Sanna Marin: Obasanjo, Gowon, Muhammed- wo àwọn olóri Nàìjíríà lọ́dọ̀ọ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iroyin nipa orilẹde Finland to fẹ ṣe ibura fun ọdọmọde Olootu ijọba lo gba ayelujara kan.
Iroyin yii lo n jẹ ki ọpọ beere nipa ki ọdọ ṣe ijọba ti awọn anfaani inu rẹ.
Ni orilẹ-ede Naijiria naa sẹyin, awọn ọdọ ti ṣe olori orilẹ-ede wa sẹyin ti wọn si gbiyanju ni bi apa eku ṣe mọ ti wọn ti fi nu oju lasiko naa.
Bẹẹ, ti ọmo ko ba ba itan, o di dandan ko ba arọba to jẹ baba itan.

Oríṣun àwòrán, others
Ogagun Yakubu Gowon ọmọ ọdun mọkanlelọgbọn nigba ti o n ṣe ijọba:
Yakubu Gowon jẹ olori orilẹ-ede Naijria lọdọ.
A bii ni ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹwaa, ọdun 1934.
O je olori kẹta fun Naijiria lati ọjọ kinni, oṣu kẹjọ, ọdun 1966 si ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu keje, ọdun 1975.
Ogagun Murtala Muhammed naa tukọ Naijiria lọmọ ọdun mẹtadinlogoji:
A bi Murtala Mohammed lọjọ kẹjọ, oṣu kọkanla, ọdun 1938.
O ṣe olori Naijiria kẹrin bẹrẹ lati ọgbọn ọjọ, oṣu keje, ọdun 1975 si ọjọ kẹtala, oṣu keji, ọdun 1976.

Oríṣun àwòrán, Other
Ogagun Oluṣẹgun Obasanjọ, ẹni ọdun mọkandinlogoji
A bi Oluṣẹgun Obasanjọ ni ọjọ karun un, oṣu karun un, ọdun 1937.
Oun ni olori orilẹ-ede ikarun un ti Naijiria ni.
O ṣe ijọba alakọkọ rẹ lati ọjọ kẹtala, oṣu keji ọdun 1976 lẹyin iku Murtala si ọgbọn ọjọ, oṣu kẹsan an, ọdun 1979.
Lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu karun un, ọdun 2018 ni Aarẹ Buhari buwọlu abadofin: 'Not too young to run', pe kọ si ọmọde ti ko le dije dupo,
Ofin yii lo din ọjọ ori awọn ọdọ to le dije dupo aarẹ Naijiria ku si ọgbọn lati ogoji.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Sanna Marin, ọmọ ọdun 34 to di olóòtú ìjọba tó kéré jùlọ láyé
Ni gbogbo agbaye lọwọ lọwọ, Sanna Marin lo kere julọ to jẹ olootu ijọba orilẹ-ede.
Omo ọdun mẹrinlelọgbọn yii jade labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party ni orilẹ-ede Finland.

Oríṣun àwòrán, @Sanna
Kete ti adari wọn , Antti Rinne kuro nipo gẹgẹ bi olootu ijọba Finland ni wọn ti yan minista fun eto irinna wọn sipo.
Lọsẹ to m bọ ni wọn maa ṣe ibura fun ọdọmọde olootu ijọba yii ni Finland.
Oun lo maa ṣaaju awọn adari ẹgbẹ oṣelu maraarun to wa ninu ijọba ilẹ naa.
Sanna ati awọn obinrin mẹta miran ti ọjọ ori wọn ko tii pe ọdun marundinlogoji ni wọn jọ maa tukọ orilẹ-ede Finland.
Obinrin ni awọn adari ẹgbẹ maraarun to n tukọ iṣelu wọn.
Ogbeni Rinne kọwe fipo rẹ silẹ lẹyin ti awọn kan ni awọn ko nigbagbọ ninu rẹ mọ gẹgẹ bii adari ijọba.
Wọn ni wọn ko dunnu si bo ṣe ṣe ọrọ iyanṣẹlodi awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ifiweranṣẹ to ṣẹlẹ ni finland.
Kete ti wọn ba ti bura fun Sanna lo maa di olootu ijọba to kere julọ lagbaye yatọ si Jacinda Ardern to jẹ omo ọdun mọkandinlogoji to n tukọ New Zealand ati Oleksiy Honcharuk to jẹ marundinlogoji to jẹ olootu Ukraine
Ta ni Sanna Marin?
Sanna ni ẹni akọkọ ninu iran rẹ to maa kawe gboye ni fasiti.
Lọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn lo ti n ṣoju ẹkun rẹ ninu ijọba.
O di ọmọ ile igbimọ aṣofin agba lọmọ ọgbọn ọdun.
O di minista fun eto irinna orilẹ-ede Finland lọdun 2019.
O jẹ iya fun ọmọ obinrin to jẹ ọmọ oṣu mejilelogun
Kete ti wọn kede Sanna lo sọ fun awọn akọroyin pe iṣẹ pọ lọwọ ijọba oun lati ṣe lẹyin idibo yii.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
O ni: Emi ko ro nipa ọjọ ori mi tabi pe obinrin ni mi, koko to mu mi lọkan ti mo fi n ṣe oṣelu ni lati lati mu igbe aye tubọ rọrun sii fawọn eniyan mi ki awọn oludibo le gbọkan le mi pe mi ko ni jẹ koju ti wọn.
















