Osu mẹ́ta si mẹ́rin ni à fi n so wọ́n mọ́lẹ̀ fun ìwòsàn -Pasitọ Ojo

Oríṣun àwòrán, @PUNCH
Olùsọ́àgùtàn Joseph Ojo, tí ọwọ ṣìkún ọlọpàá ti mú fún lílo ilé ìjọsìn rẹ̀ àgbègbè Ijegun ni ìpínlẹ Eko gẹ́gẹ́ bi ẹwọn fún àwọn alárun ọpọlọ àti àwọn ti wọn ni ààrun kan tàbi òmíràn.
Ìròyin sọ pé ọlọpàá mú Ojo lẹ́yìn ti ẹka ọlọpàá Isheri-Osun tú àwọn ènìyàn mẹ́ẹ̀dógún sílẹ̀ nínú ilé ìjọsìn rẹ̀ ní ọjọrú lẹ́yìn ti àwọn àjọ kan ti kìí ṣe ti ìjọba tá ilé iṣẹ́ ọlọpàá lólobó.
- Ilé alájà méjì tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́ wó lulẹ̀ n'Ikoyi l'Eko
- Zanku tó gbòde kan, wo ìtumọ̀ àti bó ṣe bá orin tuntun Zlatan mu
- Soyombo yẹ fún àyẹ́sí gẹ́gẹ́ bí ògbóǹtagì oníròyìn - Aregbesola
- Kò burú bí Twitter bá fòfin dè ìpolongo òṣèlú lójú òpó - Kayode Ogundamisi
- Afẹ́fẹ́ gáàsì ìdáná bú gbàmù! Ẹ̀mí èèyàn 74 ṣòfò nílùú Karachi
Abẹwò sí ìjọ náà ní ọjọbọ ni àwọn ọlọpàá ba àwọn ènìyàn ti wọ́n so mọ́lẹ̀ bi ẹran àmúso tí àwọn míràn sì ń sọrọ̀ tri kò jọrawọn.
Ojo sàlàyé fún àwọn akọròyìn pé òun so àwọn ènìyàn náà mọ́lẹ nitórí ipò ti wọn wà, àti pé ọ̀pọ̀ wọ́n ni òbí wọ́n mú wá fún ìtúsílẹ̀ àti ìwòsàn.
O ní " a so àwọn ènìyàn yìí mọlẹ̀ nítori ipò ti wọ́n wà, ti a ò bá so wọ́n mọ́lẹ̀ wọn a sálọ, wọ́n ti ko mi sí wàhálà sẹ́yìn, nítori náà ni mo ṣe so wọ́n ti ara wọ́n bá ti ya ni a máa n tú wọ́n sílẹ̀."
Pasitọ Ojo ni: "Ibí kìí ṣe ilé ìwòsàn ti wọ́n ti n wo àrùn ọpọlọ sùgbọ́n ọ̀pọ̀ wọ́n ni wọ́n ti kọ́kọ́ gbe lọ si ilé iwosan ti wọ́n ti n wo wèrè ki wọ́n tó gbe wọ́n wá síbi."
"Bí osù mẹ́ta si mẹ́rin ni a maa fi n so wọ́n mọ́lẹ̀, àwọn ẹbi wọ́n si ni yoo máa fún wọn lóunjẹ, àwọn ẹbi àwọn mírànn máa ń wá lójoojúmọ, àwọn míràn ọsẹ̀-ọ̀sẹ̀, nígbà ti àwọn míràn ń gbe pẹ̀lú ẹbí wọ́n nínú ìjọ"
- ''Òsìsẹ́ Custom tó déédé sọ ara rẹ̀ di Ọ̀gá Àgbà CG ní ìdàmú ọpọlọ''
- Wo aṣọ òtútù tó wọ́n jùlọ ní àgbáyé!
- Mobolaji Johnson: Kíkọ́ Eko Bridge, wíwó ibojì òkú Ajẹlẹ àti àwọn mánigbàgbé míì tó ṣe l'Eko
- Nínú ká máa rin ìrìnàjò ilẹ̀ òkèèrè, ọgá ní Ọbasanjọ jẹ́ fún Buhari- Oshiomole
- Ọjọ́ mẹ́rin sí ìgbéyàwó wa ní ìyàwó mi b'ómi lọ- Ibrahim Abubakar
Ọkan nínú àwọnn ti wọ́n ti so mọ́lẹ̀ fún oṣù mẹ́jọ nibẹ, Adewale Adetona sàlàyé pé wọ́n ji òun gbé ni, àwọ́n ẹbi oun si gbe oun wá si ilé ìjọsin náà, o ni kò dùn mọ oun láti maa gbe sọ́ọ̀sì.
Ẹ̀wẹ̀ ìyá Adewale, Monsurat sàlàyé pe fúnra oun ni oun gbé ọmọ náà wa si ilé ìjọsin ọhun fún àdura, nitori o maa n doju ti ẹbi láàrin igboro.
Ijọ Blessings of Goodness Healing Church ni ijegun Isheri yii ni awọn ọlọpaa ti tu awọn eniyan naa silẹ gẹgẹ bi Bala Elkana to jẹ agbẹnusọ awọn ọlọpaa ṣe ṣalaye.















