Ugbochukwu Michael: Ààrùn kòkòrò HIV kìí ṣe ìdájọ ikú
Ọ̀rọ̀ pé ẹní ti wọ́n ba ti sọ fún pé, ó ni ààrùn kòkòrò HIV ti gbá ọjọ́ ikú rẹ̀ ti di àfi ẹyín ti èègún ń fisọ. lórilẹ̀-èdè Naijiria.
Ọgbẹ́ni Ugbochukwu Michael to n ṣe etò alárina láàrin awọn oníkòkò HIV meji lorí Redio kan nílu Abuja sàlàye fún BBC pé èyí ti ń mú ojútu ba ọ̀pọ̀ àwọn ti kò ni ìrètí mọ nítori pé lùgbàdì ààrùn kòkòrò HIV.
O ní òun ko le ka ènìyàn to ti dí ọlọkọ tabi aláya nipasẹ èto ti ó ń ṣe, o ni ẹ̀rí orísirísi lo si ti n tibẹ̀ jáde.
Ọkan lára àwọn ti Michael ti ṣe ètò náà fún jẹ́rí sí ìgbéyàwọ aládùn ti òun wà lọ́wọ́lọ́wọ́, to si jẹ pé àwọn méèjèjì náà ni àwọn jọ ni ààrùn sùgbọ́n àwọn ń gbe igbé ayé ayọ àti aláfíà