Ilé-Iṣẹ́ Ọlọ́páà: Ọlọ́kadà ẹ sọ́ra nílùú Èkó

Aworan àwọn ọlọpàá

Oríṣun àwòrán, Police forcee/twitter

Àkọlé àwòrán, Ọlọ́pàá kò ní mú ọlọ́kadà níkan bíkòṣe pé kí kojú ìjìyà tó tọ lábẹ́ òfin.

Ilé iṣẹ́ ọlapàá ìpínlẹ̀ Èkó ti kéde pé, ètò ti wà ni ṣẹpẹ́ báyìí láti bẹ̀rẹ̀ sí ní mú àwọn ọlọ́kada tí kò bá rìn ní ìlànà òfin láti ọjọ́ kẹẹ̀dógun oṣù yìí.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, 'Isẹ́ Tíátà tí mò ń se ti tó mi jẹun'

Ìpinu ọ̀hún wáyé lẹ́yìn ìpàdé pẹ̀lúu kọmísọ́nà ọlapàá fún ìpínlẹ̀ Èkó, Imohimi Edgal pẹ̀lú onírúuru ẹgbẹ́ ọlọ́kadà.

Ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá ní òun yóò gùnlé ìpinu rẹ nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ aburú tó wáyé ní Ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù tó kọjá nígbà tí àwọn ọlọ́kada yabo ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá ní Ìbeṣhe tí wọn sì sun ọkọ̀ ọlọ́pàá kan délẹ̀.

Àtèjáde tí àgbẹnusọ ọlọ́pàá Chike Oti fọwọ́sí sàlàyé pé, àgbékalẹ̀ ìpádé ọ̀hún wáyétí wọn sì bu ẹnu àtẹ́ lu ìwà tí àwọn ọlọ́kàdà náà hù.

Ó ní ọlọ́pàá kò ní mú ọlọ́kadà níkan bíkòṣe pé kí kojú ìjìyà tó tọ lábẹ́ òfin.