Ìbálé ìyàwó: Àwọn onímọ̀ sọ ìdí tí àwọn obìnrin kan kìí ṣe sẹ̀jẹ̀ lẹ́yìn ìbálòpọ̀ àkọ́kọ́

Tọkọ taya ti wọn kẹyin si ara wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ibi gbogbo ni wọn ti nko adiẹ alẹ, akoko lo kan yatọ bẹẹ si ni bo se n bẹ ni liki naa lo wa ni gbanja.

Ọrọ gbigba ibale iyawo lo dabi ẹnipe ko mọ laarin iran Yoruba nikan, eyi to ti n fa wahala fun awọn idile kan jakejado agbaye.

Bi o tilẹ jẹ pe asa gbigba ibale iyawo lalẹ ọjọ igbeyawo ti n wọọkun lọ laarin ẹya Yoruba, amọ asa si rinlẹ digbin laarina ẹya Larubawa, eyi to n se akoba fun ọpọ igbeyawo bayii laarin ẹya naa.

Awọn obinrin mẹrin to ba BBC sọrọ lori asa yii salaye pe alẹ ọjọ ti ọkọ awọn fẹ gba ibale awọn, amọ ti ko mu ẹjẹ lọwọ, lo mu ko gbagbọ pe oun kii se ojulowo ọmọge eyi ti ko ri bẹẹ.

Tọkọ taya ti wọn kẹyin si ara wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iwadi awọn onimọ ijinlẹ si ti fidi rẹ mulẹ pe, kii se gbogbo obinrin ti wọn ba gba ibale rẹ ni yoo se ẹjẹ loju ara, nigba ti awọn obinrin kan tiẹ wa ti wọn ko mu ibale wa lati ọrun, tabi ki ibale wọn ti seesi ja lasiko ti wọn wa ni kekere nitori erepa to lagbara tabi ere idaraya ti wọn se.

A tun gbọ pe awọn ibale kan wa to ki pupọ, ti ko si lee tete ja, afi ti ọmọ ba fẹ gba oju ara obinrin jade nikan ni yoo to ja.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Obinrin to ba BBC sọrọ lo wa ni iru ipo taa darukọ yii, eyi ti ko jẹ ki igbeyawo rẹ tọjọ nigba ti ọkọ rẹ ko ri ẹjẹ ibale lara rẹ.

Bi alẹ ọjọ igbeyawo Somayya se ri ree nigba ti ibale ko se ẹjẹ:

Somayya ja fitafita pẹlu awọn obi rẹ lati ri pe o fẹ Ibrahim, tii se ololufẹ rẹ nile iwe fasiti tori pe o dara lọmọkunrin, to si ni amuyẹ ọkọ rere.

Amọ alẹ ariwo ni alẹ ọjọ igbeyawo wọn, ti okun ifẹ wọn si rẹ ja patapata nigbati oju Ibrahim koro pe iyawo oun ko ni ibale nigba ti ẹjẹ ko jade lara rẹ lẹyin ajọsepọ wọn akọkọ.

Obinrin ti o n ronu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O ni bi o tilẹ jẹ pe Ibrahim fẹ kọ oun silẹ, amọ oun yari pe oun ko lọ sibi kankan, to si daba pe kawọn lọ se ayẹwo nile iwosan lati mọ oun to sẹlẹ si ibale oun.

Ile iwosan ti wọn ti wa sewadi pe ibale Somayya nipọn pupọ, to si ki pẹlu, idi ree to fi nira fun ọkọ rẹ lati jaa lalẹ ọjọ igbeyawo wọn, afi igba ti Somayya ba fẹ bimọ nikan si ni ibale naa to lee ja.

Somayya ni lootọ ni inu ọkọ oun dun lati gbọ eyi amọ ohun to dara ti bajẹ, ẹpa ko si boro mọ nitori o ti sọ ọpọ ọrọ kobakungbe si oun, to si ti hu ọpọ iwa abuku, ki asiri ohun adiitu naa to tu.

Tọkọ taya ti wọn kẹyin si ara wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lẹyin eyi ni Somayaa wa pinnu pe oun yoo kọ Ibrahim silẹ nitori o ti di ajeji si oun, ti oun ko si fẹ maa pe ẹni to n tẹle asa lati ni ifẹ oun, gẹgẹ bii ọkọ.

Ọwọ meji ko oruka igbeyawo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Somayya ni"lootọ lo n ba mi sun lẹyin alẹ ọjọ igbeyawo wa amọ se ni mo n lera tori pe ọkan mi ko nifẹ rẹ mọ lati alẹ ọjọ to ti safihan ikorira si mi."