Aàrẹ Buhari yẹ́ aga nidi Muiz Banire,ó yan Edward Adamu lalága AMCON

Aworan Muiz Banire

Oríṣun àwòrán, Muiz Banire

Àkọlé àwòrán, Aàrẹ Buhari yẹ́ aga nidi Muiz Banire,ó yan Edward Adamu lalága AMCON

Lẹyin ọdun kan le diẹ nipo Aarẹ Buhari ti juwe ọna ile fun Muiz Banire to jẹ alaga ileeṣẹ to n ṣe onidurọ fawọn ile ifowopamọ ni Naijiria (AMCON)

Lọsan ọjọ Iṣẹgun ni ikede yi lu sita ninu iwe kan ti ileeṣẹ aarẹ fi ranṣẹ si aarẹ ile aṣofin agba Naijiria.

Ọgbẹni Edward Adamu ni aarẹ fi orukọ rẹ ranṣẹ gẹgẹ bi ẹni ti yoo gba ipo Muiz Banire.

A ko ti i ribi fidiẹ mulẹ idi ti aarẹ fi gbe igbesẹ yi ṣugbọn Banire ko tii pẹ pupọ lori oye naa.

Koda nigba ti aarẹ Buhari fi orukọ rẹ ranṣẹ si ile aṣofin agba, awọn oloṣelu kan ninu ẹgbẹ APC dide lati tako iyansipo rẹ.

Ṣaaju ki o to jẹ alaga AMCON, Banire ni kọmiṣọnna fun eto ayika nipinlẹ Eko ti o si tun fi igba kan jẹ oludamọran lori ọrọ ofin fun ẹgbẹ oṣelu APC.

Yatọ si Banire ti aarẹ gba iṣẹ lọwọ rẹ, Tunde Fowler ti ohun naa jẹ ọkan lara awọn wọlewọde fun igbakeji aarẹ Yemi Osinbajo naa ni aarẹ kọ lati yan sipo pada lẹyin saa rẹ gẹgẹ bi ọga agba FIRSAàrẹ Buhari júwe ilé fún Babatunde Fowler, ó yan Muhammed Nami .

Àkọlé fídíò, Silas Robotic Engineer: Kò sí ǹkan rere tí ọmọ Nàìjíríà kò lè ṣe