Kwara Local Government: EFCC jú alága ìjọba ibílẹ̀ 16 si àhámọ́

Abdulraman
Àkọlé àwòrán, Kwara Local Government: EFCC jú alága ìjọba ibílẹ̀ 16 si àhámọ́

Àjó to n gbógun ti ìwà jẹ́gúdújẹra lórílẹ̀-èdè Naijiria, ẹ̀ká ti ìpínlẹ̀ Kwara ti fi panpẹ́ ọba mú àwọn alága ìjọba ìbilẹ̀ mẹ́rìndinlógun ní ìpínlẹ̀ Kwara tí gónmìna AbdulRahman AbdulRazaq dá dúró.

Ẹ̀sùn síṣé owó bílíọ̀nù mẹ́rin àti dída ìdámẹ́wàá owo ti wọ́n ń pa wọle ni abẹ́lé sáwọn apo ara wọ́n ní wọn fi kan wọ́n.

Àwọ́n alága tí EFCC jù si gbaga ni Risikat Opakunle, Saidu Yaru Musa, Umar Belle, Ayeni Dallas, Fatai Adeniyi Garba, Lah Abdulmumeen, Raliat Funmi Salau, Aminat Omodara, Muyiwa Oladipo.

Àwọn to kù ní, Oladipo Omole, Abdullahi Abubakar Bata, Saka Eleyele, Lateef Gbadamosi, Oni Adebayo Joseph, Omokanye Joshua Olatunji àti Jibril Salihu.

Nínú àtẹjáde EFCC ti agbẹnuso r, Wilson Uwujaren fi sita sàlàyé pé lẹ́yìn ti awọn àlága náà ya owó, wọ́n ṣe ìpàdé wọ́n sì pinnu láti pín ọgọ́run un mílíọnù láàrin ara wọ́n.

Àkọlé fídíò, Lagos King: Mátikú ọba tó lo lo ọdun mẹta lórí oyé latari rogbodiyan Eko

Bí ọ̀gá EFCC ṣe sọ àwọn alága náà kọ lẹta sí oga agba ẹka ilé ifowopamọ Sterling ninu osu keji, ọdún 2108 lati yá mílíọnu mẹ́rin naira fun owo oṣù àwọn òsìsẹ́ SUBEB àti osisé ijọba ìbílẹ̀,

sùgbọ́n ko si ibi kankan ti wọ́n ti sọ nipa ọgọrun un mílíọnu Naira ti wọ́n pín.

Bá kan náà ni wọn fẹ̀sun kan pé awọn alága ọhun n da ìdá mẹ́wàá owó ti wọ́n n pa lábẹle si àpò ara wọ́n.

Gẹ́gẹ́ bi atẹjade náà se sọ: "àwọn alága náà wá n be àjọ EFCC pé ki wọn fún àwọn ni àsìkò díẹ̀ láti san owó náà pada"

EFCC ni wọ́n o ni pẹ́ gbé wọ́n lọ si ilé ẹjọ sùgbọ́n wọ́n o lo òpín ọsẹ wọ́n ni àtimọlé.

Àkọlé fídíò, Helgies Bandeira: Ọ̀pọ̀ oúnjẹ Yorùbá ni à ń jẹ ni Brazil