Yobe Lawan: Wọ́n ti ní kí Baalẹ̀ Yobe lọ rọọ́kún nílé torí ẹ̀sùn pé o fipá bá ọmọdé sùn

Yobe

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán, Gomina ipinlẹ Yobe ti ni ki Lawan Mari ti wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó fipé bá ọmọ ọdún mẹ́fà sùn ni Yobe

Gomina ipinlẹ Yobe, Mai Mala Buni ti kede pe ki Baalẹ ilu Fananami, Lawan lọ rọọkun nile.

Gomina ṣe ikede yii lataari ẹsun ti wọn fi kan Baale Lawan Mari ni Gashua pe o fipa ba ọmọ ọdun mẹfa ọkunrin kan sun ni ilu wọn ni ijọba ibilẹ Bade ni ipinlẹ Yobe.

Kọmiṣọna fun ọrọ ile, eto ifitonileti ati aṣa lo ṣe ikede yii lorukọ Gomina ni Damaturu to jẹ olu ilu ipinlẹ Yobe ni ariwa Naijiria.

Àkọlé fídíò, Èyí ni ìtàn bí ẹni tí mó gbọ́njú mọ̀ bíi bàbà ṣe fipá bá mi lájọṣepọ̀

Ogbẹni Abdullahi Bego to jẹ kọmiṣọnna yii ṣalaye pe iwa buruku gbaa ni ẹsun ti wọn fi kan odindin Emir ilu naa.

O ni Gomina Buni ti ni ki iwadii bẹrẹ ni kia lai ṣegbe fẹnikan ki ọwọ ofin si mu Baale naa to ba jẹbi ẹsun ọhun lẹyin iwadii kikun.

Kọmiṣonna ni ikede pe ki Baalẹ lọ rọọkun naa wa ni ibamu titi ti wọn yoo fi pari iwadii naa ti yoo fi otitọ ohun to ṣẹlẹ han.

Yobe

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán, Wọ́n ti ní kí Baalẹ̀ Yobe lọ rọọ́kún nílé torí ẹ̀sùn pé o fipá bá ọmọdé sùn

O ni wọn ti ṣayẹwo to yẹ fun ọdọmọde naa ti ọrọ kan nile iwosan bi o ti yẹ ati pe wọn ti ṣe akọsilẹ ipo ti wọn baa.

Àkọlé fídíò, Bi ìyàwọ mi ṣe n jábọ́ sí kọ́tà ló jẹ́ kí n kọ́ka fura pé kò ríran mọ́- ọkọ Dorcas

Ile iwosan ijọba apapọ ni Gashua ni wọn ti ṣe itọju to yẹ fun ọmọ ọdun méfa naa.

Àkọlé fídíò, Pẹtẹsi akọkọ ni Naijiria