EFCC: Ọmọ Nàíjíríà ń bèèrè pé báwo ní àjọ náà ṣé mọ èké babaláwo?

Oríṣun àwòrán, EFCC
Babalawo kan, Fatai Olalere Alli, ti inagijẹ rẹ n jẹ baba Osun to tasẹ agẹrẹ sofin, tọwọ sinkun ajọ EFCC si baa, ni adajọ kan nile ẹjọ giga nilu Ibadan ti ni ki wọn lọ fi si ahamọ.
Ajọ EFCC to fi isẹlẹ naa sita loju opo Twitter rẹ tun kede pe bakan naa tun ni oun ko awọn eeyan meji mii, Adigun Fatai Olusegun ati Olufemi Kolawole sahamọ.
Ajọ EFCC fikun pe adajọ tun faye gba oun lati gbẹsẹ le awọn ile kan to jẹ ti babalawo naa ati akoto owo ti wọn lawọn fura si pe o fi n ṣe gbajuẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Obìnrin gbọdọ̀ ṣe ara wọn lọ́kan láti gba ara wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ ìfìyàjẹni - Olùdásìlẹ̀ ẹgbẹ́ FIN
- Sinimá oríta, àwòòtán. Ambode gbé ilé aṣòfin Eko relé ẹjọ́
- APC, ẹ bá wa bẹ Buhari kó ṣí bodè ká kó ìrẹsì wọlé - Ìjọba Vietnam ń bẹ̀bẹ̀
- Àwọn ológun tó fẹ́ maa yẹ káádì ìdánimọ́ aráàlú wò, ìwà àìríṣẹ́ ṣe ni - Ilé aṣòfin
- Ọjọ́ mẹ́rin sí ìgbéyàwó wa ní ìyàwó mi b'ómi lọ- Ibrahim Abubakar
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ẹsun ti wọn fi kan awọn afurasi ọhun ni pe wọn lẹdi apo pọ lati gba owo lọna ti ko tọ, eyi taa mọ si 419.
Bawo ni EFCC ṣe mọ pe ayederu babalawo ni?
Ibeere yii lawọn eeyan n beere loju opo Twitter EFCC, lati fesi si ikede iroyin ti wọn fi sita naa.
Lara awọn to beere ọrọ yii la ti ri eeyan kan ti orukọ rẹ n jẹ North Boy, to ni bi babalawo naa ba jẹ ojulowo, ṣe EFCC yoo lawọn o mu?
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ni ti tiẹ, Klaus ni ṣe ẹṣẹ ni ki awọn irunmọlẹ ma gbe owo fun eeyan ni?
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Skala wee tilẹ ni bi babalawo naa ba ni agbẹjọro to munadoko, kia ni yoo jaja bọ lọwọ EFCC.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4
- Kogi Prison: Aráàlù tẹ́ẹ bá ní ìròyìn nípa àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó sá lọ, ẹ jọ̀wọ́ ẹ fún wa
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ṣàwárí agolo akẹ́rù tó kún fún ẹja àti oúnjẹ tó ti díbàjẹ́
- Bìlísì wáyé nígbà táwọn ṣọ́jà ya bo olú iléeṣẹ́ ọlọ́pàá l'Osogbo
- À ń ṣọ́ọ yín lórí ayélujára yín bàyìí o! Bí ẹ bá dán ọ̀rọ̀ kòbákùngbé wò - Lai Mohammed
- Mo kan wàhálà lálẹ ọjọ ìgbeyàwó torí ìbálé mi kò ṣe ẹjẹ - Ìyàwó ọ̀sìngín