a ba laba ni baba

Labala awọn olorin ti awọn eeyan n wadi iroyin nipa wọn julọ ni Naijiria lọdun 2019, Zlatan, Burna Boy,Naira Marley,Teni ati Kizz Daniel wa lara wọn.

Ninu awọn kan miran tawọn eeyan nwadi loju opo Google la ti ri :

  • Bi eeyan ti ṣele ṣe ẹgusi
  • Big Brother Naija
  • Kini o n jẹ Ruga?
  • Ọrọ orin Davido Risky
  • Ọrọ orin Soapy Naira Marley
  • Woske

Lọdọọdun ni ile iṣẹ Google ma n gbe orukọ ati awọn ọrọ tawọn eeyan n bere nipa rẹ julọ loju opo rẹ jade .