Gómìnà Kwara: A kò ní w'ojú olóṣèlú kankan to bá pín nínú owó N5bn ní Kwara

Abdulrahaman
Àkọlé àwòrán, Laipẹ yi ni EFCC jú alága ìjọba ibílẹ̀ 16 si àhámọ́ lóríi ẹ̀sùn àjẹbánu ní Kwara

Ijọba ipinlẹ Kwara ti leri lati fi ijiya to tọ jẹ eyikeyi aṣofin ipinlẹ naa to ba lọwọ ninu apapin owo biliọnu marun un Naira ti aṣiri lu sita pawọn aṣofin ile ana kan pin.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ Gomina,Rafiu Ajakaiye fi sita lọjọ Abamẹta, o ni bo ṣe ẹni to ti fi ipo silẹ, tabi eleyi to wa lori oye, ko si ni ti yoo lọ lalai koju ijiya ofin ti wọn ba jẹbi.

Atẹjade naa to n fesi si iroyin kan to tati ọwọ EFCC jade pe awọn ti ṣe iwadi ri bi awọn aṣofin ile aṣofin ipinlẹ ana kan ti ṣe ṣapapin biliọnu marun un naira owo ajọ to n gbowo ori nipinlẹ Kwara.

EFCC darukọ alaga ajọ naa to ti fi ipo silẹ,Ọjọgbọn Muritala Awodu,ọmọ ile aṣofin ipinlẹ naa kan lana,Moshood Bakare ati awọn awọn oṣiṣẹ KWIRS gẹgẹ bi awọn to lewaju nibi apapin owo yi.

Bakanaa ni EFCC sọ pe awọn ile iṣẹ marun un kan ti o jẹ tawọn ilumọọka oloṣelu nipinlẹ naa gba biliọnu mẹrin ninu owo yi lalai ni iwe adehun iṣẹ agbaṣe pẹlu ijọba.

Abdulrahaman
Àkọlé àwòrán, Laipẹ yi ni EFCC jú alága ìjọba ibílẹ̀ 16 si àhámọ́ lóríi ẹ̀sùn àjẹbánu ní Kwara

Iwaadi EFCC ti wọn lawọn ṣe ọhun tun ṣalaye pe gbogbo awọn awọn ọm ile aṣofin ni ṣaa oṣelu to kọja lo pin ninu owo yi to fi mọ olri ile aṣofin,Ali Ahmad.

Ninu ọrọ to tẹnu ọkan lara awọn oṣiṣẹ KWIRS to jẹwọ fun EFCC,o ni ''Kọmisana eto ọrọ aje tẹlẹ Ademola Banu a ma gba miliọmu Naira loṣooṣu lalai ṣiṣẹ fun''

''Koda emi ni mo ma n gbe owo naa lọ ba nile rẹ,bi a ko ba fun ni owo naa, ko ni buwọlu ohunkohun ta ba gbe lọ ba''

Gomina Kwara wa tẹpẹlẹ mọ ifarajin ijọba rẹ lati ri pe gbogbo awọn to ba n gba ọna ẹburu ji owo ijọba yoo foju wina ofin