Saraki: Mo ti ní kí olùrànlọ́wọ́ mi gba ìwé ìpeni àwọn Ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, @bukolasaraki
Adarí ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà, Bukola Saraki ní òun ti ni kí olùrànlọ́wọ́ pàtàkì òun tẹ́wọ́ gba ìwé ìpeni látọ̀dọ̀ ilé isẹ́ Ọlọ́pàá látàrí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án lánàá wí pe ó lọ́wọ́ nínú ìsẹ̀lẹ̀ ìdigunjalè Ọffa tó wáyé nínú osù kẹrin ọdún yìí níbí tí wọ́n ti pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Saraki sọ pe "mo sẹ̀sẹ̀ sọ fún olùrànlọ́wọ́ mi pé kó gba ìwé ìpeni látọ̀dọ̀ ilé isẹ̀ Ọlọ́pàá èyí tó ní se pẹ̀lú ẹ̀sùn tí wọ́n gbé jáde lánàá kí n lè tètè jẹ́ wọn ní òo".
Sáájú, adarí ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà, Bukola Saraki ti kọ ìwé jáde lórí ẹ̀rọ ayélujára wí pé ó ń fẹ́ kí gbogbo ará ìlú kọ etí ikún sí ẹ̀sùn tí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ tó tún jẹ́ ọàdọ́gbọ́n kó bá ni ní gbogbo ọ̀nà èyí tí ilé isẹ́ ọlọ́pàá rawọ́lé.

Oríṣun àwòrán, ALHAJI ABDULFATAH AHMED
"Ẹ jẹ́ kó di mímọ̀ wí pé kò sí ọ̀nà tí mo fẹ́ gbà lọ́wọ́ nínú kí wọ́n digun ja àwọn ènìyàn mi. Nígbà tí ìdigunjalè Ọffa sẹlẹ̀, èmi ní àgbà òsìsẹ́ Ọba tó kọ́kọ́ se ìbẹ̀wò síbẹ̀ bẹ́ẹ̀ si ni ní ààfin Ọba ìlú náà, mo fi ẹ̀rọ alágbéká pe Ọ̀gá àgbà àwọn Ọlọ́pàá, Ọ̀gbẹ́ni Ibrahim Idris pé kó se àlàkalẹ̀ fún àbò tí àwọn ènìyàn nílò.


Ọkọ̀ Lexus kan tí wọ́n lẹ orúkọ Olórí Ilé Aṣòfin Àgbà, Bukola Saraki, sí wà nínú nkan tí ó dá wàhálà sílẹ̀ tí ó fi di pé ọlọ́pàá orílẹ̀èdè Naijiria yóò máa fa Gómínà Ìpínlẹ̀ Kwara, Abdulfatah Ahmed, létí aṣọ lórí ìdigunjalè Offa.
Agbẹnusọ àjọ ọlọ̀paa, Jimoh Moshood, ní ọ̀gbẹ́ni Alabi Olalekan, tí ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ pàtàki fun gómínà náà rán arákùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Adeola Omiyale láti lọ fi ọkọ̀ náà pamọ́ sí Ilé Gomina ní Ilorin nígbà tí ó gbọ́ pé ọlọ̀paa ń wá ọkọ̀ náà nítorí ìdigunjalè Offa.

Oríṣun àwòrán, NIGERIA POLICE
Olalekan tí wọ́n tún bá ìbọn ìléwọ́ kan lọ́wọ́ rẹ̀ wà ní panpẹ́ ọlọ́pàá bayìí.
Ṣùgbọ́n gomina Kwara ní kò sí ọwọ́ oun nínú ọ̀rọ̀ náà,
Bákan náà, adarí àwọn òṣìṣẹ́ gómínà, Yusuf Abdulwahab, ni wọ́n fẹ̀sùn kan pé ó tún yọ nọ́mbà ìdánimọ̀ tí wọ́n kọ orúkọ Sarakí sí lára ọkọ̀ náà kí ó ṣẹ̀ tó wá lo ṣe ìfórúkọsílẹ̀ ọkọ̀ náà. Oun náà ti wà ní àhámọ báyìí.

Oríṣun àwòrán, NIGERIA POLICE
Ninú ìdáhùn rẹ̀ sí ẹ̀sùn tí ọlọ́pàá fi kàń, Ahmed, sọ wí pé òun kò ṣàtìlẹ́yìn fún àwọn jàǹdùkú kankan o.
Àtẹ̀jáde kan tí olùrànlọ́wọ́ pàtàki rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ìròyin, Muyideen Akorede ní òun ṣe ìrànlọ́wọ́ oríṣiríṣi fún àwọn ọ̀dọ́, ṣùgbọ́n kò mọ àwọn agbeébọn ti ọ ṣọsẹ́ ní Offa rí.














