Kurt sweater: Wo aṣọ òjò tó wọ́n jùlọ ní àgbáyé!

Oríṣun àwòrán, AFP / Getty
Ko si nkan ti awọn eniyan ko le tà tabi ra ni ọja agbaye!
Aṣọ otutu Kurt Cobain di aṣọ to wọn julọ ni gbogbo agbaye nigba ti wọn taa ni ẹgbẹrun mẹrinlelọgbọn o le ni ọọdunrun owo dọla ilẹ Amerika ni eyi to jẹ miliọnu mọkanlelọgọfa naira o le ni ẹgbẹrun irinwo naira.
Aṣọ otutu ti aṣaaju akọrin awọn ọmọ ẹgbẹ Nirvana, Kurt Cobain wọ to jẹ aṣọ otutu alawọ eweko to di akunlẹbọ yii lo fi ṣere "Unplugged" MTV lọdun 1993.
Wọn ko tii fọ aṣọ naa lati ọjọ naa to ti wọ ọ gbẹyin titi di oni oloni.
Lọjọ Abamẹta ni wọn ta aṣọ otutu yii ni New York ni $334, 000 ni eyi to jẹ N121.4 miliọnu owo naira.
Darren Julien to jẹ aarẹ awọn agbatẹru eto tita aṣọ otutu onkọrin Kurt yii ni aṣọ yii jẹ ọkan pataki julọ lara aṣọ ti awọn gbajugbaja onkọrin lagbaye tii wọ ri.
O ni aṣọ yii wa lara aṣọ to wọn julọ ti onkọrin takasufe yii wọri.
Kini wọn tun ta ni New York?
Kii ṣe aṣọ nikan ni wọn ta nibi itaja ojule ọhun to waye ni New York.
Wọn tun ta gìtá adaṣe fun ni ti Fender Mustang ṣe fun Cobain naa nibẹ.
Gita yii ni Cobain ta lasiko to n rin irinajo ipolongo orin ni Nirvana ni Utero tour.
Wọn ta gita yii ni $340, 000 eyi to jẹ ẹgberun marundinlaadọrin le ni igba owo pọun ilẹ Gẹẹsi.
Kini igbẹyin gbajugbaja onkọrin Cobain?
Opọlọpọ ọdun sẹyin ni wọn ti gbiyanju lati ta gita Cobain yii ni Rock and Roll Hal;l of Fame ki won to wa rii ta lọjọ Abamẹta yii.
Leyin ti Cobain kọ orin Nirvana lọdun 1987 lo di ojulumọ ninu orin takWo aṣasufe.
O jagun pelu oogun oloro, irobinujẹ ati jijẹ okutaye ki ọlọjọ to de.
Cobain pa ara rẹ loṣu kẹrin, ọdun 1994 lọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn.
- Àsìkò tó láti dóòlà Nàíjíríà, a ti gbé ẹ̀ṣùn ìbò lọ sílé ẹjọ́ tó ga jùlọ - PDP
- Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì yóò kúrò pátápátá lára àjọ EU ní Jan 31 ọdún 2020
- Lẹ́yìn ìpàdé òní l‘Abuja, ṣé ASUU yóò yanṣẹ́ lódì àbí bẹ́ẹ̀kọ́?
- Tọwọ́ tẹsẹ̀ laá fi gba ìrànwọ́ owó ẹ̀kọ́ Almajiri ní ìpinlẹ̀ Oyo- Alága Subeb
- Buhari kàn ń kọwọ́ bọ̀wé nílẹ̀ òkèèrè kiri ni, a ò rí ipa ní Nàijíríà- Onímọ̀ ọrọ̀-ajé
















