Phone Battery: Wo bí o ṣe lè jẹ́ kí bátììrì fóònù rẹ pẹ́ síi

Oríṣun àwòrán, @others
Ohunkohun ti ẹda ba n ṣe laye yii, o yẹ ki a fi tọkan tara ṣee ni- Ọjọgbọn
Nigba ti ọjọgbọn Akira Yoshino bẹrẹ iṣẹ iwadii rẹ lori lilo batiri tuntun ti ẹmi rẹ yoo gun sii nibẹrẹ 1980; ko mọ pe pe iwadii naa maa di nla mọ oun lọwọ.
O ni erongba oun ni ibẹrẹ iwadii naa ni pe kamẹra oni milimita mẹjọ a le maa lo batiri naa fun ọpọ wakati.
Akira ni iyalẹnu lo jẹ nigba ti iṣẹ iwadii naa n di nla ti o fi di itẹwọgba ni gbogbo agbaye bayii.
Iṣẹ iwadii lagbaye ti gbọrẹjẹgijẹ de ibi ti burọọṣi ifọyin, foonu, ati ọpọ nkan idana naa ti n lo batiri bayii.
Lodun 2019 ni wọn fun ọjọgbọn Yoshino ni ami ẹyẹ to ga julọ lagbaye ninu Chemistry to jẹ imọ sayẹnsi.
Awọn ọna wo ni batiiri rẹ ṣe fi le pẹ sii lọwọ rẹ?
1) Pa ibi to n sọ ibudo ti o wa ninu foonu rẹ. Pa àwọn aapu bii afihan ibudo ti o wa ati maapu lasiko ti o ko ba lo wọn.
2) Ṣọra fun yiya fọto tabi fidio ni igba gbogbo lojoojumọ. Ọpọ lo maa n tan kamẹra foonu wọn silẹ nitori pe iṣẹju kọọkan ni wọn fi n ya fọto.
3) O ṣeeṣe fun ẹ lati paṣẹ fun foonu rẹ pe ko má lo batiiri pupọ nipa titan ibi ti wọn pe ni 'Low battery mode' ninu foonu rẹ.
4) Yọọ kuro ni pe ko maa gbọ̀n rìrì bíi ẹlẹgun Sango. Eyi maa n jẹ batiri pupọ bo ṣe n gbọn yẹn.
5) Pa awọn ifitonileti iṣẹju iṣẹju to n sọ nipa awọn atẹjiṣẹ to n wọle bi wọn ṣe n wọle.
6) Pa awọn aṣẹ to ni ṣe ki foonu rẹ maa ṣatunṣe sawọn nkan ti o n wọ ori foonu rẹ bii fidio to maa bọ sinu rẹ ni kete to ba ti de ori ẹrọ ibanisọrọ rẹ.
7) Yọ awọn aapu ti o ko nilo tabi ti o kii lo nigba gbogbo
8) Ṣe adinku si bi oju foonu rẹ ṣe mọlẹ to. Bi foonu ba ṣe n tan ina si ni odiwọn batiiri to maa lo.
9) Fi ara balẹ ṣakiyesi bi batiiri foonu rẹ ṣe n lọ, eyi yoo jẹ ki o maa kiyesi ti o ba ti fẹ ku lainii fi ṣe odiwọn nọmba to gbe soju.
10) Ṣọra fun fifi foonu rẹ si ibi to gbona bii inu oorun tabi ibi to tutu pupọ nitori bi oju ọjọ agbegbe too fi foonu si ṣe ri maa n jẹ ki o tun bajẹ
11) Sọra fun fifi foonu rẹ sinu ina nigba gbogbo, rii pe batiiri rẹ ti fẹ tan ki o to kii bọ inu ina. Eyi tumọ si pe ko maṣe fi foonu rẹ sinu ina di oru mọju rara.
12) Ma ṣe lo batiri rẹ de ibi pe o maa ku patapata to jẹ ida odo ninu ọgọrun un tabi koo maa fi sina si ida ọgọrun un nigba gbogbo.

Oríṣun àwòrán, Reuters
13) Rii pe ṣájà ti o ba foonu ré wa ni o n lo fun foonu re nitori awọn ṣájà miran maa n ba foonu jẹ. Eyi lo difa fun pe ki o ṣọra fun lilo ṣájà inu mọto ti ko dara to.
14) Maa fi igbagbogbo pa Blutooth ti a fi n fi nkan ranṣẹ ati ayelujara wi-fi ti o ko ba nilo wọn nigba gbogbo tabi ki o fi si ti o ba wa lori afẹfẹ.
15) Ma sọrọ pẹ ju lasiko kan nigba ti o ba n gba ipe lori ẹrọ ibanisọrọ rẹ.
Ọjọgbọn yii gba awọn ọdọ nimọran lati tẹra mọ iṣẹkiṣẹ ti onikaluku yan laayo nitori pe ohunkohun ti o ba dawọle yẹ koo ṣee daadaa de ibi ere.
Ọjọgbọn yii sọrọ lori ibi ti iṣẹ de duro ati iṣẹ iwadii to ṣi n tẹsiwaju kaakiri ki batiri le maa pẹ ko too jo tan lasiko yi.
















