Ọ̀gá ẹlẹ́wọ̀n kan kú sí ìkọlù agbébọn tó fọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n Minna

Aworan ile ọgba ẹwọn kan

Oríṣun àwòrán, @npsreformer

Àkọlé àwòrán, Iléeṣẹ́ Ọgbà ẹ̀wọ̀n kò tíì sọ iye àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó sálọ nínú ìkọlù ọgbà ẹ̀wọ̀n Minna

Awọn agbebọn kan ti fọ ọgba ẹwọn to wa nilu Minna nipinlẹ Niger.

Ileeṣẹ ọgba ẹwọn lorilẹede Naijiria, lo kede rẹ pe ni alẹ ọjọ aiku ni awọn agbebọn naa fọ ọgba ẹwọn naa ti wọn si ko awọn ẹlẹwọn naa gbiyanju ati sa mọ ofin lọwọ.

Wọn ni awọn ko tii le sọ ni pato iye ẹlẹwọn to salọ ṣugbọn agbẹnusọ fun ileeṣẹ naa, Rabiu Shuaibu ni wọn ti mu awọn meje pada ninu awọn ẹlẹwọn naa.

O ni ọga ẹlẹwọn kan padanu ẹmi rẹ lasiko iṣẹlẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Awọn ọdaran kan ti wọn di ihamọra ibọn ni wọn kọlu ọgba ẹwọn wa ti wọn si ṣina ibọn fun awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn.

Nnkan bii agogo mẹjọ alẹ ọjọ aiku ni wọn kọlu ọgba ẹwọn to wa lagbegbe Tunga nilu Minna.

Oṣiṣẹ ọgba ẹwọn kan pẹlu ọlọkada kan to gbe oṣiṣẹ ileeṣẹ ọgba ẹwọn to wa ni iṣẹ alẹ wa sibi isẹ ni wọn yinbọn pa lasiko ti ikọlu naa waye."

Alaafia ti jọba pada lọgba ẹwọn naa bayi ṣugbọn awọn alaṣẹ ọgba ẹwọn naa ti sọ pe iwadi ti n waye lati ṣe awari awọn ẹlẹwọn to salọ naa.