Elephants Death: Erin mẹ́fa d'olóògbé níbi tí wọ́n ti fẹ́ dóòlà ẹ̀mí ara wọn

Awon eerin ni Thailand

Oríṣun àwòrán, Khao Yai National Park

Àkọlé àwòrán, Erin mẹ́fa d'olóògbé níbi tí wọ́n ti fẹ́ dóòlà ẹ̀mí ara wọn

Erin mẹfa ṣagbako iku lorilẹ-ede Thailand nibi ti wọn ti n gbiyanju lati doola ẹmi ara wọn.

Awọn oṣiṣẹ ọgba ẹranko Khao Yai National Park lorilẹ-ede Thailand ṣalaye pe ọmọ erin kan lo yọ ṣubu nibi ida omi tawọn erin mi ṣi fẹ doola ẹmi rẹ.

Nibi ti wọn ti n gbiyanju lati rii wi pe ọmọ erin naa ko ku lawọn naa gbọjọ iku wọn.

Koda, awọn alaṣẹ ọgba ẹranko naa daabo bo erin meji miiran ti wọn tun fẹ yọ ṣubu lori oke ti ko jina si ibi tawọn erin mẹfa ti ku.

Ida-omi yii ti wọn n pe orukọ ni Haew Narok ni wọn sọ pe iru iṣẹlẹ bayii ti wọpọ ni bẹ.

Àkọlé fídíò, Ogun Cholera: Ọdọọdún ni àrùn onígbá-méjì máa n ṣọṣẹ́ ní Nàìjíríà-NCDC

Akọsilẹ fihan pe erin mẹjọ lo ku lọdun 1992 nibẹ, eyi to jẹ ki ijọba Thailand jiroro lori ọrọ naa.

Ibẹ maa n yọ awọn ẹranko ti wọn ba n kọja lati igba de igba ni.

Oku erin ni Thailand

Oríṣun àwòrán, Thailand DNP

Àkọlé àwòrán, Erin mẹ́fa d'olóògbé níbi tí wọ́n ti fẹ́ dóòlà ẹ̀mí ara wọn

Awọn oṣiṣẹ ọgba ẹranko lorilẹ-ede Thailand sọ pe awọn kan lo ṣaa deede pe akiyesi awọn lọjọ Abamẹta to kọja si awọn erin ti wọn duro soju ọna to lọ si ibi ida omi ọhun.

Lẹyin wakati mẹta lawọn oṣiṣẹ ọgba ẹranko naa ko oku ọmọ erin kan ati atawọn marun un miiran nitosi ara wọn.