Ayédèrú agbẹjọ́rò tó ṣiṣẹ́ fún ọdún mẹ́ta láì ní'wé ẹ̀rí

Oríṣun àwòrán, LAGOS STATE POLICE COMMAND
Ọwọ́ ọlọ́pàá ti tẹ arákùnrín kan ní ilé ẹjọ́ ìbílẹ̀ tí ó wà ní Ọ̀jọ́ ni Ìpínlẹ̀ Eko lórí ẹ̀sùn pé ayédèrú agbẹjarò ni.Agbẹnusọ fún àjọ ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Eko, Chike Oti, sọ wipé àwọn ikọ̀ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ àjọ náà ni ó mu u, ti ó sì jẹ́wọ́ wípé òun ti ń ṣiṣẹ́ agbẹjọ́rò fún ọdún mẹ́ta láà ní ìwé ẹ̀rí kankan.
Ilé ẹjọ́ kan náà ni Ọ̀jọ́ tí wọn ti mú arákùnrín náà ni awọn ọlọ́pàá gbé e lọ láti lọ jẹ́jọ́.
Ajọ ọlọ́pàá nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò rẹ̀, ayédèrú agbẹjarò náà ní òun nífẹ̀ sí ìṣẹ́ agbẹjọ́rò nígbà tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan ran kí ó ṣe bí amòfin láti lọ jáwè fún ayálégbé kan.
A gbọ́ pé ọwọ́ tẹ̀ ẹ́ nígbà tí àwọn ojúlówó agbẹjọ́rò tó wà nínu ilé ẹjọ́ nígbà tí ó ń sọrọ níwájú adájọ funra pé kò kàwé.








