Sowore: Àjọ DSS tọrọ àforíjìn lórí ìwà ti wọ́n hù nílé ẹjọ- Femi Falana

Agbẹ́jọrò ajàfẹ́tọ ọmọniyan Femi Falana (SAN) ní irọ́ pọ́nbélé ni ọ̀rọ̀ ti àwọn àjọ DSS sọ pé àwọn kò da èto ilé ẹjọ giga jùlọ rú lọ́jọ́ Jimọ to kojá lásìkò ti wọ́n ń gbìyànjù láti mú Omoyele Sowore.
Falana nínú àtẹjáde kan to fi síta lati lòdì sí ìrọ́ ti ajọ DSS fi síta ninú atẹjáde tiwọ́n pe àwọn kò da ìjókó ilé ẹjọ́ rú lọ́jọ́ Sátide,
O fí kun un pé ọlọri ajọ DSS tilẹ̀ wá tọrọ àforijín fún ìhùwàsí wọ́n níwáju adájọ Ojukwu Ijeoma.
Falana ní àjọ DSS o lé fọ́wọ́ ìwà ìbàjẹ́ wọ́n gbári, nítori náà kilóde ti wọ́n bẹ adájọ ti wọ́n mú ni pápá mọ́ra láti mu opin wa si ètò ilé ẹjọ nígbà ti wọ́n ya wọ ilé ẹjọ.

Oríṣun àwòrán, Falana
O sàpàjúwé àtẹjáde àgbẹnusọ DSS to fi síta lọjọ Sátije gẹ́gẹ́ bi ẹni pé ènìyàn ń tako ara rẹ àti ọ̀gbọ́n láti bo àṣiri pé àwọn ò huwà aitọ,
Bi wọ́n ṣe ya wọ ilé ẹjọ àti bi wọ́n ṣe tẹ òfin lójú mọlẹ̀ pàápàá jùlọ adájọ Ojukwu àti ọ̀nà àitọ ti wọ́n gbà mú Omoyele Sowore ko dara rara.
"Àjọ DSS ko lé yọ ara rẹ kúro nínú ìwà ìtinilóju yìí ní ọjọ kẹfa, oṣu Kejila, ọdun 2019."
Falana ní ìwà àìtọ tí ajọ náà hù, gbàngba ojú ayé ló ṣe yala si àwọn ènìyàn Naijiria ni tàbi àwọn ara ilẹ̀ okere pàápàá jùlọ awọn oníròyìn
O pè fún ìtúsílẹ̀ Sowore ni kíakía àti awọn míràn ti wọ́n tì mọ́lé àti awọn ti wọ́n ti gba oníduro fún ti wọ́n si tún fi si àhámọ.














