Ayo Fayose: Gómìnà àná ìpínlẹ̀ Ekiti tọrọ àforíjìn, ó ní PDP gbọdọ̀ gbapò gómìnà padà

Ayo Fayose atawọn ọmọ ẹgbẹ PDP

Oríṣun àwòrán, Twitter/Peter Ayodele Fayose

Àkọlé àwòrán, Gómìnà àná ìpínlẹ̀ Ekiti tọrọ àforíjìn, ó ní PDP gbọdọ̀ gbapò gómìnà padà
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

A kii rin, ki ori maa ma mi. Eyi lo difa fun gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ ri, Ayodele Fayoṣe to tọrọ aforijin lọwọ gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ naa.

Fayoṣe sọrọ yii nibi ipade ibara ẹni laja laarin awọn olori atawọn eekan inu ẹgbẹ PDP to waye nile rẹ ni Afao Ekiti lọjọ Iṣẹgun.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Sẹnẹtọ Biodun Olujimi, Duro Faṣeyi to jẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin l'Abuja tẹlẹ ati alaga ẹgbẹ PDP nipinlẹ Ekiti, Oloye Gboyega Oguntuwase ti wọn jẹ adari ẹgbẹ naa ni iyapa wa laarin awọn.

Fayoṣe ni ''ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ekiti nilo atunṣe lọna ti yoo mu ilọsiwaju ba ẹgbẹ wa, ohun to ku fun wa bayii ni lati fọwọsowọpọ lati gbe PDP ga lẹẹkan si l'Ekiti.''

Àkọlé fídíò, Akure Kidnap: Àwọn abiyamọ fẹ̀hónúhàn lórí ọmọ tí wan jígbé nílé ìjọsìn Akurẹ

''Mi o dije fun ipo kankan mọ, amọ mo fẹ ki PDP jawe olubori ninu ibo gomina pada l'Ekiti. Ojuṣe mi si ni pe ki ẹgbẹ PDP maa kuna nipinlẹ Ekiti,'' Fayoṣe lo woye bẹẹ.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Fayoṣe lo anfaani ipade naa lati bẹ Sẹnẹtọ Olujimi, Faṣeyi ati Oloye Oguntunwaṣe wi pe ki wọn forijin oun ti oun ba ṣẹ wọn.

O ni oun ko figba kankan gbero lati ba awọn olori ẹgbẹ PDP ja, bakan naa lo sọ pe awọn to n mu iyapa wa ẹgbẹ naa n ṣe e fun anfaani ara wọn ni.

Igbakeji Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ọjọgbọn Kolapo Olusola, Kọmiṣọnna fun ọrọ ayika tẹlẹ, Oloye Bisi Kolawole ati ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Samuel Omotoṣo atawọn mii lo wa nibi ipade naa.

Àkọlé fídíò, Bi ìyàwọ mi ṣe n jábọ́ sí kọ́tà ló jẹ́ kí n kọ́ka fura pé kò ríran mọ́- ọkọ Dorcas